فَصْلٌ فِي
الْأَوْقَاتِ
ÌPÍN TÍ Ó Ń SÀLÀYÉ ÀWỌN
ÀKÓKÒ ÌRUN
اَلْوَقْتُ
الْمُخْتَارُ لِلظُّهْرِ مِنْ زَوَالِ الشَّمْسِ إِلَى آخَرَ الْقَامَةِ.
وَالْمُخْتَارُ لِلْعَصْرِ مِنْ الْقَامَةِ إِلَى الِاصْفِرَارِ وَضَرُورِيُّهُمَا
إِلَى الْغُرُوبِ. وَالْمُخْتَارُ لِلْمَغْرِبِ: قَدْرُ مَا تُصَلَّى فِيهِ بَعْدَ
شُرُوطِهَا. وَالْمُخْتَارُ لِلْعَشَاءِ مِنْ مَغِيبِ الشَّفَقِ إِلَى ثُلُثِ
اللَّيْلِ الْأَوَّلِ. وَضَرُورِيُّهُمَا إِلَى طُلُوعِ اَلْفَجْرِ.
وَالْمُخْتَارُ لِلصُّبْحِ مِنَ الْفَجْرِ إِلَى الْإِسْفَارِ الْأَعْلَى
وَضَرُورِيُّهُ إِلَى طُلُوعِ الشَّمْسِ، وَالْقَضَاءُ فِي الْجَمِيعِ مَا وَرَاءَ
ذَلِكَ.
Ojúlówó àkókò tí wọ́n sà ní ẹ̀sà fún
ìrun Àílà (Zuhr) ní ìgbà tí òòrùn bá yẹ àtààrí parí sí ìgbà tí ìnàró gbogbo
ǹkan yóò fi se déédé ara wọn. Àkókò ẹ̀sà fún ìrun Àláásàrì (Asr), àti àsìkò
làlúrí fún ìrun àílà (Dhuhr) ni ìgbà tí ìnàró gbogbo ǹkan bá se déédé ara wọn
títí ojú ọjọ́ yóò fi di òfééfèé (Yẹ́lò). Nígbà tí àsìkò làlúrí fún ìrun Àílà
(Dhuhr) àti àsìkò ẹ̀sà fún àláásàrì (Asr) bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ojú ọjọ́ bá ti di
òfééfèé (Yẹ́lò) títí òòrùn yóò fi wọ̀. Àkókò ẹ̀sà fún ìrun Mọ́gáríbì (Magrib)
ni òdiwọ̀n ìgbà tí ìrun náà yóò fi jẹ́ kíkí lẹ́yìn tí gbogbo májẹ̀mu ti ó gbe
dúró ti pé lẹ́yìn tí òòrùn ti wọ̀. Àkókò ẹ̀sà fún ìrun Ìsháì (Ishai) ni ìgbà tí
awòǹpàpà (Tanmọóko) yóò fi wọlé títí di ídá mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú òru. Àsìkò
làlúrí fún ìrun Ìsháì sì wà títí di àsìkò
lílà àlùfájàrí. Àsìkò ẹ̀sà fún ìrun Àsùnbáà (Subhi) ni ìgbà tí àlùfájàrí bá ti
là títí di ìgbà tí òye yóó fi mọ́lẹ̀ kedere. Àsìkò làlúrí rẹ̀ sì lọ títí di
ìgbà tí òòrùn yóò fi yọ. Ìrun tí ó bá sì ti bọ́ sí ẹ̀yìn àwọn àsìkò làlúrí ti bọ́
sí ipò gbèsè sísan.
وَمَنْ
أَخَّرَ الصَّلَاةَ حَتَّى خَرَجَ وَقْتُهَا فَعَلَيْهِ ذَنْبٌ عَظِيمٌ إِلَّا أَنْ
يَكُونَ نَاسِيًا أَوْ نَائِمًا. وَلَا تُصَلَّى نَافِلَةٌ بَعْدَ صَلَاةِ
الصُّبْحِ إِلَى ارْتِفَاعِ الشَّمْسِ، وَبَعْدَ صَلَاةِ الْعَصْرِ إِلَى صَلَاةِ
الْمَغْرِبِ، وَبَعْدَ طُلُوعِ الْفَجْرِ إِلَّا الْوِرْدَ لِنَائِمٍ عَنْهُ
وَعِنْدَ جُلُوسِ إِمَامِ الْجُمُعَةِ عَلَى الْمِنْبَرِ، وَبَعْدَ الْجُمْعَةِ
حَتَّى يَخْرُجَ مِنَ الْمَسْجِدِ.
Ẹni tí ó bá lọ́ ìrun lára tí àsìkò rẹ̀ fi kọjá, ẹrù ẹ̀sẹ̀ ńlá ń
bẹ lórí rẹ̀, àyàfi tí ó bá gbàgbé tàbí ó sùn lọ. Kò sì sí ìgbàláyè fún àkígbọrẹ
(Nafila) lẹ́yìn ìrun Àsùnbáà (Subhi) títí tí òòrùn yóò fi kan àtààrí. Bẹ́ẹ̀ni
kó sí fún un lẹ́yìn ìrun Àláásàrì (Asr) títí di àsìkò Mọ́gáríbì (Magrib). Kò sì
sí fún un lẹ́yìn tí Àlùfájàrí (Fajr) bá ti là, àyàfi Nafila tí ó sùn gbàgbé
láti se. Kò tún sí fún un lẹ́yìn tí ìmámù bá ti gun pẹpẹ (Minbari) ní ọjọ́ Jímọ̀,
àti lẹ́yìn ìrun Jímọ̀ títí tí yóò fi jáde ní Mọ́sálásí.
فَصْلٌ فِي
شُرُوطِ الصَّلَاةِ
ÌPÍN TÍ Ó Ń SÀLÀYÉ ÀWỌN
MÁJẸ̀MÚ ÌRUN
وَشُرُوطُ
الصَّلَاةِ طَهَارَةُ الْحَدَثِ وَطَهَارَةُ الْخَبَثِ مِنَ الْبَدَنِ وَالثَّوْبِ
وَالْمَكَانِ وَسَتْرُ الْعَوْرَةِ وَاسْتِقْبَالُ الْقِبْلَةِ، وَتَرْكُ
الْكَلَامِ وَتَرْكُ الْأَفْعَالِ الْكَثِيرَةِ. وَعَوْرَةُ الرَّجُلِ مَا بَيْنَ
السُّرَّةِ وَالرُّكْبَةِ، وَالْمَرْأَةُ كُلُّهَا عَوْرَةٌ مَا عَدَا الْوَجْهَ
وَالْكَفَّيْنِ. وَتُكْرَهُ الصَّلَاةُ فِي السَّرَاوِيلِ، إِلَّا إِذَا كَانَ
فَوْقَهَا شَيْءٌ. وَمَنْ تَنَجَّسِ ثَوْبُهُ وَلَمْ يَجِدْ ثَوْبًا غَيْرَهُ
وَلَمْ يَجِدْ مَاءً يَغْسِلُهُ بِهِ أَوْ لَمْ يَكُنْ عِنْدَهُ مَا يَلْبَسُ
حَتَّى يَغْسِلَهُ وَخَافَ خُرُوجَ الْوَقْتِ صَلَّى بِنَجَاسَتِهِ. وَلَا يَحِلُّ
تَأْخِيرُ الصَّلَاةِ لِعَدَمِ اَلطَّهَارَةِ، وَمَنْ فَعَلَ ذَلِكَ فَقَدْ عَصَى
رَبَّهُ. وَمَنْ لَمْ يَجِدْ مَا يَسْتُرُ بِهِ عَوْرَتَهُ صَلَّى عُرْيَانًا.
وَمَنْ أَخْطَأَ الْقِبْلَةَ أَعَادَ فِي الْوَقْتِ، وَكُلُّ إِعَادَةٍ فِي
الْوَقْتِ فَهِيَ فَضِيلَةٌ. وَكُلُّ مَا تُعَادُ مِنْهُ الصَّلَاةُ فِي الْوَقْتِ
فَلَا تُعَادُ مِنْهُ الْفَائِتَةُ وَالنَّافِلَةُ.
Àwọn májẹ̀mú ni: (1) Ìmọra níbi ẹ̀gbin. (2) Ìmú ẹ̀gbin kúrò ní
ara, asọ, àti ààyè ìkírun. (3) Bíbo ìhòòhò. (4) Dídojúkọ kàábà. (5) Gbígbé ọ̀rọ̀
sísọ (Tí ó bá yàtọ̀ sí oun tí a fí ń se ìjọsìn ìrun) jù sílẹ̀. (6)
Gbígbé isẹ́ ọlọ́pọ̀lọpọ̀ (Tí ó bá yàtọ̀ sí àwọn tí a fí ń se ìjọsìn ìrun)
jù sílẹ̀. Ìhòòhò ọkùnrin lórí ìrun
ni àlàfo ìdajì ara (Ìdodo) títí dé orúnkún rẹ̀. Ìhòòhò obìnrin sì ni gbogbo ara
rẹ̀ pátá tí a bá yọwọ́ ojú àti àtẹlẹwọ́
rẹ̀ méjéèjì. Wọ́n sì kọ kíkí ìrun pẹ̀lu sòkòtò lásán láì kò wọ ǹkan sí òkè rẹ̀. Ẹni tí ẹ̀gbin bá wà ní ara asọ rẹ̀, tí ó
sàfẹ́kù asọ míràn, tí kò sì rí omi tí ó lè fi mọ́ ọn, tàbí kò ní asọ òmíràn tí
ó le fi sọ́rùn láti fi se ìmọ́tótó èyí tí ẹ̀gbin ńbẹ lára rẹ̀, tí ó sì ń bẹ̀rù
kí àsìkò ìrun má jáde mọ́ ọn lọ́wọ́, Ó lè kírun pẹ̀lú ẹ̀gbin tí ó wà lára asọ rẹ̀. Lílọ́ ìrun lára kò tọ́ ní
tìtorí àìmọ́ra, ẹni tí ó bá fi ìrun lọ́ra nítorí ìdí yí ti dá ẹ̀sẹ̀ sí Ọlọ́hun ọba
rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì se àfẹ́kù
oun tí ó lè fi bo ìhòòhò rẹ̀, yóò kí ìrun rẹ̀ ní ìhòòhò náà ni. Ẹni tí ó bá sì
se àsìyàn ibùdojúkọ kírun (Kibla) yóò tun kí lópin ìgbà tí àsìkò ìrun náà kò bá
tíì jáde. Gbogbo ààyè tí wọ́n bá ti fẹ́ sísan ìrun padà lópin ìgbà tí àsìkò
ìrun kò bá tíì jáde ń dá lórí wípé “Ọlá ńbẹ níbi síse é”, “Bí ènìyàn kò bá sì
sé, kò buru”. Gbogbo ìse tí ó bá sì bèèrè fún sísan ìrun padà lópin ìgbà tí
àsìkò rẹ̀ kò bá tíì jáde, èyí tí ó bá ti jáde àti àkígbọrẹ (Naafila) kò níí jẹ́
sísan padà nítorí wọn.
فَصْلٌ:
فَرَائِضُ الصَّلَاةِ: نِيَّةُ الصَّلَاةِ الْمُعَيَّنَةِ، وَتَكْبِيرَةُ
الْإِحْرَامِ وَالْقِيَامُ لَهَا، وَالْفَاتِحَةُ وَالْقِيَامُ لَهَا،
وَالرُّكُوعُ وَالرَّفْعُ مِنْهُ، وَالسُّجُودُ عَلَى الْجَبْهَةِ وَالرَّفْعُ
مِنْهُ، وَالِاعْتِدَالُ، وَالطُّمَانِينَةُ، وَالتَّرْتِيبُ بَيْنَ فَرَائِضِهَا،
وَالسَّلَامُ وَجُلُوسُهُ الَّذِي يُقَارِنُهُ.
Ẹ̀kọ́ Míràn- Àwọn Ọ̀ranyàn Ìrun ni: (1) Mímú àníyàn
irú ìrun tí a fẹ́ẹ́ kí gan gan wá. (2) Gbígbé kábárá (Allahu Akbar tí a fí
ń sọ gbogbo ìse àti ọ̀rọ̀ míràn tí ó yàtọ̀ sí èyí tí a fi ń se ìjọsìn ìrun di
èèwọ̀). (3) Dìdúró gbé kábárá. (4) Kíka ọgbà ọ̀rọ̀ ìsí Alukuraani (Suratul
Faatiha). (5) Dìdúró ka ọgbà ọ̀rọ̀ ìsí Alukuraani (Suratul Faatiha). (6) Títẹríba
(Rukuu). (7) Sísí orí kúrò ní ítẹríba (Rukuu). (8) Fífi iwájú orí kanlẹ̀
(Sujuudu). (9) Gbígbé orí nílẹ̀. (10) Dídúró
dáradára lẹ́yìn ísí orí kúrò ní ítẹríba (Rukuu), àti ìjókó dáradára lẹ́yìn gbígbé orí nílẹ̀. (11) Fífara
balẹ̀ níbi ìdúró àti ìjòkó. (12) Tító àwọn ọ̀ranyàn ìrun yí tẹ̀lé ara wọn. (13)
Píparí ìrun pẹ̀lú sálámọ̀. (14) Jíjòkó sálámọ̀.
(وَشَرْطُ)
النِّيَّةِ مُقَارَنَتُهَا لِتَكْبِيرَةِ الْإِحْرَامِ.
Májẹ̀mu àníyàn ni síse é mọ́ kábárá (Allahu Akbar tí a fí ń sọ
gbogbo ìse àti ọ̀rọ̀ míràn tí ó yàtọ̀ sí èyí tí a fi ń se ìjọsìn ìrun di èèwọ̀).
(وَسُنَّتُهَا):
الْإِقَامَةُ، وَالسُّورَةُ الَّتِي بَعْدَ الْفَاتِحَةِ، وَالْقِيَامُ لَهَا،
وَالسِّرُّ فِيمَا يُسَرُّ فِيهِ، وَالْجَهْرُ فِيمَا يُجْهَرُ فِيهِ، وَسَمِعَ
اللَّهُ لِمَنْ حَمِدَهُ. وَكُلُّ تَكْبِيرَةٍ سُنَّةٌ إِلَّا الْأُولَى
وَالتَّشَهُّدَانِ وَالْجُلُوسُ لَهُمَا، وَتَقْدِيمُ الْفَاتِحَةِ عَلَى
السُّورَةِ وَالْتَّسْلِيمِةُ الثَّانِيَةُ وَالثَّالِثَةُ لِلْمَأْمُومِ،
وَالْجَهْرُ بَالتَّسْلِيمِةِ الْوَاجِبَةِ، وَالصَّلَاةُ عَلَى رَسُولِ اللَّهِ
صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، وَالسُّجُودُ عَلَى الْأَنْفِ وَالْكَفَّيْنِ
وَالرُّكْبَتَيْنِ وَأَطْرَافِ الْقَدَمَيْنِ وَالسُّتْرَةُ لِغَيْرِ الْمَأْمُومِ
وَأَقَلُّهَا غِلَظُ رُمْحٍ وَطُولُ ذِرَاعٍ طَاهِرٍ ثَابِتٍ غَيْرِ مُشَوَّشٍ.
Ìlànà Ànábì Lórí Ìrun Kíkí ni: (1) Gbígbé
ìrun dúró (Ìkáámà). (2) Kíka ọgbà ọ̀rọ̀ (Suura) míràn lẹ́yín ọgbà ọ̀rọ̀ ìsí
Alukuraani (Suratul Faatiha). (3) Dídúró ka ọgbà ọ̀rọ̀ (Suura) míràn. (4) Kíka
kéwú jẹ́ẹ́jẹ́ láàyè rẹ̀. (5) Kíka kéwú sókè láàyè rẹ̀. (6) Wíwí gbólóhùn “Semial
lahu liman hamdau” níbi sísí orí kúrò ní ítẹríba (Rukuu). (7) Gbogbo kábárà
tí ó bá ti yàtọ̀ sí kábárà ìbẹ̀rẹ̀ ìrun. (8) Síse àtááyá méjéèjì. (9) Jíjòkó se
àtááyá méjéèjì. (10) Kíka ọgbà ọ̀rọ̀ ìsí Alukuraani (Suratul Faatiha) síwájú ọgbà
ọ̀rọ̀ (Suura) míràn. (11) Síse sálámọ̀ kejì àti ìkẹta fún olùtẹ̀lé ìmáámù ní
ìparí ìrun. (12) Gbígbé òhùn sókè se sálámọ̀ àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ọ̀ranyàn. (13)
Síse ìtọrọ ìkẹ́ àti ìgẹ̀ fún Ànábì (Àsàláátù) níbi àtááyá ìkángun ìrun. (14)
Fífi imú, àtẹlẹwọ́ méjéèjì, orúnkún méjéèjì, àwọn ọmọníka ẹsẹ̀ méjéèjì lẹ́lẹ̀
níbi ìforí kanlẹ̀. (15) Lílo agàgá fún ìmáámù. Agàgá yí kéré jù aò rí irú rẹ̀
rí ni kí ó nípọn bí ọ̀kọ̀, kí ó sì gùn ní òdiwọ̀n
ìgbùnwọ́ kan tí ó mọ́, tí ó le dúró sinsin, tí kò sì níí jẹ́ oun ìdíwọ́ fún
olùkírun.



