Monday, 29 June 2020

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Kejìlá)

فَصْلٌ فِي السُجُودِ فِي سَهْوِ السُّنَنِ

وَلَا يَكُونُ السُّجُودُ الْقَبَلِيُّ إِلَّا لِتَرْكِ سُنَّتَيْنِ فَأَكْثَرَ. وَأَمَّا السُّنَّةُ الْوَاحِدَةُ فَلَا سُجُودَ لَهَا إِلَّا السِّرَّ وَالْجَهْرَ، فَمَنْ أَسَرَّ فِي الْجَهْرِ سَجَدَ قَبْلَ السَّلَامِ، وَمَنْ جَهَرَ فِي السِّرِّ سَجَدَ بَعْدَ السَّلَامِ. وَمَنْ تَكَلَّمَ سَاهِيًا سَجَدَ بَعْدَ السَّلَامِ، وَمَنْ سَلَّمَ مِنْ رَكْعَتَيْنِ سَاهِيًا سَجَدَ بَعْدَ السَّلَامِ، وَمَنْ زَادَ فِي الصَّلَاةِ رَكْعَةً أَوْ رَكْعَتَيْنِ سَجَدَ بَعْدَ السَّلَامِ. وَمَنْ زَادَ فِي الصَّلَاةِ مِثْلَهَا بَطَلَتْ، وَمَنْ شَكَّ فِي كَمَالِ صَلَاتِهِ أَتَى بِمَا شَكّ فِيهِ، وَالشَّكُّ فِي النُّقْصَانِ كَتَحَقُّقِهِ.

 

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìforíkanlẹ̀ Ìgbàgbé Níbi Àwọn Isẹ́ tí Kìí Se Ọ̀ranyàn

 

Ìgbà tí áò mú ìforíkanlẹ̀ méjì síwájú sálámọ̀ wá níbi ìgbàgbé àwọn isẹ́ tí kìí se ọ̀ranyàn (Sunan) ni ìgbà tí ìgbàgbé láti mú méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ wá nínú irúfẹ́ àwọn isẹ́ yìí sẹlẹ̀ lórí ìrun kíkí. Sùgbọ́n tí kò bá ju ẹyọkan péré lọ, kò sí ìforíkanlẹ̀ ìgbàgbé fún un àyàfi tí ó bá jẹ́ ìgbàgbé ọ̀kan nínú àwọn ìlànà ìkírun tí ó kanpá (Sunnatun Muakkadah); gẹ́gẹ́ bíi kíkéwú sókè tàbí kíkéwú jẹ́ẹ́jẹ́.

Ẹni tí ó bá kéwú sókè láyè jẹ́ẹ́jẹ́, yóò tánràn rẹ̀ pẹ̀lú ìforíkanlẹ̀ ìgbàgbé lẹ́yìn sálámọ̀. Ẹni bá wáá kéwú jẹ́ẹ́jẹ́ láyè kíké sókè, ìforíkanlẹ̀ ìgbàgbé síwájú sálámọ̀ ni yóò fi tán an.

Ẹni bá gbàgbé sọ̀rọ̀ lórí ìrun, ìtanràn rẹ̀ ni síse ìforíkanlẹ̀ ìgbàgbé lẹ́yìn sálámọ̀.

Ẹni tí ó bá gbàgbé sálámọ̀ lórí ọ̀pá méjì, ìforíkanlẹ̀ ìgbàgbé lẹ́yìn sálámọ̀ ni ìtanràn rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì gbàgbé fi ọ̀pá kan tàbí méjì kún ìrun, òun náà yóò fi ìforíkanlẹ̀ ìgbàgbé lẹ́yìn sálámọ̀ tán an.

Ẹni tí ó bá wáá gbàgbé fi dèèdé iye ọ̀pá ìrun tí ó ń kí lọ́wọ́ kún ìrun, ìrun rẹ̀ ti bàjẹ́. Ẹni tí ó bá ń se iyè méjì lórí pípé ìrun rẹ̀ tàbí àìpé, yóò mú ọ̀pá tí iye méjì wà lórí rẹ̀ wá. 

Wednesday, 24 June 2020

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Kọkànlá)

بَابٌ فِي السَّهْوِ

 

وَسُجُودُ السَّهْوِ فِي الصَّلَاةِ سُنَّةٌ، فَلِلنُّقْصَانِ سَجْدَتَانِ قَبْلَ السَّلَامِ بَعْدَ تَمَامِ التَّشَهُّدَيْنِ يَزِيدُ بَعْدَهُمَا تَشَهُّدًا آخَرَ. وَلِلزِّيَادَةِ سَجْدَتَانِ بَعْدَ السَّلَامِ يَتَشَهَّدُ بَعْدَهُمَا وَيُسَلِّمُ تَسْلِيمَةً أُخْرَى. وَمَنْ نَقَصَ وَزَادَ سَجَدَ قَبْلَ السَّلَامِ. وَمَنْ نَسِيَ السُّجُودَ الْقَبَلِيَّ حَتَّى سَلَّمَ سَجَدَ إِنْ كَانَ قَرِيبًا. وَإِنْ طَالَ أَوْ خَرَجَ مِنَ الْمَسْجِدِ بَطَلَ السُّجُودُ وَتَبْطُلُ الصَّلَاةُ مَعَهُ إِنْ كَانَ عَلَى ثَلَاثِ سُنَنٍ أَوْ أَكْثَرَ مِنْ ذَلِكَ وَإِلَّا فَلَا تَبْطُلُ. وَمَنْ نَسِيَ السُّجُودَ البَعْدِيَّ سَجَدَهُ وَلَوْ بَعْدَ عَامٍ. وَمَنْ نَقَصَ فَرِيضَةً فَلَا يُجْزِيهِ السُّجُودُ عَنْهَا. وَمَنْ نَقَصَ الْفَضَائِلَ فَلَا سُجُودَ عَلَيْهِ. 

 

ÀKÒRÍ ASÀLÀYÉ NÍPA ÌFORÍKANLẸ̀ ÌGBÀGBÉ

 

Ìlànà ànábì (Muhammad) ni ìforíkanlẹ̀ ìgbàgbé níbi ìrun jẹ́. Tí ó bá jẹ́ àdínkù ìrun ni ó sẹlẹ̀, ìforíkanlẹ̀ méjì síwájú sálámọ̀ lẹ́yìn àtááyá (Taṣahudu) ìgbẹ̀yìn ni ìtanràn rẹ̀, pẹ̀lú síse àtááyá (Taṣahudu) míràn lẹ́yìn ìforínkanlẹ̀ méjéèjì síwájú sálámọ̀.

Tí ó bá wáá jẹ́ àlékún ìrun ní ó bá ìgbàgbé wá, ìforíkanlẹ̀ méjì lẹ́yìn sálámọ̀ ní ìtanràn rẹ̀, pẹ̀lú sìse àtááyá (Taṣahudu) míràn lẹ́yìn ìforíkanlẹ̀ méjéèjì, pẹ̀lú mímú sálámọ̀ míràn wá.

Ẹni tí ó bá jẹ́ wípé méjéèjì (Àdínkù àtí Àlékún) ni ó sẹlẹ̀ lórí ìrun rẹ̀, ìforíkanlẹ̀ méjì síwájú sálámọ̀ ni yóó fi tánràn rẹ̀.

Ẹni tí ó bá yẹ kí ó se ìforíkanlẹ̀ méjì síwájú sálámọ̀ tí kò ranti tí ó fi sálámọ̀, yóò mú ìforíkanlẹ̀ méjì náà wá tí àsìkò tí ó wà láàrin sálámọ̀ rẹ̀ àti ìsọyè rẹ̀ kò bá jágùn. Sùgbọ́n tí àsìkò tí ó wà láàrin méjéèjì bá fi jágùn tàbí olùkírun ti jáde ní ibùdó ìkírun (Masalasi), ìforíkanlẹ̀ méjéèjì pẹ̀lú ìrun rẹ̀ ti bàjẹ́, èyun ùn tí ó bá jẹ́ wípé oun tí ó bá igbagbe rẹ̀ rìn ni àwọn oun tí kíì se ọ̀ranyan (Sunan) mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ; láì kò jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìrun rẹ̀ kò bàjẹ́.

Ẹni tí ó bá wáá jẹ́ ìforíkanlẹ̀ ẹ̀yìn sálámọ̀ ni ó gbàgbé láti mú wá, yóò mu wá ní ìgbàkígbà tí ó bá ranti kì bá ǹjẹ́ lẹ́yìn odidi ọdún kan ni.

Tí ó bá jẹ́pé isẹ́ ọ̀ranyàn ìrun ni ó bá igbagbe rìn, ìforínkanlẹ̀ igbagbe kò ràn án, àyàfi kí ó mú isẹ́ ọ̀ranyàn náà wá padà.

Tí ó bá sì jẹ́ wípé oun tí ó bá ìgbàgbé rìn ni ọ̀kan nímú àwọn oun tí wọ́n kàn fẹ́ síse wọ́n lórí ìrun, ìforíkanlẹ̀ ìgbàgbé kíì se ọ̀ranyàn láti mú wá.

Wednesday, 17 June 2020

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Kẹ̀wá)

فَصْلٌ فِي قَضَاءِ الصَّلاةِ


 يَجِبُ قَضَاءُ مَا فِي الذِّمَّةِ مِنْ الصَّلَوَاتِ وَلَا يَحِلُّ التَّفْرِيطُ فِيهَا. وَمَنْ صَلَّى كُلَّ يَوْمٍ خَمْسَةَ أَيَّامٍ فَلَيْسَ بِمُفَرِّطٍ. وَيَقْضِيهَا عَلَى نَحْوِ مَا فَاتَتْهُ، إِنْ كَانَتْ حَضَرِيَّةً قَضَاهَا حَضَرِيَّةً. وَإِنْ كَانَتْ سَفَرِيَّةً قَضَاهَا سَفَرِيَّةً سَوَاءٌ كَانَ حِينَ الْقَضَاءِ فِي حَضَرٍ أَوْ سَفَرٍ. وَالتَّرْتِيبُ بَيْنَ الْحَاضِرَتَيْنِ وَبَيْنَ يَسِيرِ الْفَوَائِتِ مَعَ الْحَاضِرَةِ وَاجِبٌ مَعَ الذِّكْرِ. وَالْيَسِيرُ أَرْبَعُ صَلَوَاتٍ فَأَدْنَى، وَمَنْ كَانَتْ عَلَيْهِ أَرْبَعُ صَلَوَاتٍ فَأَقَلُّ صَلَّاهَا قَبْلَ الْحَاضِرَةِ وَلَوْ خَرَجَ وَقْتُهَا، وَيَجُوزُ الْقَضَاءُ فِي كُلِّ وَقْتٍ. وَلَا يَتَنَفَّلُ مَنْ عَلَيْهِ الْقَضَاءُ وَلَا يُصَلِّي الضُّحَى وَلَا قِيَامَ رَمَضَانَ وَلَا يَجُوزُ لَهُ إِلَّا الشَّفْعُ وَالْوَتْرُ وَالْفَجْرُ وَالْعِيدَانِ وَالْخُسُوفُ وَالِاسْتِسْقَاءُ. وَيَجُوزُ لِمَنْ عَلَيْهِمُ الْقَضَاءُ أَنْ يُصَلُّوا جَمَاعَةً إِذَا اسْتَوَتْ صَلَاتُهُمْ. وَمَنْ نَسِيَ عَدَدَ مَا عَلَيْهِ مِنْ الْقَضَاءِ صَلَّى عَدَدًا لَا يَبْقَى مَعَهُ شَكٌّ.

 

Ẹ̀kọ́ Nípa Sísan Gbèsè Ìrun


Ọ̀ranyàn ni fún ẹni tí ó bá jẹ gbèsè ìrun kí ó san án láì kò fi jáfara. Ẹni tí ó bọ́ níbi fífi gbèsè ìrun jáfara ni ẹni tí ó bá sapá san gbèsè odidi ìrun ọjọ́ máàrún ní ọjọ́ kan.


Dèèdé ìrun tí onígbèsè ìrun bá sì jẹ ni yóò san; bí ó bá jẹ́ gbèsè ìrun onílé ni ó jẹ, ìsan onílé náà ni yóó san àn, bí ó bá sì jẹ́ gbèsè ìrun arìnrìn àjò náà ni ó jẹ, ìsan arìnrìn àjò náà ni yóò san án, yálà àjò ni sísan gbèsè ìrun onílé bá a ni tàbí ilé ni sísan gbèsè ìrun arìnrìn àjò bá a.


Sísan gbèsè ìrun méjì (tí ó tò tẹ̀lé ara wọn lẹ́yìn tí àsìkò wọn ti jáde, àti ìrun méjì tí kò pẹ́jù tí àsìkò ọ̀kan nínú wọn ti jáde tí ìkejì kò tíì jáde) ní tẹ̀létẹ̀lé jẹ́ ọ̀ranyàn, lópin ìgbà tí ìgbàgbé kò bá se olùjẹ gbèsè ìrun.


Òdiwọ̀n gbèsè tí kò pọ̀jù ni ọ̀pá ìrun mẹ́rin wálẹ̀. Ẹni tí ó bá ní gbèsè ọ̀pá ìrun mẹ́rin wálẹ̀ lọ́rùn gbudọ̀ sán síwájú ìrun tí àsìkò rẹ̀ wà níta, kódà kí àsìkò ìrun tí ó wà níta jáde síwájú kí ó tóó san án tán. Ìgbàkígbà sì ni sísan gbèsè ìrun lẹ́tọ́, yálà ní ọ̀sán tàbí òru.


Kò sì lẹ́tọ́ fún ẹni tí ó bá ní gbèsè ìrun lọ́rùn kí ó máa kí ìrun àkígbọrẹ (Naafila); bíi naafila ìyálẹ̀ta (Duhaa), naafila òru osù ààwẹ ramalaana (Áásámú). Àyàfi àkígbọrẹ (Nááfílà) oníméjìméjì (Ṣáfúì) àti ẹlẹ́yọkọ̀ọ̀kan (Wítìrí) tí a máá ń yàn lóru, nááfílà ọ̀pá méjì ẹ̀yìn àlùfájàrí, ìrun ọdún méjéèjì (Ìtunu àti Iléyá), nááfílà ìtọrọ àánú Ọlọ́hun nígbà tí ìmọ́lẹ̀ òòrùn bá wọlé (Khusuufu), àti nááfílà tí ìtọrọ omi òjò lọ́dọ̀ Ọlọ́hun lásìkò ọ̀dá (Istiskọọu).


Kòsì burú kí àwọn èèyàn púpọ̀ tí gbèsè wọn papọ̀ san gbèsè wọn ní àpapọ̀ (Jànmọ́ ọ̀n).


Ẹni tí ìgbàgbé iye gbèsè wákàtí ìrun tí ó jẹ sọ́rùn bá wáá se, iye wákàtí tí ó le gbé ìrújú kúrò fun ni yóó san.


Saturday, 13 June 2020

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Kẹsan)

فَصْلٌ فِي أَحْوَالِ أَدَاءِ الصَّلاةِ

لِلصَّلَاةِ الْمَفْرُوضَةِ سَبْعَةُ أَحْوَالٍ مُرَتَّبَةٍ تُؤَدَّى عَلَيْهَا. أَرْبَعَةٌ مِنْهَا عَلَى الْوُجُوبِ، وَثَلَاثَةٌ عَلَى الِاسْتِحْبَابِ. أَوَّلُهَا الْقِيَامُ بِغَيْرِ اسْتِنَادٍ ثُمَّ الْقِيَامُ بِاسْتِنَادٍ، ثُمَّ الْجُلُوسُ بِغَيْرِ اسْتِنَادٍ، ثُمَّ الْجُلُوسُ بِاسْتِنَادٍ، فَالتَّرْتِيبُ بَيْنَ هَذِهِ الْأَرْبَعَةِ عَلَى الْوُجُوبِ إِذَا قَدَرَ عَلَى حَالَةٍ مِنْهَا وَصَلَّى بِحَالَةٍ دُونَهَا بِطَلَتْ صَلَاتُه. وَالثَّلَاثَةُ الَّتِي عَلَى الِاسْتِحْبَابِ هِيَ: أَنْ يُصَلِّيَ الْعَاجِزُ عَنْ هَذِهِ الثَّلَاثَةِ الْمَذْكُورَةِ عَلَى جَنْبِهِ الْأَيْمَنِ، ثُمَّ عَلَى الْأَيْسَرِ ثُمَّ عَلَى ظَهْرِهِ. فَإِنْ خَالَفَ فِي الثَّلَاثَةِ لَمْ تَبْطُلْ صَلَاتُهُ. وَالِاسْتِنَادُ الَّذِي تَبْطُلُ بِهِ صَلَاةُ الْقَادِرِ عَلَى تَرْكِهِ هُوَ الَّذِي يَسْقُطُ بِسُقُوطِهِ، وَإِنْ كَانَ لَا يَسْقُطُ بِسُقُوطِهِ فَهُوَ مَكْرُوهٌ. وَأَمَّا النَّافِلَةُ فَيَجُوزُ لِلْقَادِرِ عَلَى الْقِيَامِ أَنْ يُصَلِّيَهَا جَالِسًا، وَلَهُ نِصْفُ أَجْرِ الْقَائِمِ. وَيَجُوزُ أَنْ يَدْخُلَهَا جَالِسًا وَيَقُومَ بَعْدَ ذَلِكَ أَوْ يَدْخُلَهَا قَائِمًا وَيَجْلِسَ بَعْدَ ذَلِكَ إِلَّا أَنْ يَدْخُلَهَا بِنِيَّةِ الْقِيَامِ فِيهَا فَيَمْتَنِعَ جُلُوسُهُ بَعْدَ ذَلِكَ.

 

Ẹ̀kọ́ Nípa Àwọn Ìsesí tí A Lè Gbà Kí Ìrun


Isèsí méje ni ìrun ọ̀ranyàn lè gbà jẹ́ kíkí; Mẹ́rin nínú wọn jẹ́ ọ̀ranyàn, nígbà tí mẹ́ta yókù sì jẹ́ oun tí a fẹ́. Àwọn ni ìwọ̀nyí ní sísẹ̀ n tẹ̀lé:

Àkọ́kọ́: kíkí ìrun ní ídùró láì kò fara ti ǹkankan.

Ìkejì: kíkí ìrun ní ídúró pẹ̀lú ìfara ti ǹkan.

Ìkẹta: kíkí ìrun ní ìjòkó láì kò fara ti ǹkan.

Ìkẹrin: kíkí ìrun ní ìjòkó pẹ̀lú fifi ara ti ǹkan.

Títo àwọn ọ̀nà mẹ́ẹ́rẹ̀rin yí tẹ̀lé ara wọn jẹ́ ọ̀ranyàn, ẹni tí ó bá lágbára àkọ́kọ́ nínú wọn tí ó wáá fò sórí èyí tí ó tẹ̀le, ìrun rẹ̀ ti bàjẹ́.

Ẹò wáá rí àwọn ìsesí mẹ̀ta tí èèyàn lè gbà kírun bí ó bá se fẹ́ ni ìwọ̀n yí:

Àkọ́kọ́: Kí aláìlágbára àwọn ọ̀nà mẹ́ẹ́rẹ̀rin tí ó siwájú yẹn fi ìhà ọ̀tún rẹ̀ lélẹ̀ kí ìrun.

Ìkejì: kíkí ìrun pẹ̀lú fífi ìhà àlááfíà (Òsì) lélẹ̀.

Ìkẹta: kíkí ìrun pẹ̀lú fifi ẹ̀yìn lélẹ̀.

Tí aláìlágbára àwọn ọ̀nà mẹ́ẹ́rẹ̀rin tí ó siwájú yẹn bá wáá kí ìrun pẹ̀lú èyíkéyí nínú àwọn ìsesí mẹ́ta tí ó gbẹ̀yìn yìí bí ó se wùú, ìrun rẹ̀ ní àlááfíà, kò sì bàjẹ́.

 

Àkíyèsí:

Ìfaratì tí ó lè ba ìrun ẹni tí ó lágbára láti dúró láì kò fi ara ti ǹkankan jẹ́ ni ìfaratì tí ó lágbára debi tí ó se wípé tí oun tí ó bá fi ara tì bá subú, òhun náà yóò subú tẹ̀le. Sùgbọ́n tí ìfaratì náà kò bá lágbára tó bẹ́ẹ̀, ìrun kò bàjẹ́, sùgbọ́n oun ẹ̀kọ̀ ni.

    Tí ó bá wáá jẹ́ ìrun àkígbọrẹ (Nááfílà) ni, ẹni tí ó lágbára láti dúró láì kò fi ara ti ǹkankan lè kí i ní ìjòkó, sùgbọ́n ìlàjì láádá (Ẹ̀san) ni yóó gbà. Ìgbàláyè sì wà fún un kí ó bẹ̀rẹ̀ ìrun àkígbọrẹ (Naafila) pẹ̀lú ìjòkó, kí ó parí rẹ̀ pẹ̀lú ìnàró. Tàbí kí ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìnàró, kí ó sì parí rẹ̀ pẹ̀lú ìjòkó. Àyàfi tí ó bá jẹ́ wípé àníyàn ìnàró ni ó dà fi bẹ̀rẹ̀ ìrun naafila, èèwọ̀ ni kí ó joko parí rẹ.

Wednesday, 10 June 2020

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Kẹjọ)

فَصْلٌ فِي الخُشُوعِ فِي الصَّلاةِ


لِلصَّلَاةِ نُورٌ عَظِيمٌ تُشْرِقُ بِهِ قُلُوبُ الْمُصَلِّينَ، وَلَا يَنَالُهُ إِلَّا الْخَاشِعُونَ، فَإِذَا أَتَيْتَ إِلَى الصَّلَاةِ فَفَرِّغْ قَلْبَكَ مِنْ الدُّنْيَا وَمَا فِيهَا، وَاشْتَغِلَ بِمُرَاقَبَةِ مَوْلَاكَ الَّذِي تُصَلِّى لِوَجْهِهِ. وَاعْتَقِدْ أَنَّ الصَّلَاةَ خُشُوعٌ وَتَوَاضُعٌ لِلَّهِ سُبْحَانَهُ بِالْقِيَامِ وَالرُّكُوعِ وَالسُّجُودِ وَإِجْلَالٌ وَتَعْظِيمٌ لَهُ بِالتَّكْبِيرِ وَالتَّسْبِيحِ وَالذِّكْرِ. فَحَافِظَ عَلَى صَلَاتِكَ فَإِنَّهَا أَعْظَمُ الْعِبَادَاتِ، وَلَا تَتْرُكِ الشَّيْطَانَ يَلْعَبُ بِقَلْبِكَ وَيَشْغَلُكَ عَنْ صَلَاتِكَ حَتَّى يَطْمِسَ قَلْبَكَ وَيَحْرِمَكَ مِنْ لَذَّةِ أَنْوَارِ الصَّلَاةِ، فَعَلَيْكَ بِدَوَامِ الْخُشُوعِ فِيهَا فَإِنَّهَا تَنْهَى عَنْ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ بِسَبَبِ الْخُشُوعِ فِيهَا، فَاسْتَعِنْ بِاللَّهِ إِنَّهُ خَيْرُ مُسْتَعَانٍ.

 

Ẹ̀kọ́ Míràn Lórí Ìfọkàn-Sìn Ọlọ́hun


Ìmọ́lẹ̀ ńlá kan ń bẹ níbi ìrun kíkí, tí ó má ń tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn àwọn olùkirun. Àwọn olùfọkàn sin Ọlọ́hun lórí ìrun wọn nìkan ni ọwọ́ wọn sì má ń tẹ ìmọ́lẹ̀ náà.


Torínáà, tí o bá ti fẹ́ẹ́ kírun, pa ọkàn rẹ lófo kúrò níbi ayé àti yòdòyindin rẹ̀, kí o sì pa ọkàn rẹ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun tí ò ń torí rẹ̀ jọ́sìn. Sì ní àdìsọ́kàn wípé òpó ńlá tí ó gbé ìrun dùró náà ni; ìpáyá àti ìtẹríba fún Ọlọ́hun; pẹ̀lú ìdúró, ìtẹ̀ kọkọrọ (RukË‘), àti ìforíbalẹ̀ (SujËd). Àti ìbàbàrà Ọlọ́hun; pẹ̀lú síse gbólóhùn ‘Allahu Akbaru’, síse àfọ̀mọ́ (SubÍÉnallÉh), àti ìrántí Rẹ̀ (Al-Dhikr).


Sì se àmójútó ìrun rẹ, torípé ìjọsìn tí ó kàǹkà ni. Má se gba èsù láyè láti fi ọpọlọ rẹ seré tàbí darí ọkàn ìrẹ kúrò níbi ìrun kiki; kí ó lè gba ọpọlọ rẹ àti láti kọ dí rírí adùn àwọn ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ níbi ìrun kíkí fún ìrẹ.


Ó sì di ọ̀ranyàn fún ọ kí o dún ní mọ́ ìfọkàn-sin Ọlọ́hun, nítorípé yóò maa darí ìrẹ kúrò níbi ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà èérí. Wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́hun lórí fífi ìfọkàn-sin Ín rọ ìrẹ lọ́rùn, torípé Òun (Ọlọ́hun) nìkan ni ó lè fi rọ ènìyàn lọ́rùn.


Monday, 8 June 2020

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Keje)

فَضَائِلُ الصَّلَاةِ وَمَكرُوهاتُها
Àwọn Oun tí Wọ́n Fẹ́ Sìse Wọ́n àti Àwọn Èyí tí Wọ́n Kọ̀ Nibi Ìrun Kíkí


صورة الأخضري.jpg
(وَفَضَائِلُهَا) رَفْعُ الْيَدَيْنِ عِنْدَ الْإِحْرَامِ حَتَّى تُقَابِلَا الْأُذُنَيْنِ وَقَوْلُ الْمَأْمُومِ وَالْفَذِّ: رَبَّنَا وَلَكَ الْحَمْدُ، وَالتَّأْمِينُ بَعْدَ الْفَاتِحَةِ لِلْفَذِّ وَالْمَأْمُومِ، وَلَا يَقُولُهَا الْإِمَامُ إِلَّا فِي قِرَاءَةِ السِّرِّ، وَالتَّسْبِيحُ فِي الرُّكُوعِ وَالدُّعَاءُ فِي السُّجُودِ، وَتَطْوِيلُ الْقِرَاءَةِ فِي الصُّبْحِ وَالظُّهْرِ تَلِيهَا وَتَقْصِيرُهَا فِي الْعَصْرِ وَالْمَغْرِبِ، وَتَوَسُّطُهَا فِي الْعِشَاءِ، وَتَكُونُ السُّورَةُ الْأُولَى قَبْلَ الثَّانِيَةِ وَأَطْوَلَ مِنْهَا، وَالْهَيْئَةُ الْمَعْلُومَةُ فِي الرُّكُوعِ وَالسُّجُودِ وَالْجُلُوسِ وَالْقُنُوتِ سِرًّا قَبْلَ الرُّكُوعِ وَبَعْدَ السُّورَةِ فِي ثَانِيَةِ الصُّبْحِ وَيَجُوزُ بَعْدَ الرُّكوعِ وَالدُّعَاءُ بَعْدَ التَّشَهُّدِ الثَّانِي، وَيَكُونُ التَّشَهُّدُ الثَّانِي أَطْوَلَ مِنَ الْأَوَّلِ وَالْتَّيَامُنُ بِالسَّلَامِ وَتَحْرِيكُ السَّبَّابَةِ فِي التَّشَهُّدِ.


Àwọn oun tí wọ́n fẹ́ síse wọn níbi ìrun kiki ni: (1) Gbígbé ọwọ́ sókè titi yóò fi kan etí níbi síse kábárà (Allahu Akbar) alákọ́kọ́. (2) Wíwí gbólóhùn ‘Rabbanaa walakal hamdu’fún ẹni tí ń tẹ̀lé ìmáámù àti ẹni tí ó ń dá ìrun kí. (3) Wíwí gbólóhùn ‘Aamiina’ lẹ́yìn kika ‘Suratul Faatihah’ fún ẹni tí ó ń tẹ̀lé ìmáámù àti ẹni tí ó ń dá ìrun kí, ìmáámù kò sì níí wí i àyàfi níbi ìkéwú jẹ́ẹ́jẹ́. (4) Síse gbólóhùn àfọ̀mọ́ ‘Subhaanallahi’ ní ìtẹríba (Rukuu). (5) Àdúà síse ní ìforíbalẹ̀ (Sujuudu). (6) Ìkéwú tí ó jagun níbi ìrun àsùnbáà (Subui), àti àílà (Duhri). (7) Ìkéwú mọ ní ìwọ̀nba níbi ìrun àlásàrì (Asri), àti Mọ́gáríbì (Magribi). (8) Ìkéwú ní ìwọ̀ntunwọ̀nsí níbi ìrun ishai. (9) Kí kéwú ọ̀pá alákọ́kọ́ jagun ju ti ọ̀pá ẹlẹ́kejì lọ. (10) Àwọn ìṣesí bí ó se yẹ kí ó rí ní ìtẹríba (Rukuu) bíi títẹ́ ẹ̀yìn pẹrẹsẹ, ìforí kanlẹ̀ (Sujuudu) bíi dída àtẹlẹwọ́ délẹ̀, àti ìjòkó (Juluusu) títẹ́ ẹsẹ̀ méjéèjì sílẹ̀ láti jókó lé e. (11) Kíké adua ‘Kunuutu’ ní jẹ́ẹ́jẹ́ síwájú ìtẹríba (Rukuu) lẹ́yìn kéwú ní ọ̀pá keji ìrun àsúnbà (Subhi). Kò sì buru kí ó jẹ́ síse lẹ́yìn ìtẹríba (Rukuu) náà. (12) Àdúà síse lẹ́yìn ‘Àtááyá’ ìkẹyìn. (13) Fífa ‘Àtááyá’ ìkẹyìn gùn ju ti alákọ́kọ́ lọ. (14) Yíyí orí níbi gbolohun sálámọ̀. (15) Mími ọmọníka ìfábẹ̀lá níbi ‘Àtááyá’.

وَيُكْرَهُ الِالْتِفَاتُ فِي الصَّلَاةِ، وَتَغْمِيضُ الْعَيْنَيْنِ، وَالْبَسْمَلَةُ وَالتَّعَوُّذُ فِي الْفَرِيضَةِ وَيَجُوزَانِ فِي النَّفْلِ، وَالْوُقُوفُ عَلَى رِجْلٍ وَاحِدَةٍ إِلَّا أَنْ يَطُولَ قِيَامُهُ، وَاقْتِرَانُ رِجْلَيْهِ وَجَعْلُ دِرْهَمٍ أَوْ غَيْرِهِ فِي فَمِهِ، وَكَذَلِكَ كُلُّ مَا يُشَوِّشُهُ فِي جَيْبِهِ أَوْ كُمِّهُ أَوْ عَلَى ظَهْرِهِ، وَالتَّفَكُّرُ فِي أُمُورِ الدُّنْيَا، وَكُلُّ مَا يَشْغُلْهُ عَنِ الْخُشُوعِ فِي الصَّلَاةِ.

Wọ́n kọ: (1) Wíwo ìhín wo ọ̀hún lórí ìrun. (2) Dídi ojú. (3) Kíké ‘Bismillahi’ pẹ̀lú ‘Auudu billahi’ níbi ìrun ọ̀ranyàn, kò sì burú níbi àkígbọrẹ (Naafila). (4) Ìdúró lórí ẹsẹ̀ kan (Kátò) fi kírun, áyàfi tí ó bá bùkáátà sí i, latari jíjágùn ìdúró. (5) Lílọ́ ẹsẹ̀ méjéèjì pọ̀ lórí ìrun. (6) Fífi ǹkan (bíi owó dirhamu àti àfijọ rẹ̀) tí ó le dí kíka kéwú dáadáa sẹ́nu lórí ìrun. Bẹ́ẹ̀ náà ni kíkó gbogbo oun tí ó lè se ìdíwọ́ sí àpò asọ, ọwọ́ rẹ̀, àti ara rẹ̀. (7) Ìmaa ronú yòdòyindin ayé lórí ìrun, àti gbogbo oun tí ó lè se ìdíwọ́ fún ìfarabalẹ̀ lórí ìrun.

Sunday, 29 October 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Kẹfà)

فَصْلٌ فِي الْأَوْقَاتِ
ÌPÍN TÍ Ó Ń SÀLÀYÉ ÀWỌN ÀKÓKÒ ÌRUN
اَلْوَقْتُ الْمُخْتَارُ لِلظُّهْرِ مِنْ زَوَالِ الشَّمْسِ إِلَى آخَرَ الْقَامَةِ. وَالْمُخْتَارُ لِلْعَصْرِ مِنْ الْقَامَةِ إِلَى الِاصْفِرَارِ وَضَرُورِيُّهُمَا إِلَى الْغُرُوبِ. وَالْمُخْتَارُ لِلْمَغْرِبِ: قَدْرُ مَا تُصَلَّى فِيهِ بَعْدَ شُرُوطِهَا. وَالْمُخْتَارُ لِلْعَشَاءِ مِنْ مَغِيبِ الشَّفَقِ إِلَى ثُلُثِ اللَّيْلِ الْأَوَّلِ. وَضَرُورِيُّهُمَا إِلَى طُلُوعِ اَلْفَجْرِ. وَالْمُخْتَارُ لِلصُّبْحِ مِنَ الْفَجْرِ إِلَى الْإِسْفَارِ الْأَعْلَى وَضَرُورِيُّهُ إِلَى طُلُوعِ الشَّمْسِ، وَالْقَضَاءُ فِي الْجَمِيعِ مَا وَرَاءَ ذَلِكَ.

Ojúlówó àkókò tí wọ́n sà ní ẹ̀sà fún ìrun Àílà (Zuhr) ní ìgbà tí òòrùn bá yẹ àtààrí parí sí ìgbà tí ìnàró gbogbo ǹkan yóò fi se déédé ara wọn. Àkókò ẹ̀sà fún ìrun Àláásàrì (Asr), àti àsìkò làlúrí fún ìrun àílà (Dhuhr) ni ìgbà tí ìnàró gbogbo ǹkan bá se déédé ara wọn títí ojú ọjọ́ yóò fi di òfééfèé (Yẹ́lò). Nígbà tí àsìkò làlúrí fún ìrun Àílà (Dhuhr) àti àsìkò ẹ̀sà fún àláásàrì (Asr) bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ojú ọjọ́ bá ti di òfééfèé (Yẹ́lò) títí òòrùn yóò fi wọ̀. Àkókò ẹ̀sà fún ìrun Mọ́gáríbì (Magrib) ni òdiwọ̀n ìgbà tí ìrun náà yóò fi jẹ́ kíkí lẹ́yìn tí gbogbo májẹ̀mu ti ó gbe dúró ti pé lẹ́yìn tí òòrùn ti wọ̀. Àkókò ẹ̀sà fún ìrun Ìsháì (Ishai) ni ìgbà tí awòǹpàpà (Tanmọóko) yóò fi wọlé títí di ídá mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú òru. Àsìkò làlúrí fún ìrun Ìsháì sì wà títí di àsìkò lílà àlùfájàrí. Àsìkò ẹ̀sà fún ìrun Àsùnbáà (Subhi) ni ìgbà tí àlùfájàrí bá ti là títí di ìgbà tí òye yóó fi mọ́lẹ̀ kedere. Àsìkò làlúrí rẹ̀ sì lọ títí di ìgbà tí òòrùn yóò fi yọ. Ìrun tí ó bá sì ti bọ́ sí ẹ̀yìn àwọn àsìkò làlúrí ti bọ́ sí ipò gbèsè sísan.

وَمَنْ أَخَّرَ الصَّلَاةَ حَتَّى خَرَجَ وَقْتُهَا فَعَلَيْهِ ذَنْبٌ عَظِيمٌ إِلَّا أَنْ يَكُونَ نَاسِيًا أَوْ نَائِمًا. وَلَا تُصَلَّى نَافِلَةٌ بَعْدَ صَلَاةِ الصُّبْحِ إِلَى ارْتِفَاعِ الشَّمْسِ، وَبَعْدَ صَلَاةِ الْعَصْرِ إِلَى صَلَاةِ الْمَغْرِبِ، وَبَعْدَ طُلُوعِ الْفَجْرِ إِلَّا الْوِرْدَ لِنَائِمٍ عَنْهُ وَعِنْدَ جُلُوسِ إِمَامِ الْجُمُعَةِ عَلَى الْمِنْبَرِ، وَبَعْدَ الْجُمْعَةِ حَتَّى يَخْرُجَ مِنَ الْمَسْجِدِ.

Ẹni tí ó bá lọ́ ìrun lára tí àsìkò rẹ̀ fi kọjá, ẹrù ẹ̀sẹ̀ ńlá ń bẹ lórí rẹ̀, àyàfi tí ó bá gbàgbé tàbí ó sùn lọ. Kò sì sí ìgbàláyè fún àkígbọrẹ (Nafila) lẹ́yìn ìrun Àsùnbáà (Subhi) títí tí òòrùn yóò fi kan àtààrí. Bẹ́ẹ̀ni kó sí fún un lẹ́yìn ìrun Àláásàrì (Asr) títí di àsìkò Mọ́gáríbì (Magrib). Kò sì sí fún un lẹ́yìn tí Àlùfájàrí (Fajr) bá ti là, àyàfi Nafila tí ó sùn gbàgbé láti se. Kò tún sí fún un lẹ́yìn tí ìmámù bá ti gun pẹpẹ (Minbari) ní ọjọ́ Jímọ̀, àti lẹ́yìn ìrun Jímọ̀ títí tí yóò fi jáde ní Mọ́sálásí.

فَصْلٌ فِي شُرُوطِ الصَّلَاةِ
ÌPÍN TÍ Ó Ń SÀLÀYÉ ÀWỌN MÁJẸ̀MÚ ÌRUN

وَشُرُوطُ الصَّلَاةِ طَهَارَةُ الْحَدَثِ وَطَهَارَةُ الْخَبَثِ مِنَ الْبَدَنِ وَالثَّوْبِ وَالْمَكَانِ وَسَتْرُ الْعَوْرَةِ وَاسْتِقْبَالُ الْقِبْلَةِ، وَتَرْكُ الْكَلَامِ وَتَرْكُ الْأَفْعَالِ الْكَثِيرَةِ. وَعَوْرَةُ الرَّجُلِ مَا بَيْنَ السُّرَّةِ وَالرُّكْبَةِ، وَالْمَرْأَةُ كُلُّهَا عَوْرَةٌ مَا عَدَا الْوَجْهَ وَالْكَفَّيْنِ. وَتُكْرَهُ الصَّلَاةُ فِي السَّرَاوِيلِ، إِلَّا إِذَا كَانَ فَوْقَهَا شَيْءٌ. وَمَنْ تَنَجَّسِ ثَوْبُهُ وَلَمْ يَجِدْ ثَوْبًا غَيْرَهُ وَلَمْ يَجِدْ مَاءً يَغْسِلُهُ بِهِ أَوْ لَمْ يَكُنْ عِنْدَهُ مَا يَلْبَسُ حَتَّى يَغْسِلَهُ وَخَافَ خُرُوجَ الْوَقْتِ صَلَّى بِنَجَاسَتِهِ. وَلَا يَحِلُّ تَأْخِيرُ الصَّلَاةِ لِعَدَمِ اَلطَّهَارَةِ، وَمَنْ فَعَلَ ذَلِكَ فَقَدْ عَصَى رَبَّهُ. وَمَنْ لَمْ يَجِدْ مَا يَسْتُرُ بِهِ عَوْرَتَهُ صَلَّى عُرْيَانًا. وَمَنْ أَخْطَأَ الْقِبْلَةَ أَعَادَ فِي الْوَقْتِ، وَكُلُّ إِعَادَةٍ فِي الْوَقْتِ فَهِيَ فَضِيلَةٌ. وَكُلُّ مَا تُعَادُ مِنْهُ الصَّلَاةُ فِي الْوَقْتِ فَلَا تُعَادُ مِنْهُ الْفَائِتَةُ وَالنَّافِلَةُ.

Àwọn májẹ̀mú ni: (1) Ìmọra níbi ẹ̀gbin. (2) Ìmú ẹ̀gbin kúrò ní ara, asọ, àti ààyè ìkírun. (3) Bíbo ìhòòhò. (4) Dídojúkọ kàábà. (5) Gbígbé ọ̀rọ̀ sísọ (Tí ó bá yàtọ̀ sí oun tí a fí ń se ìjọsìn ìrun) jù sílẹ̀. (6) Gbígbé isẹ́ ọlọ́pọ̀lọpọ̀ (Tí ó bá yàtọ̀ sí àwọn tí a fí ń se ìjọsìn ìrun) jù sílẹ̀.  Ìhòòhò ọkùnrin lórí ìrun ni àlàfo ìdajì ara (Ìdodo) títí dé orúnkún rẹ̀. Ìhòòhò obìnrin sì ni gbogbo ara rẹ̀ pátá tí a bá yọwọ́ ojú àti àtẹlẹwọ́ rẹ̀ méjéèjì. Wọ́n sì kọ kíkí ìrun pẹ̀lu sòkòtò lásán láì kò wọ ǹkan sí òkè rẹ̀. Ẹni tí ẹ̀gbin bá wà ní ara asọ rẹ̀, tí ó sàfẹ́kù asọ míràn, tí kò sì rí omi tí ó lè fi mọ́ ọn, tàbí kò ní asọ òmíràn tí ó le fi sọ́rùn láti fi se ìmọ́tótó èyí tí ẹ̀gbin ńbẹ lára rẹ̀, tí ó sì ń bẹ̀rù kí àsìkò ìrun má jáde mọ́ ọn lọ́wọ́, Ó lè kírun pẹ̀lú ẹ̀gbin tí ó wà lára asọ rẹ̀.  Lílọ́ ìrun lára kò tọ́ ní tìtorí àìmọ́ra, ẹni tí ó bá fi ìrun lọ́ra nítorí ìdí yí ti dá ẹ̀sẹ̀ sí Ọlọ́hun ọba rẹ̀.  Ẹni tí ó bá sì se àfẹ́kù oun tí ó lè fi bo ìhòòhò rẹ̀, yóò kí ìrun rẹ̀ ní ìhòòhò náà ni. Ẹni tí ó bá sì se àsìyàn ibùdojúkọ kírun (Kibla) yóò tun kí lópin ìgbà tí àsìkò ìrun náà kò bá tíì jáde. Gbogbo ààyè tí wọ́n bá ti fẹ́ sísan ìrun padà lópin ìgbà tí àsìkò ìrun kò bá tíì jáde ń dá lórí wípé “Ọlá ńbẹ níbi síse é”, “Bí ènìyàn kò bá sì sé, kò buru”. Gbogbo ìse tí ó bá sì bèèrè fún sísan ìrun padà lópin ìgbà tí àsìkò rẹ̀ kò bá tíì jáde, èyí tí ó bá ti jáde àti àkígbọrẹ (Naafila) kò níí jẹ́ sísan padà nítorí wọn.

فَصْلٌ: فَرَائِضُ الصَّلَاةِ: نِيَّةُ الصَّلَاةِ الْمُعَيَّنَةِ، وَتَكْبِيرَةُ الْإِحْرَامِ وَالْقِيَامُ لَهَا، وَالْفَاتِحَةُ وَالْقِيَامُ لَهَا، وَالرُّكُوعُ وَالرَّفْعُ مِنْهُ، وَالسُّجُودُ عَلَى الْجَبْهَةِ وَالرَّفْعُ مِنْهُ، وَالِاعْتِدَالُ، وَالطُّمَانِينَةُ، وَالتَّرْتِيبُ بَيْنَ فَرَائِضِهَا، وَالسَّلَامُ وَجُلُوسُهُ الَّذِي يُقَارِنُهُ.

Ẹ̀kọ́ Míràn- Àwọn Ọ̀ranyàn Ìrun ni: (1) Mímú àníyàn irú ìrun tí a fẹ́ẹ́ kí gan gan wá. (2) Gbígbé kábárá (Allahu Akbar tí a fí ń sọ gbogbo ìse àti ọ̀rọ̀ míràn tí ó yàtọ̀ sí èyí tí a fi ń se ìjọsìn ìrun di èèwọ̀). (3) Dìdúró gbé kábárá. (4) Kíka ọgbà ọ̀rọ̀ ìsí Alukuraani (Suratul Faatiha). (5) Dìdúró ka ọgbà ọ̀rọ̀ ìsí Alukuraani (Suratul Faatiha). (6) Títẹríba (Rukuu). (7) Sísí orí kúrò ní ítẹríba (Rukuu). (8) Fífi iwájú orí kanlẹ̀ (Sujuudu). (9) Gbígbé orí nílẹ̀. (10) Dídúró dáradára lẹ́yìn ísí orí kúrò ní ítẹríba (Rukuu), àti ìjókó dáradára lẹ́yìn gbígbé orí nílẹ̀. (11) Fífara balẹ̀ níbi ìdúró àti ìjòkó. (12) Tító àwọn ọ̀ranyàn ìrun yí tẹ̀lé ara wọn. (13) Píparí ìrun pẹ̀lú sálámọ̀. (14) Jíjòkó sálámọ̀.

(وَشَرْطُ) النِّيَّةِ مُقَارَنَتُهَا لِتَكْبِيرَةِ الْإِحْرَامِ.

Májẹ̀mu àníyàn ni síse é mọ́ kábárá (Allahu Akbar tí a fí ń sọ gbogbo ìse àti ọ̀rọ̀ míràn tí ó yàtọ̀ sí èyí tí a fi ń se ìjọsìn ìrun di èèwọ̀).

(وَسُنَّتُهَا): الْإِقَامَةُ، وَالسُّورَةُ الَّتِي بَعْدَ الْفَاتِحَةِ، وَالْقِيَامُ لَهَا، وَالسِّرُّ فِيمَا يُسَرُّ فِيهِ، وَالْجَهْرُ فِيمَا يُجْهَرُ فِيهِ، وَسَمِعَ اللَّهُ لِمَنْ حَمِدَهُ. وَكُلُّ تَكْبِيرَةٍ سُنَّةٌ إِلَّا الْأُولَى وَالتَّشَهُّدَانِ وَالْجُلُوسُ لَهُمَا، وَتَقْدِيمُ الْفَاتِحَةِ عَلَى السُّورَةِ وَالْتَّسْلِيمِةُ الثَّانِيَةُ وَالثَّالِثَةُ لِلْمَأْمُومِ، وَالْجَهْرُ بَالتَّسْلِيمِةِ الْوَاجِبَةِ، وَالصَّلَاةُ عَلَى رَسُولِ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، وَالسُّجُودُ عَلَى الْأَنْفِ وَالْكَفَّيْنِ وَالرُّكْبَتَيْنِ وَأَطْرَافِ الْقَدَمَيْنِ وَالسُّتْرَةُ لِغَيْرِ الْمَأْمُومِ وَأَقَلُّهَا غِلَظُ رُمْحٍ وَطُولُ ذِرَاعٍ طَاهِرٍ ثَابِتٍ غَيْرِ مُشَوَّشٍ.


Ìlànà Ànábì Lórí Ìrun Kíkí ni: (1) Gbígbé ìrun dúró (Ìkáámà). (2) Kíka ọgbà ọ̀rọ̀ (Suura) míràn lẹ́yín ọgbà ọ̀rọ̀ ìsí Alukuraani (Suratul Faatiha). (3) Dídúró ka ọgbà ọ̀rọ̀ (Suura) míràn. (4) Kíka kéwú jẹ́ẹ́jẹ́ láàyè rẹ̀. (5) Kíka kéwú sókè láàyè rẹ̀. (6) Wíwí gbólóhùn “Semial lahu liman hamdau” níbi sísí orí kúrò ní ítẹríba (Rukuu). (7) Gbogbo kábárà tí ó bá ti yàtọ̀ sí kábárà ìbẹ̀rẹ̀ ìrun. (8) Síse àtááyá méjéèjì. (9) Jíjòkó se àtááyá méjéèjì. (10) Kíka ọgbà ọ̀rọ̀ ìsí Alukuraani (Suratul Faatiha) síwájú ọgbà ọ̀rọ̀ (Suura) míràn. (11) Síse sálámọ̀ kejì àti ìkẹta fún olùtẹ̀lé ìmáámù ní ìparí ìrun. (12) Gbígbé òhùn sókè se sálámọ̀ àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ọ̀ranyàn. (13) Síse ìtọrọ ìkẹ́ àti ìgẹ̀ fún Ànábì (Àsàláátù) níbi àtááyá ìkángun ìrun. (14) Fífi imú, àtẹlẹwọ́ méjéèjì, orúnkún méjéèjì, àwọn ọmọníka ẹsẹ̀ méjéèjì lẹ́lẹ̀ níbi ìforí kanlẹ̀. (15) Lílo agàgá fún ìmáámù. Agàgá yí kéré jù aò rí irú rẹ̀ rí ni kí ó nípọn bí ọ̀kọ̀, kí ó sì gùn ní òdiwọ̀n ìgbùnwọ́ kan tí ó mọ́, tí ó le dúró sinsin, tí kò sì níí jẹ́ oun ìdíwọ́ fún olùkírun.

Thursday, 26 October 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Karùn)

فَصْلٌ فِي الْحَيْضِ
ÌPÍN TÍ Ó Ń SÀLÀYÉ ǸKAN OSÙ OBÌNRIN (ÉÉLÀ)

وَالنِّسَاءُ مُبْتَدَأَةٌ وَمُعْتَادَةٌ وَحَامِلٌ، وَأَكْثَرُ الْحَيْضِ لَلْمُبْتَدِأَةِ خَمْسَةَ عَشَرَ يَوْمًا. وَلِلْمُعْتَادَةِ عَادَتُهَا. فَإِنْ تَمَادَى بِهَا الدَّمُ زَادَتْ ثَلَاثَةَ أَيَّامٍ مَا لَمْ تُجَاوِزْ خَمْسَةَ عَشَرَ يَوْمًا. وَلِلْحَامِلِ بَعْدَ ثَلَاثَةِ أَشْهُر خَمْسَةَ عَشَرَ يَوْمًا وَنَحْوُهَا، وَبَعْدَ سِتَّةِ أَشْهُرٍ عِشْرُونَ وَنَحْوُهَا، فَإِنْ تَقَطَّعَ الدَّمُ لَفَّقَتْ أَيَّامَهُ حَتَّى تُكَمِّلَ عَادَتَهَا. وَلَا يَحِلُّ لِلْحَائِضِ صَلَاةٌ وَلَا صَوْمٌ وَلَا طَوَافٌ وَلَا مَسُّ مُصْحَفٍ وَلَا دُخُولُ مَسْجِدٍ. وَعَلَيْهَا قَضَاءُ الصَّوْمِ دُونَ الصَّلَاةِ، وَقِرَاءَتُهَا جَائِزَةٌ، وَلَا يَحِلُّ لِزَوْجِهَا فَرْجُهَا وَلَا مَا بَيْنَ سُرَّتِهَا وَرُكْبَتَيْهَا حَتَّى تَغْتَسِلَ.

Ìran obinrin níbi ǹkan osù síse lè jẹ́: (1) Olùsẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀, (2) Ẹni tí kò sẹ̀sẹ̀ maa se ǹkan osù (Ẹni tí ǹkan osù ti di àláádà rẹ̀), (3) Àti Aboyún. Ó pọ̀jù, a kò rí irú rẹ̀ rí làti fi se ǹkan osù fún olùsẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún (15). Ó sì pọ̀jù, a kò rí irú rẹ̀ rí làti fi se ǹkan osù fún ẹni tí kò sẹ̀sẹ̀ maa se ǹkan osù (Ẹni tí ǹkan osù ti di àláádà rẹ̀) ni iye ọjọ́ tí ó ti bá sáábà láti máá fi sé tẹ́lẹ̀. Tí ẹ̀jẹ̀ ǹkan osù bá wáá kọ̀ tí ó se aláìdá ní àsìkò tí ó tí ó ti bá sáábà dídá, olùse ǹkan osù yóò wo ojú rẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta si kí ó tóó di ẹ̀jẹ̀ àwọ́ọ̀dá, lópin ìgbà tí ọjọ́ ǹkan osù kò bá tíì pé ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún (15) tẹ́lẹ̀, tàbí kò níí lé ní ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún (15) nígbà tí ọjọ́ mẹ́ta bá gùn ún  (Tí ọjọ́ tí ó wà láàrin àláádà rẹ̀ sí ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún (15) kò bá tó mẹ́ta, iye ọjọ́ tí ó bá kù tí yóò fi pé ni yóò fi kún un, gẹ́gẹ́ bíi méjì tàbí ẹyọkan). Sùgbọ́n fún ìran aboyun, ó pọ̀jù, a kò rí irú rẹ̀ rí làti fise ǹkan osù fún un –ìyẹn tí ǹkan osù rẹ̀ bá tún ń wá lasiko tí ó diwọ́ disẹ̀ sinu- lẹ́yìn osù mẹ́ta alákọ̀kọ́, ni ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún (15) àti oun tí ó sún mọ́ ọn. Ó sì pọ̀jù, a kò rí irú rẹ̀ rí làti fise ǹkan osù fún un lẹ́yìn tí osù mẹ́fà ti kọjá ni ogúnjọ́ (20) àti oun tí ó sún mọ́ ọn. Tí ẹ̀jẹ̀ ǹkan osù aboyún bá wáá ń wá ségesège –bíi kó wá fún ígbà díẹ̀, kó dá fún ìgbà díẹ̀- yóò só àwọn ọjọ́ náà pọ̀ tí yóò fi pé iye ọjọ́ àláádà rẹ̀ tàbi ọjọ́ tí ó pọ̀ jùlọ tí ó yẹ kó fi sé, kí ó tóó gbe síipò àwọ́ọ̀dá. Kò tọ́ fún obinrin tí ó ń se ǹkan osù (Éélà) lọ́wọ́ kí ó kí ìrun, kí ó gba ààwẹ̀, kí ó pòòrì ilé Ọlọ́hun (Kaaba), kí ó gbá ìwé mímọ́ (Àlùkùráánì) mú, àti kí ó wọ mọ́sálásí. Ọ̀ranyàn ni fún un kí ó san ààwẹ̀ tí ó bá jẹ ní àsìkò tí ó ń se ǹkan osù (Éélà) lọ́wọ́. Kò sì níí san ìrun tí ó bá bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́ lasiko yí. Ìgbàláyè wà fún un láti yọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Àlùkùráánì) kà. Kò sì sí ìgbàláyè fún ẹlẹ́tọ́ (Ọkọ) rẹ̀ láti súnmọ́ níbi ojú ara rẹ̀, áti gbígbádùn pẹ̀lú ààyè tíó wà ní àlàfo ìdajì ara (Ìdodo) rẹ̀ titi dé ibi orúnkún, títí tí yóó fi mọ́ra.

فَصْلٌ فِي النِّفَاسِ
ÌPÍN TÍ Ó Ń SÀLÀYÉ Ẹ̀JẸ̀ ÌBIMỌ OBÌNRIN (NIFAASI)

وَالنِّفَاسُ كَالْحَيْضِ فِي مَنْعِهِ، وَأَكْثَرُهُ سِتُّونَ يَوْمًا. فَإِذَا انْقَطَعَ الدَّمُ قَبْلَهَا وَلَوْ فِي يَوْمِ الْوِلَادَةِ، اغْتَسَلَتْ وَصَلَّتْ. فَإِذَا عَاوَدَهَا الدَّمُ، فَإِنْ كَانَ بَيْنَهُمَا خَمْسَةَ عَشَرَ يَوْمًا فَأَكْثَرَ كَانَ الثَّانِي حَيْضًا، وَإِلَّا ضُمَّ إِلَى الْأَوَّلِ وَكَانَ مِنْ تَمَامِ اَلنِّفَاسُ.

Ẹ̀jẹ̀ ìbimọ (Nifaasi) kó yàtọ̀ sí ẹ̀jẹ̀ ǹkan osù (Éélà) níbi àwọn ǹkan tí ìgbàláyè àti èyí tí kò sì ìgbàláyè fún síse wọ́n. Ó pọ̀jù, a kò rí irú rẹ̀ rí fún obìnrin làti fi se ẹ̀jẹ̀ ìbimọ (Nifaasi)  ni ọgọ́ta ọjọ́ (60). Tí ẹ̀jẹ̀ ìbimọ bá dá síwájú ọgọ́ta ọjọ́ (60), koda kí ó jẹ́ ọjọ́ tí ọmọ waye náà ni, ẹni tí ó bímọ náa yóó wẹ̀, yóó sì máa kí ìrun. Tí ó bá tún wáá rí ẹ̀jẹ̀ míràn lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún (15) lọ sókè -lẹ́yìn tí ẹ̀jẹ̀ ìbimọ ti kọ́kọ́ dá- ipò ẹ̀jẹ̀ ǹkan osù (Éélà) ni yóó gbe sí. Tí kò bá tó ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún (15) tí ó fi rí ẹ̀jẹ̀ padà -lẹ́yìn tí ẹ̀jẹ̀ alákọ̀kọ́ ti dá- yóò si mọ́ ẹ̀jẹ̀ ìbimọ (Nifaasi), tí yóò maa jẹ́ ìparí rẹ̀.

Friday, 20 October 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Kẹrin)

فَصْلٌ فِي التَّيَمُّمِ
ÌPÍN TÍ Ó Ń SÀLÀYÉ ÀLÙWÀLÁ ELÉÉPẸ̀ (TÁYÀMỌ́MÙ)

وَيَتَيَمَّمُ الْمُسَافِرُ فِي غَيْرِ مَعْصِيَةٍ، وَالْمَرِيضُ لِفَرِيضَةٍ أَوْ نَافِلَةٍ. وَيَتَيَمَّمُ الْحَاضِرُ الصَّحِيحُ لِلْفَرَائِضِ إِذَا خَافَ خُرُوجَ وَقْتِهَا. وَلَا يَتَيَمَّمُ الْحَاضِرُ الصَّحِيحُ لِنَافِلَةٍ وَلَا جُمُعَةٍ وَلَا جِنَازَةٍ إِلَّا إِذَا تَعَيَّنَتْ عَلَيْهِ الْجَنَازَةُ.

Arìn ìrìn àjó tí ìrìn àjó rẹ̀ kìí se ìrìn àjò ẹ̀sẹ̀, àti aláárẹ̀ lè se àlùwàlá eléépẹ̀ (Táyàmọ́mù) láti fi kí ìrun ọ̀ranyàn tàbí àkígbọrẹ (Nááfílà) nígbà tí wọ́n bá se àfẹ́kù omi. Aláìrìnrìn àjò tàbí onílé tí ó dápé, tí ó se àfẹ́kù omi náà lè se àlùwàlá eléépẹ̀ (Táyàmọ́mù) láti fi kí ìrun ọ̀ranyàn, nígbà tí ó bá ń bẹ̀rù kí àkókò ìrun má lọ mọ́ ọn lọ́wọ́. Kò sì lẹ́tọ́ fún aláìrìnrìn àjò tàbí onílé tí ó dápé, tí ó se àfẹ́kù omi láti se àlùwàlá eléépẹ̀ (Táyàmọ́mù) láti fi kí ìrun àkígbọrẹ (Nááfílà), ìrun Jímọ̀, àti ìrun kiki sí òkú lára. Àyàfi tí kò bá sí ẹlòmíràn tí ó dé ipò kí ó kí ìrun sí òkú lára lẹ́yìn rẹ̀.

(وَفَرَائِضُ التَّيَمُّمِ): النِّيَّةُ وَالصَّعِيدُ الطَّاهِرُ، وَمَسْحُ الْوَجْهِ وَمَسْحُ الْيَدَيْنِ إِلَى الْكُوعَيْنِ، وَضَرْبَةُ الْأَرْضِ الْأُولَى وَالْفَوْرُ، وَدُخُولُ الْوَقْتِ وَاتِّصَالُهُ بِالصَّلَاةِ. وَالصَّعِيدُ هُوَ التُّرَابُ وَالطُّوبُ، وَالْحَجَرُ، وَالثَّلْجُ وَالْخَضْخَاضُ وَنَحْوُ ذَلِكَ. وَلَا يَجُوزُ بِالْجِص اَلْمَطْبُوخِ وَالْحَصِيرِ وَالْخَشَبِ وَالْحَشِيشِ وَنَحْوِهِ، وَرُخِّصَ لِلْمَرِيضِ فِي حَائِطِ الْحَجَرِ وَالطُّوبِ إِنْ لَمْ يَجِدْ مُنَاوِلًا غَيْرَهُ.

Àwọn ọ̀ranyàn àlùwàlá eléépẹ̀ (Táyàmọ́mù) ni; (1) Dída àníyàn, (2) Ibi tí ó mọ́ ní ojú ilẹ̀, (3) Pípá ojú, (4) Pípá ọwọ́ méjéèjì títí dé ọrùn ọwọ́, (5) Fífi ọwọ́ lu ilẹ̀ ní ìgbà àkọ́kọ́, (6) Yíyára se àwọn oríké táyàmọ́mù tẹ̀lé ara wọn, (7) Wíwọlé àsìkò ìrun síwájú síse àlùwàlá eléépẹ̀ (Táyàmọ́mù), (8) Síse àlùwàlá eléépẹ̀ (Táyàmọ́mù) mọ́ àsìkò ìrun kíkí. Oun tí wọ́n ń pè ní ojú ilẹ̀ ni iyẹ̀ẹ̀pẹ̀, àkàsù iyẹ̀ẹ̀pẹ̀ (Bíríkì), òkuta, yìnyín, iyẹ̀ẹ̀pẹ̀ múlọ́múlọ́, àti àwọn tí ó bá tún rí bíi wọn. Táyàmọ́mù kò sì lẹ́tọ́ síse pẹ̀lú pílásítà, pòpórò ẹní, pákó, igi, koríko, àti àwọn tí ó bá tún rí bíi wọn. Ìgbà láyè wà fún aláìlera kí ó fi ọwọ́ pa ògiri tí wọ́n mọ pẹ̀lú òkuta, àti èyí tí wọ́n fi bíríkì mọ, nígbà tí kò bá rí ǹkan míràn tí ó lè fi se àlùwàlá eléépẹ̀ (Táyàmọ́mù) tayọ àwọn ǹkan wọ̀nyí.

(وَسُنَنُهُ): تَجْدِيدُ الصَّعِيدِ لِيَدَيْهِ وَمَسْحُ مَا بَيْنَ الْكُوعَيْنِ وَالْمِرْفَقَيْنَ، وَالتَّرْتِيبُ.

Àwọn ìlànà ànábì lórí ìwẹ̀ àlùwàlá eléépẹ̀ (Táyàmọ́mù) ni: (1) Títún ọwọ́ fi kan ojú ilẹ̀ nígbà tí ó bá fẹ́ pá ọwọ́ rẹ̀ méjéèjì, (2) Pípá ọrùn ọwọ́ sí ìgbùnwọ́, (3) Títo àwọn ààyè àlùwàlá eléépẹ̀ (Táyàmọ́mù) tẹ̀lé ara wọn, kí ó sì má sé ní pasípayọ.

وَفَضَائِلُهُ التَّسْمِيَةُ وَتَقْدِيمُ الْيُمْنَى عَلَى الْيُسْرَى وَتَقْدِيمُ ظَاهِرِ الذِّرَاعِ عَلَى بَاطِنِهِ وَمُقَدِّمِهِ عَلَى مُؤَخِّرِهِ.

Àwọn oun tí wọ́n fẹ́ síse wọn níbi àlùwàlá eléépẹ̀ (Táyàmọ́mù) ni: (1) Bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́hun (Bismillah), (2) Pípá apá ọ̀tún síwájú òsì, (3) Pípá iwájú orí síwájú ẹ̀yìn rẹ̀.

(وَنَوَاقِضُهُ): كَالْوُضُوءِ وَلَا تُصَلَّى فَرِيضَتَانِ بِتَيَمُّمٍ وَاحِدٍ. وَمَنْ تَيَمَّمَ لِفَرِيضَةٍ جَازَ لَهُ النَّوَافِلُ بَعْدَهَا وَمَسُّ الْمُصْحَفِ، وَالطَّوَافُ وَالتِّلَاوَةُ إِنْ نَوَى ذَلِكَ وَاتَّصَلَتْ بِالصَّلَاةِ وَلَمْ يَخْرُجِ الْوَقْتُ، وَجَازَ بِتَيَمُّمِ النَّافِلَةِ كُلُّ مَا ذُكِرَ إِلَّا الْفَرِيضَةَ، وَمَنْ صَلَّى الْعِشَاءَ بِتَيَمُّمٍ قَامَ لِلشَّفْعِ وَالْوَتْرِ بَعْدَهَا مِنْ غَيْرِ تَأْخِيرٍ، وَمَنْ تَيَمَّمَ مِنْ جَنَابَةٍ فَلَا بُدَّ مِنْ نِيَّتِهَا.

Àwọn oun tí ó lè ba Táyàmọ́mù jẹ́ kò yàtọ̀ sí àwọn oun tí ó lè ba àlùwàlá olómi jẹ́. Táyàmọ́mù kan soso kò sì séé fi kí ìrun ọ̀ranyàn méjì papọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì se táyàmọ́mù fi kí ìrun ọ̀ranyàn kan, ààyè gbà á láti fi yan nafila (Ìrun àkígbọrẹ) lẹ́yìn rẹ̀, àti láti gbá ìwé mímọ́ (Àlùkùráánì) mú, ààyè tún gbà á láti fi pòòrì ilé Ọlọ́hun ni Mákkà (Kàábà), àti láti ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Àlùkùráánì). Lópin ígbà tí ó bá ti da aniyan síse àwọn isẹ́ yìí lasiko tí ó ńse táyàmọ́mù fún ìrun ọ̀ranyàn, tí síse àwọn isẹ́ náà sì bẹ̀rẹ̀ ní kete tí ó kí ìrun ọ̀rànyàn tán, tí àsìkò ìrun ọ̀ranyan tí ó se táyàmọ́mù fún kò sì tíì jáde. Ó lẹ́tọ́ pẹ̀lú kí ó fi táyàmọ́mù tí ó fi sọrí nafila (Ìrun àkígbọrẹ) se àwọn isẹ́ tí wọ̀nyí àyàfi ìrun ọ̀ranyàn. Ẹni tí ó bá fi táyàmọ́mù kí ìrun Ishai lè fi yan nafila (Ìrun àkígbọrẹ) oní méjìméjì (Shafui) àti ẹlẹ́yọkan lẹ́yìn rẹ̀, láì kò fi falẹ̀ rárá. Ẹni tí ó bá sì jẹ́ ẹ̀gbin jánábà tí ó wà lára rẹ̀ ni ó torí rẹ̀ se táyàmọ́mù gbudọ̀ ni àníyàn ìmú ẹ̀gbin jánábà kúrò ní ara láti ìbẹ̀rẹ̀ síse rẹ̀, kí ìrun rẹ̀ lè ní àlààfíà.

Saturday, 14 October 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Kẹta)

فَصْلٌ: يَجِبُ الْغُسْلُ مِنْ ثَلَاثَةِ أَشْيَاءَ: اَلْجَنَابَةِ وَالْحَيْضِ وَالنِّفَاسِ.
فَالْجَنَابَةُ قِسْمَانِ: أَحَدُهُمَا خُرُوجُ الْمَنِيِّ بِلَذَّةٍ مُعْتَادَةٍ فِي نَوْمٍ أَوْ يَقَظَةٍ بِجِمَاعٍ أَوْ غَيْرِهِ. وَالثَّانِي: مَغِيبُ الْحَشَفَةِ فِي الْفَرْجِ. وَمَنْ رَأَى فِي مَنَامِهِ كَأَنَّهُ يُجَامِعُ وَلَمْ يَخْرُجْ مِنْهُ مَنِيٌّ فَلَا شَيْءَ عَلَيْهِ، وَمَنْ وَجَدَ فِي ثَوْبِهِ مَنِيًّا يَابِسًا لَا يَدْرِي مَتَى أَصَابَهُ اغْتَسَلَ وَأَعَادَ مَا صَلَّى مِنْ آخِرِ نَوْمِةٍ نَامَهَا فِيهِ.

Ẹ̀kọ́ míràn: Ìwẹ̀ òfin di ọ̀ranyàn níbi ǹkan mẹ́ta; lílu jánábà, ẹ̀jẹ̀ ǹkan osù obìnrin (Éélà), ẹ̀jẹ̀ ìbimọ (Nìfáásì). Jánábà ní ìpín méjì:
Àkọ́kọ́: jíjáde àtọ̀ (látààrí ìgbadùn tí a ti mọ̀) ní ojú oorun tàbí lójú ayé, kò bá ǹ jẹ́ pẹ̀lú níní àsepọ̀ pẹ̀lú obìnrin tàbí pẹ̀lú ǹkan míràn.
Ìkejì: kí òdiwọ̀n adéńdérí abẹ́ ọkùnrin wọ abẹ́ obìnrin. Ẹni tí ó bá lá àlá tí ó rí ní ojúran wípe òun ń ní àsepọ̀ pẹ̀lú obìnrin tí kò sì rí orípa àtọ̀ nígbà tí ó lajú, kò bùkáátà kí ó wẹ̀ ìwẹ̀ òfin. Ẹni tí ó bá orípa àtọ̀ tí ó ti gbẹ, tí kò mọ ìgbà tí ó jáde lára rẹ̀, ẹni náà yóó wẹ̀, yóò sì dá àwọn ìrun tí ó ti kí láti ẹ̀yìn oorun tí ó sùn gbẹ̀yìn di àkókò tí ó rántí padà.

فَصْلٌ: فَرَائِضُ الْغُسْلِ: النِّيَّةُ عِنْدَ الشُّرُوعِ وَالْفَوْرُ وَالدَّلْكُ وَالْعُمُومُ.

Ẹ̀kọ́ míràn: àwọn ọ̀ranyàn ìwẹ̀ òfin ni; (1) dída àníyàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwẹ̀, (2) yíyára wẹ̀ ìwẹ̀ òfin, (3) fífi ọwọ́ gbo ara ní àsìkò ìwẹ̀, (4) fífi omi kárí ara.

(وَسُنَنُهُ): غَسْلُ الْيَدَيْنِ إِلَى الْكُوعَيْنِ كَالْوُضُوءِ، وَالْمَضْمَضَةُ وَالِاسْتِنْشَاقُ وَالِاسْتِنْثَارُ، وَغَسْلُ صِمَاخِ الْأُذُنِ وَهِيَ الثُقْبَةُ الدَّاخِلَةُ فِي الرَّأْسِ. وَأَمَّا صَحْفَةُ الْأُذُنِ فَيَجِبُ غَسْلُ ظَاهِرِهَا وَبَاطِنِهَا.

Àwọn ìlànà ànábì lórí ìwẹ̀ òfin ni: (1) wíwẹ ọwọ̀ mèjèèjì títí dé ọrùn ọwọ́ bíi ti àlùwàlá, (2) yíyọ ẹnu, (3) fífín imú, (4) fífọn omi tí a fín sinu ihò imú sí ìta padà, (5) fífọ inú ihò etí. Òun ni ihò tí ó lu já inú agbárí. Ọ̀ranyàn sì ni fífọ inú àti òde ẹ̀rọ etí.

(وَفَضَائِلُهُ): الْبِدَايَةُ بِغَسْلِ النَّجَاسَةِ ثُمَّ الذَّكَرِ فَيَنْوِي عِنْدَهُ، ثُمَّ أَعْضَاءِ الْوُضُوءِ مَرَّةً مَرَّةً، ثُمَّ أَعْلَى جَسَدِهِ، وَتَثْلِيثُ غُسْلِ الرَّأْسِ، وَتَقْدِيمُ شِقِّ جَسَدِهِ الْأَيْمَنِ، وَتَقْلِيلُ الْمَاءِ عَلَى الْأَعْضَاءِ. وَمَنْ نَسِيَ لُمْعَةً أَوْ عُضْوًا مِنْ غُسْلِهِ بَادَرَ إِلَى غَسْلِهِ حِينَ تَذَكُّرِهِ، وَلَوْ بَعْدَ شَهْرٍ، وَأَعَادَ مَا صَلَّى قَبْلَهُ. وَإِنْ أَخَّرَهُ بَعْدَ ذِكْرِهِ بَطَلَ غَسْلُهُ. فَإِنْ كَانَ فِي أَعْضَاءِ الْوُضُوءِ وَصَادَفَهُ غَسْلُ الْوُضُوءِ أَجْزَأَهُ.

Àwọn oun tí wọ́n fẹ́ síse wọn níbi ìwẹ̀ òfin ni: (1) bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mímú ẹ̀gbin kúrò ní ara, (2) lẹ́yìn náà ni fífọ abẹ́ rẹ̀ (Àsákàrí), níbi fífọ abẹ́ rẹ̀ ni yóò sì ti da àníyàn, (3) lẹ́yìn náà ni síse àwọn iburè àlùwàlá ní ìgbà kọ̀ọ̀kan, (4) lẹ́yìn náà ni wíwẹ òkè ara rẹ̀, (5) fífọ orí ní ìgbà mẹ́ta, (6) wíwẹ abala ọ̀tún ara síwájú abala òsì, (7) lílo omi níwọ̀n níbi wíwẹ̀ àwọn iburè náà. Ẹni tí ó bá gbàgbé wíwẹ̀ ààyè tàbí iburè kan, kí ó yára tete wẹ̀ ẹ́ ní ìgbàkígbà tí ó bá ti rántí, kò bá ǹjẹ́ lẹ́yìn osù kan, kí ó sì san àwọn ìrun tí ó ti kí síwájú rẹ̀. Tí ó bá wáá fi wíwẹ̀ rẹ̀ falẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti rántí, ìwẹ̀ òfin tí ó wẹ̀ ti bàjẹ́. Tí ó bá wáá jẹ́ wípé ààyè àlùwàlá ni ó gbàgbé, sùgbọ́n tí omi ìwẹ̀ ti ré kọjá lórí ààyè náà, ìwẹ̀ òfin rẹ̀ kò bàjẹ́.
   
فَصْلٌ: لَا يَحِلُّ لِلْجُنُبِ دُخُولُ الْمَسْجِدِ، وَلَا قِرَاءَةُ الْقُرْآنِ إِلَّا الْآيَةَ وَنَحْوَهَا لِلتَّعَوُّذِ وَنَحْوِهِ. وَلَا يَجُوزُ لِمَنْ لَا يَقْدِرُ عَلَى الْمَاءِ الْبَارِدِ أَنْ يَأْتِيَ زَوْجَتَهُ حَتَّى يُعِدَّ الْآلَةَ إِلَّا أَنْ يَحْتَلِمَ، فَلَا شَيْءَ عَلَيْهِ.  

Ẹ̀kọ́ míràn: kò lẹ́tọ́ fún ẹni tí ó bá ní jánábà lára kí ó wọ ilé ìjọsìn (Masálásí), kò sì lẹ́tọ́ fún un láti ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Àlùkùráánì) àyàfi bíi ẹsẹ kan (aayah) àti oun tí ó bá súnmọ́ ọn tí ó yọ kà láti fi wá ìsọ́ Ọlọ́hun. Kò sì lẹ̀tọ́ fún ẹni tí kò lágbára láti fi omi tutu wẹ̀ kí ó súnmọ́ ìyàwó rẹ̀ titi yóó fi pèsè irin isẹ́ amú omi lọ́ wọ́ọ́rọ́. Àyàfi tí ó bá jẹ́ wípé ó tí lá àlá da ǹkan sí ara tẹ́lẹ̀, kòburú kí ó súnmọ́ ìyàwó rẹ̀. 

The timeless lessons from Abū Bakr’s companionship with the Prophet ﷺ during the migration to Madinah

  كِتَابُ فَضَائِلِ الصَّحَابَةِ مَنَاقِبُ أَبِي بَكْرٍ رَضِي عَنْهُ بَابُ قَوْلِهِ تَعَالَى: ﴿إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ ا...