فَالْجَنَابَةُ
قِسْمَانِ: أَحَدُهُمَا خُرُوجُ الْمَنِيِّ بِلَذَّةٍ مُعْتَادَةٍ فِي نَوْمٍ أَوْ
يَقَظَةٍ بِجِمَاعٍ أَوْ غَيْرِهِ. وَالثَّانِي: مَغِيبُ الْحَشَفَةِ فِي
الْفَرْجِ. وَمَنْ رَأَى فِي مَنَامِهِ كَأَنَّهُ يُجَامِعُ وَلَمْ يَخْرُجْ
مِنْهُ مَنِيٌّ فَلَا شَيْءَ عَلَيْهِ، وَمَنْ وَجَدَ فِي ثَوْبِهِ مَنِيًّا
يَابِسًا لَا يَدْرِي مَتَى أَصَابَهُ اغْتَسَلَ وَأَعَادَ مَا صَلَّى مِنْ آخِرِ
نَوْمِةٍ نَامَهَا فِيهِ.
Ẹ̀kọ́ míràn: Ìwẹ̀ òfin di ọ̀ranyàn níbi ǹkan mẹ́ta; lílu jánábà, ẹ̀jẹ̀
ǹkan osù obìnrin (Éélà), ẹ̀jẹ̀ ìbimọ (Nìfáásì). Jánábà ní ìpín méjì:
Àkọ́kọ́: jíjáde àtọ̀ (látààrí ìgbadùn tí a ti mọ̀) ní ojú oorun
tàbí lójú ayé, kò bá ǹ jẹ́ pẹ̀lú níní àsepọ̀ pẹ̀lú obìnrin tàbí pẹ̀lú ǹkan
míràn.
Ìkejì: kí òdiwọ̀n adéńdérí abẹ́ ọkùnrin wọ abẹ́ obìnrin. Ẹni tí ó
bá lá àlá tí ó rí ní ojúran wípe òun ń ní àsepọ̀ pẹ̀lú obìnrin tí kò sì rí
orípa àtọ̀ nígbà tí ó lajú, kò bùkáátà kí ó wẹ̀ ìwẹ̀ òfin. Ẹni tí ó bá orípa àtọ̀
tí ó ti gbẹ, tí kò mọ ìgbà tí ó jáde lára rẹ̀, ẹni náà yóó wẹ̀, yóò sì dá àwọn
ìrun tí ó ti kí láti ẹ̀yìn oorun tí ó sùn gbẹ̀yìn di àkókò tí ó rántí padà.
فَصْلٌ:
فَرَائِضُ الْغُسْلِ: النِّيَّةُ عِنْدَ الشُّرُوعِ وَالْفَوْرُ وَالدَّلْكُ
وَالْعُمُومُ.
Ẹ̀kọ́ míràn: àwọn ọ̀ranyàn ìwẹ̀ òfin ni; (1) dída àníyàn ní ìbẹ̀rẹ̀
ìwẹ̀, (2) yíyára wẹ̀ ìwẹ̀ òfin, (3) fífi ọwọ́ gbo ara ní àsìkò ìwẹ̀, (4) fífi
omi kárí ara.
(وَسُنَنُهُ):
غَسْلُ الْيَدَيْنِ إِلَى الْكُوعَيْنِ كَالْوُضُوءِ، وَالْمَضْمَضَةُ
وَالِاسْتِنْشَاقُ وَالِاسْتِنْثَارُ، وَغَسْلُ صِمَاخِ الْأُذُنِ وَهِيَ
الثُقْبَةُ الدَّاخِلَةُ فِي الرَّأْسِ. وَأَمَّا صَحْفَةُ الْأُذُنِ فَيَجِبُ
غَسْلُ ظَاهِرِهَا وَبَاطِنِهَا.
Àwọn ìlànà ànábì lórí ìwẹ̀ òfin ni: (1) wíwẹ ọwọ̀ mèjèèjì títí dé ọrùn
ọwọ́ bíi ti àlùwàlá, (2) yíyọ ẹnu, (3) fífín imú, (4) fífọn omi tí a fín sinu ihò imú sí ìta padà, (5) fífọ inú
ihò etí. Òun ni ihò tí ó lu já inú agbárí. Ọ̀ranyàn sì ni fífọ inú àti òde ẹ̀rọ
etí.
(وَفَضَائِلُهُ):
الْبِدَايَةُ بِغَسْلِ النَّجَاسَةِ ثُمَّ الذَّكَرِ فَيَنْوِي عِنْدَهُ، ثُمَّ
أَعْضَاءِ الْوُضُوءِ مَرَّةً مَرَّةً، ثُمَّ أَعْلَى جَسَدِهِ، وَتَثْلِيثُ
غُسْلِ الرَّأْسِ، وَتَقْدِيمُ شِقِّ جَسَدِهِ الْأَيْمَنِ، وَتَقْلِيلُ الْمَاءِ
عَلَى الْأَعْضَاءِ. وَمَنْ نَسِيَ لُمْعَةً أَوْ عُضْوًا مِنْ غُسْلِهِ بَادَرَ
إِلَى غَسْلِهِ حِينَ تَذَكُّرِهِ، وَلَوْ بَعْدَ شَهْرٍ، وَأَعَادَ مَا صَلَّى
قَبْلَهُ. وَإِنْ أَخَّرَهُ بَعْدَ ذِكْرِهِ بَطَلَ غَسْلُهُ. فَإِنْ كَانَ فِي
أَعْضَاءِ الْوُضُوءِ وَصَادَفَهُ غَسْلُ الْوُضُوءِ أَجْزَأَهُ.
Àwọn oun tí wọ́n fẹ́ síse wọn níbi ìwẹ̀ òfin ni: (1) bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú
mímú ẹ̀gbin kúrò ní ara, (2) lẹ́yìn náà ni fífọ abẹ́ rẹ̀ (Àsákàrí), níbi fífọ
abẹ́ rẹ̀ ni yóò sì ti da àníyàn, (3) lẹ́yìn náà ni síse àwọn iburè àlùwàlá ní
ìgbà kọ̀ọ̀kan, (4) lẹ́yìn náà ni wíwẹ òkè ara rẹ̀, (5) fífọ orí ní ìgbà mẹ́ta,
(6) wíwẹ abala ọ̀tún ara síwájú abala òsì, (7) lílo omi níwọ̀n níbi wíwẹ̀ àwọn
iburè náà. Ẹni tí ó bá gbàgbé wíwẹ̀ ààyè tàbí iburè kan, kí ó yára tete wẹ̀ ẹ́
ní ìgbàkígbà tí ó bá ti rántí, kò bá ǹjẹ́ lẹ́yìn osù kan, kí ó sì san àwọn
ìrun tí ó ti kí síwájú rẹ̀. Tí ó bá wáá
fi wíwẹ̀ rẹ̀ falẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti rántí, ìwẹ̀ òfin tí ó wẹ̀ ti bàjẹ́. Tí ó bá wáá
jẹ́ wípé ààyè àlùwàlá ni ó gbàgbé, sùgbọ́n tí omi ìwẹ̀ ti ré kọjá lórí ààyè náà,
ìwẹ̀ òfin rẹ̀ kò bàjẹ́.
فَصْلٌ:
لَا يَحِلُّ لِلْجُنُبِ دُخُولُ الْمَسْجِدِ، وَلَا قِرَاءَةُ الْقُرْآنِ إِلَّا
الْآيَةَ وَنَحْوَهَا لِلتَّعَوُّذِ وَنَحْوِهِ. وَلَا يَجُوزُ لِمَنْ لَا
يَقْدِرُ عَلَى الْمَاءِ الْبَارِدِ أَنْ يَأْتِيَ زَوْجَتَهُ حَتَّى يُعِدَّ
الْآلَةَ إِلَّا أَنْ يَحْتَلِمَ، فَلَا شَيْءَ عَلَيْهِ.
Ẹ̀kọ́
míràn: kò lẹ́tọ́ fún ẹni tí ó bá ní jánábà lára kí ó wọ ilé ìjọsìn (Masálásí),
kò sì lẹ́tọ́ fún un láti ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Àlùkùráánì) àyàfi bíi ẹsẹ kan
(aayah) àti oun tí ó bá súnmọ́ ọn tí ó yọ kà láti fi wá ìsọ́ Ọlọ́hun. Kò sì lẹ̀tọ́
fún ẹni tí kò lágbára láti fi omi tutu wẹ̀ kí ó súnmọ́ ìyàwó rẹ̀ titi yóó fi pèsè
irin isẹ́ amú omi lọ́ wọ́ọ́rọ́. Àyàfi tí ó bá jẹ́ wípé ó tí lá àlá da ǹkan sí
ara tẹ́lẹ̀, kòburú kí ó súnmọ́ ìyàwó rẹ̀.

No comments:
Post a Comment