Wednesday, 30 August 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹrin)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
الثَّانِيَةُ: أَنَّ الله لا يَرْضَى أَنْ يُشْرَكَ معه أحدً في عبادته، لا مَلَكٌ مُقَرَّبٌ، وَلا نَبِيٌّ مُرْسَلٌ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿وَأَنَّ الْمَسَاجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدْعُوا مَعَ اللَّهِ أَحَدًا [الجن: 18].

ÌTUMỌ̀
Ẹ̀kejì: òun ni wípé dájúdájú Ọlọ́hun (Allahu) kò níí yọ́nú sí ìmú ẹnikẹ́ni ní orogún pẹ̀lú rẹ̀ níbi isẹ́ ìjọsìn Fún un, kì bá ǹ jẹ́ màláíká tó sùnmọ́ Ọn, tàbí ọ̀kan nínú àwọn ànábì tó fi isẹ́ rán. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Dájúdájú, ti Ọlọ́hun nìkan soso ni gbogbo ààyè ìsìn àti ibù fisìn, nítorí náà, ẹ má se tún máa sin ẹnìkẹni míràn ní àwọn ààyè náà tàbí fi àwọn ibùsìn náà sin ẹlòmíràn lẹ́yìn Ọlọ́hun) (Ọgbà ọ̀rọ̀ àlùjànnú [Suratul Jinni], Ẹsẹ 18).


الثَّالِثَةُ: أَنَّ مَنْ أَطَاعَ الرَّسُولَ وَوَحَّدَ اللهَ، لا يجوز له موالاة من حادَّ الله وَرَسُولَهُ، وَلَوْ كَانَ أَقْرَبَ قَرِيبٍ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تعالى: ﴿لَا تَجِدُ قَوْمًا يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ يُوَادُّونَ مَنْ حَادَّ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَوْ كَانُوا آبَاءَهُمْ أَوْ أَبْنَاءَهُمْ أَوْ إِخْوَانَهُمْ أَوْ عَشِيرَتَهُمْ أُولَئِكَ كَتَبَ فِي قُلُوبِهِمُ الْإِيمَانَ وَأَيَّدَهُمْ بِرُوحٍ مِنْهُ وَيُدْخِلُهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ أُولَئِكَ حِزْبُ اللَّهِ أَلَا إِنَّ حِزْبَ اللَّهِ هُمُ الْمُفْلِحُونَ [المجادلة: 22].

ÌTUMỌ̀
Ẹ̀kẹta: nipé ẹni tó bá ń tẹ̀le òjísẹ́ Ọlọ́hun (Allahu) lódodo, tó sì gbà Ọlọ́hun lọ́kan soso, kò tọ́ fún un láti mú olùkọ tọlọ́hun àti òjísẹ́ rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ ààyò. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Oò le rí ọ̀kankan nínú àwọn èèyàn tó ní ígbàgbọ́ òdodo sí Ọlọ́hun àti ọjọ́ ìkẹhìn tí yóò maa sọ̀rẹ́ ààyò pẹ̀lú àwọn ọ̀tá Ọlọ́hun àti òjísẹ rẹ̀, kódà kí wọ́n jẹ́ bàbá, tàbí ọmọ, tábí ọmọ ìyá, tàbí mọ̀lẹ́bí fún wọn. Irú àwọn wọ̀nnì ni Ọlọ́hun se àfirinlẹ̀ ìgbàgbọ̀ sínú ọkàn wọn tí Ó tún se ìkúnwọ fún wọn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí yóò sì tún fiwọ́n wọ ọgbà ìdẹ̀ra (Àlùjánnà) tí àwọn akérémọdò ń sàn lábẹ́ rẹ́ lẹ́ni tí yóò se gbére nínú rẹ́, látààrí pé Ọlọ́hun (Allahu) yọ́nú síwọn, àwọn náà sì yọ́nú sí I (Allahu). Àwọn wọ̀nnì ni a le pè ní ọmọ ogun Ọlọ́hun (Allahu), Ẹ tẹ́tí gbọ́, àwọn ọmọ ogun Ọlọ́hun (Allahu) ni ẹni ọlà) (Ọgbá ọ̀rọ̀ irin [Suratul Hadiid], Ẹsẹ 22).

Monday, 28 August 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹta)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá

اعْلَمْ -رَحِمَكَ اللهُ- أَنَّه يَجِبُ عَلَى كُلِّ مُسْلِمٍ وَمُسْلِمَةٍ تَعَلُّمُ هَذِهِ الثَّلاثِ مَسَائِل والْعَمَلُ بِهِنَّ:
الأُولَى: أَنَّ اللهَ خَلَقَنَا وَرَزَقَنَا وَلَمْ يَتْرُكْنَا هَمَلا، بَلْ أَرْسَلَ إِلَيْنَا رَسُولاً، فَمَنْ أَطَاعَهُ دَخَلَ الجَنَّةَ، وَمَنْ عَصَاهُ دَخَلَ النَّارَ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿إِنَّا أَرْسَلْنَا إِلَيْكُمْ رَسُولًا شَاهِدًا عَلَيْكُمْ كَمَا أَرْسَلْنَا إِلَى فِرْعَوْنَ رَسُولًا فَعَصَى فِرْعَوْنُ الرَّسُولَ فَأَخَذْنَاهُ أَخْذًا وَبِيلًا [المزمل: 15 - 16].


ÌTUMỌ̀
Lọrèémọ̀ -Ọlọ́hun (Allahu) yóò kẹ́ ọ- wípé ó tún di ọ̀ranyàn lé gbogbo mùsùlùmí lọ́kùnrin lóbìnrin lórí ì mọ̀ nípa àwọn àláámọ̀rí mẹ́ta tó ń bọ̀yí pẹ̀lú sí sisẹ́ tọ̀wọ́n:

Ákọ́kọ́: ni wípé Ọlọ́hun (Allahu) ni ó sẹ̀dá wa, òun náà sì ni ó ń se íjẹ ìmu (Arísìkí) fún wa, kò tún wáá fiwá kalẹ̀ lásán, ó tún rán òjísẹ́ kan síwa, ẹnikéni tó bá tẹ̀le ìlànà rẹ̀ ti fi ọgbà ìdẹ̀ra (Àlùjánnà) se ìfà jẹ, ẹnikéni tó bá sì yapa ilànà rẹ̀ ti lùgbàdì iná. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Pàá a ti rán an sí yín òjísẹ́ kan tí yóò máa jẹ́ ẹlẹ́rì leyín lórí gẹ́gẹ́ bí a ti se rán òjísẹ́ sí Fíríáónà sùgbọ́n tí ó kọ etí ikún sí òjísẹ́ wa, a wáá torí rẹ̀ fi ọwọ́ agbára apanirun múu). (Suratu Musamilu, 15-16).

Tuesday, 22 August 2017

Ìtumọ̀ Tírà Usulu Salasa (Ìpìlẹ̀ Èsìn Mẹ́ta tò se pàtàkì) (Ẹ̀kọ́ Kejì)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
قَالَ الشَّافِعِيُّ -رَحِمَهُ اللهُ تَعَالَى-: "لَوْ مَا أَنْزَلَ اللهُ حُجَّةً عَلَى خَلْقِهِ إِلَّا َهذِهِ السُّورَةَ لَكَفَتْهُم.
وَقَالَ البُخَارِيُّ -رَحِمَهُ اللهُ-: بَابٌ: الْعِلْمُ قَبْلَ القَوْلِ وَالْعَمَلِ.
وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿فَاعْلَمْ أَنَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ وَاسْتَغْفِرْ لِذَنْبِكَ وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَات وَاللَّهُ يَعْلَمُ مُتَقَلَّبَكُمْ وَمَثْوَاكُمْ﴾ [محمد: 19]. فَبَدَأَ بِالْعِلَمِ قَبْلَ الْقَوْلِ وَالْعَمَلِ.
ÌTUMỌ̀
Olùmọ̀ Àgbà, Asíwájú Ṣafiiyu –kí Ọlọ́hun lékún ìkẹ́ wọn- sọpé: “tí Ọlọ́hun Ọba (Allahu) kò bá sọ ọgbà ọ̀rọ̀ (Suuratu) míràn kalẹ̀ fún àwọn ẹ́dá rẹ̀ lòrí àwọn ìpìlẹ̀ mẹ́ẹ́rẹ̀rin yìí tó kọjá eléyìí, ó ti tó fún wọn”.


Olùmọ̀ Àgbà, Asíwájú Buhariyyu - kí Ọlọ́hun lékún ìkẹ́ wọn- náà tún fi se àkọlé ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Aayatu) tó ń bọ̀ yìí, ọ́rọ̀ rẹ̀ tó sọ pé: “ákórí ẹsẹ ọ̀rọ̀ (Aayatu) tó ń bọ̀ yí ni wípé: ìmọ̀ gbudọ̀ síwájú èyíkéyí ọ̀rọ̀ àti ìse”. Ẹ̀rí eléyí sì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Kọ́kọ́ lọrèémọ̀ wípé kò sí ẹnikẹ́ni tó lẹ́tọ́ sí ìjọsìn òdodo yàtọ̀ sí Ọlọ́hun (Allahu), lẹ́yìn náà kí o máa wá àforíjìn ẹ̀sẹ̀ fún ara rẹ àti fún gbogbo ódodo lọ́kùnrin àti lóbìnrin). Èyí nipé, Ọlọ́hun (Allahu) fi ìmọ̀ siwájú ọ̀rọ̀ àti íse.

Friday, 18 August 2017

Ìtumọ̀ Tírà Usulu Salasa (Ìpìlẹ̀ Èsìn Mẹ́ta tò se pàtàkì) (Ẹ̀kọ́ Kínní)


Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
اعْلَمْ -رَحِمَكَ اللهُ- أَنَّهُ يَجِبُ عَلَيْنَا تَعَلُّمُ أَرْبَعِ مَسَائِلَ:
الأُولى: العِلْمُ- وَهُوَ مَعْرِفَةُ اللهِ، وَمَعْرِفَةُ نَبِيِّهِ، وَمَعْرِفَةُ دِينِ الإِسْلَامِ بِالأَدِلَّةِ.
الثانية: العَمَلُ بِهِ.
الثالثة: الدَّعْوَةُ إِلَيْهِ.
الرابعة: الصَّبْرُ عَلَى الأَذَى فِيهِ.
وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَالْعَصْرِ ۞ إِنَّ الْإِنْسَانَ لَفِي خُسْرٍ ۞ إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَتَوَاصَوْا بِالْحَقِّ وَتَوَاصَوْا بِالصَّبْرِ(

ÌTUMỌ̀
Lọrèémọ̀ -Ọlọ́hun (Allahu) yóò kẹ́ ọ- wípé ó di ọ̀ranyàn lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lórí ì wámọ̀ nìpa àwọn àláámọ̀rí mẹ́ẹ́rin kan:
Alákọ̀kọ́: Ìmọ̀ – òun náà ni níní ìmọ̀ tó jindò nípa Ọlọ́hun (Allahu), òjísẹ́ rẹ̀, àti ẹ̀sìn Isilaamu pẹ̀lú ìtọ́ka.
Ẹlẹ́ẹ̀kejì: ì fi sisẹ́ se.
Ẹlẹ́ẹ̀kẹta: ì pèpè lọ síbẹ̀.
Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin: àmúmọ́ra lóri gbogbo ẹ̀gin tó lè jẹyọ lórí ípèpè síbẹ̀.

Ẹ̀rí mọ́ọ jẹ́mi ǹsó lórí àwọn nkan wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ̀hun (Allahu) tí ìtumọ́ rẹ̀ lọ báyí wípé:
(Mo fi ìgbà ìrọ̀lẹ́ ayé búra ^ dájúdájú ìran ọmọnìyàn yóò máa yí nínú òfò ní àsìkò náà ^ àyàfi àwọn tó bání ìgbàgbọ́ àní dọ́kàn tí wọ́n sì se àwọn isẹ́ rere tí wọ́n tún wá ń pèpè lọ síbi òdodo àti àtẹ̀mọra)  




Wednesday, 16 August 2017




ÌTUMỌ̀ TÍRÀ
ÀWỌN ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀SÌN MẸ́TA

TÍ MÍMỌ̀ NÍPA WỌN ÀTI ÌSISẸ́ TỌ̀ WỌ̀N DI Ọ̀RANYÀN FÚN GBOGBO ỌMỌNÌYÀN

TI
ÀGBÀ ÒǸKỌ̀WÉ, ONÍMÍMỌ̀ MUHAMMADU ỌMỌ ABDUL WAHABI


SÍ ÈDÈ YORÙBÁ
LÁTI ỌWỌ́ AKẸ́KỌ́ Ẹ̀SÌN KAN

 

Monday, 14 August 2017

Islamic Learning Centre in Yoruba language




ÌKÍNI KÚ ÀBỌ̀


ẸKÚ ÀBỌ̀ SÌ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÈSÌN NÍ ÈDÈ YORÙBÁ TI ORÍLẸ̀ ÈDÈ NIGERIA

The timeless lessons from Abū Bakr’s companionship with the Prophet ﷺ during the migration to Madinah

  كِتَابُ فَضَائِلِ الصَّحَابَةِ مَنَاقِبُ أَبِي بَكْرٍ رَضِي عَنْهُ بَابُ قَوْلِهِ تَعَالَى: ﴿إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ ا...