Saturday, 30 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Ìgbẹ̀yìn)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
فَلَمَّا اسْتَقَرَّ فِي الْمَدِينَةِ أُمِرَ بِبَقِيَّةِ شَرَائِعِ الإِسْلامِ مِثلِ الزَّكَاةِ، وَالصَّوْمِ، وَالْحَجِّ، وَالأَذَانِ، وَالْجِهَادِ، وَالأَمْرِ بِالْمَعْرُوفِ، وَالنَّهْيِ عَنِ الْمُنْكَرِ، وَغَيْرِ ذَلِكَ مِنْ شَرَائِعِ الإِسْلامِ. أَخَذَ عَلَى هَذَا عَشْرَ سِنِينَ. وَتُوُفِّيَ صَلواتُ اللهِ وَسَلامُهُ عَلَيْهِ وَدِينُهُ بَاقٍ، وَهَذَا دِينُهُ، لا خَيْرَ إِلا دَلَّ الأُمَّةَ عَلَيْهِ وَلا شَرَّ إِلا حَذَّرَهَا مِنْهُ، وَالْخَيْرُ الَّذِي دَلَّهَا عَلَيْهِ التَّوْحِيدُ وَجَمِيعُ مَا يُحِبُّهُ اللهُ وَيَرْضَاهُ، وَالشَّرُ الَّذِي حَذَّرَهَا مِنْهُ الشِّرْكُ وَجَمِيعُ مَا يَكْرَهُ اللهُ وَيَأْبَاهُ.

Nígbà tí Ànábì gúnlẹ̀ sí Màdíínà, wọ́n paá lásẹ àwọn òfin ẹ̀sìn yókù, bíi Sàká Owó yíyọ, Ààwẹ̀ gbígbà, Ìjọsìn Hajji, Ìrun pípè, Ogun jíjà, Ìpàsẹ dáadáa àti Ìkọ Àìdaa, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn Òfin Ẹ̀sìn. Ọdún mẹ́wá gbáko ni eléyá gbà. Ànábì –kí àlékún ìkẹ́ àti ìgẹ̀ Ọlọ́hun máa bá a- ti kú, ẹ̀sìn rẹ̀ sì sẹ́kù. Àwọn oun tí ó ti síwájú yí sì ni ẹ̀sìn rẹ̀. Kò sí ǹkankan tí oore wà níbẹ̀ àyàfi kí ó tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níka sí i, kò sì sí ǹkankan tí ó jẹ́ aburú àyàfi kí ó kìwọ́n nílọ̀ nipa rẹ̀. Àwọn oun rere tí ó tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níka sí ni: “Ìmú Ọlọ́hun lọ́kan soso, àti gbogbo oun tí Ọlọ́hun bá ní ìfẹ́ sí, tí Ó sì yọ́nú sí”. Àwọn oun aburú tí ó sì lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jìnnà sí ni: “Ẹbọ síse, àti èyíkéyí oun tí Ó bá kọ̀, tí kÒ sì nífẹ́ sí”.

بَعَثَهُ الله في النَّاسِ كَافَّةً، وَافْتَرَضَ طَاعَتَهُ عَلَى جَمِيعِ الثَّقَلَيْنِ الْجِنِّ وَالإِنْسِ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ جَمِيعًا( [الأعراف: 158].

Gbogbo ìran èèyàn pátá ni Ọlọ́hun rán Ànábì sí, Ó sì se ìtẹ̀le ní ọ̀ranyàn fún gbogbo ìran èèyàn àti alujannnu. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí  wípé: (Ìrẹ Ànábì, sọpé: “Ẹ̀yin ọmọnìyàn, òjísẹ́ Ọlọ́hun ni mo jẹ́ sí gbogbo yín pátá). (Ọgbà ọ̀rọ̀ àwọn alágbede méjì [Suratul Aaraafi], ẹsẹ 158).

وَكَمَّلَ اللهُ بِهِ الدِّينَ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الْإِسْلَامَ دِينًا( [المائدة: 3].

Ànábì yí ni Ọlọ́hun fi pé ẹ̀sìn Ìsìláámù. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí  wípé: (Ní òní yí, èmi (Ọlọ́hun) ti pé ẹ̀sìn yín fún yín, mo sì ti parí ìdẹ̀ra mi leyin lórí, Ìsìláámù ni mo sì yọ́nú sí lẹ́sìn fún yín). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Tábìlì Óunjẹ [Suratul Maaidati], ẹsẹ 3).

وَالدَّلِيلُ عَلَى مَوْتِهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّكَ مَيِّتٌ وَإِنَّهُمْ مَيِّتُونَ ^ ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عِنْدَ رَبِّكُمْ تَخْتَصِمُونَ( [الزمر: 30 - 31]. وَالنَّاسُ إِذَا مَاتُواْ يُبْعَثُونَ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )مِنْهَا خَلَقْنَاكُمْ وَفِيهَا نُعِيدُكُمْ وَمِنْهَا نُخْرِجُكُمْ تَارَةً أُخْرَى( [طه: 55]، وقَوْلُهُ تَعَالَى: )وَاللَّهُ أَنْبَتَكُمْ مِنَ الْأَرْضِ نَبَاتًا ^ ثُمَّ يُعِيدُكُمْ فِيهَا وَيُخْرِجُكُمْ إِخْرَاجًا( [نوح: 17 - 18]. وَبَعْدَ الْبَعْثِ مُحَاسَبُونَ وَمَجْزِيُّونَ بِأَعْمَالِهِمْ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ لِيَجْزِيَ الَّذِينَ أَسَاءُوا بِمَا عَمِلُوا وَيَجْزِيَ الَّذِينَ أَحْسَنُوا بِالْحُسْنَى( [النجم: 31]. وَمَنْ كَذَّبَ بِالْبَعْثِ كَفَرَ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )زَعَمَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَنْ لَنْ يُبْعَثُوا قُلْ بَلَى وَرَبِّي لَتُبْعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلْتُمْ وَذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ( [التغابن: 7].

Ẹ̀rí lórí ikú Ànábì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Dájúdájú ìwọ Ànábì yóò kú, kò sì sí iyèméjì pé àwọn aláìgbọràn náà yóò kú ^ lẹ́yìn náà, ẹó dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun yín ní ọjọ́ ìgbéǹde àlùkíyáámọ̀ lọ rèé yanjú gbogbo oun tí ń dá họ́ù họ́ù kalẹ̀ láàrin yín). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Ìjọ Ìjọ [Suratuz Zumar], ẹsẹ 30-31). Ìgbéǹde yóó sì sẹlẹ̀ sí ọmọ èèyàn lẹ́yìn ikú. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí  wípé: (Láti inú iyẹ̀pẹ̀ ni A ti sẹ̀dá yín, inú rẹ̀ náà ni A yóò sì dayín padà sí, láti inú rẹ̀ náà ni A yóò si ti gbéyin dìde ní ìgbà míràn). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Tọọhaa [Suratu Tọọhaa], ẹsẹ 55). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí  wípé: (Ọlọ́hun (Allahu) ni Ó fàyín yọ láti inú ilẹ̀ ní ti fífàyọ ^ Lẹ́yìn náà, yóò dayín padà sí inú rẹ̀, yóó tún wáá muyín jáde níti mímú jáde). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ànábì Nua [Suratu Nuuha], ẹsẹ 17-18). Lẹ́yìn àgbéǹde, ọmọ ènìyàn yóò se ìṣirò, wọn yóò sì gbẹ̀san isẹ́ wọn. Ẹ̀rí lórí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Ti Ọlọ́hun (Allahu) nìkan ni gbogbo oun tí ń bẹ ní sánmọ̀ àti ilẹ̀, kí Ọlọ́hun le san àwọn ẹni aburú le gbẹ̀san isẹ́ wọn, kí Ó sì le fi dáradára san àwọn ẹnire lẹ́san). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ìràwọ̀ [Suratun Najmi], ẹsẹ 31). Ẹni tí ó bà sì pe ìgbéǹde nírọ́ ti se kèfèrí. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Àwọn aláìgbàgbọ́ (Kèfèrí) lérò wípé wọn kò níí gbé àwọn dìde lẹ́yìn ikú. Sọ (Ìrẹ Ànábì) fún wọn wípé: “Kò rí bí ẹ se ń ró”. Ọlọ́hun yóò gbeyín dìde. lẹ́yìn náà, yóò tún sanyín lẹ́san isẹ́ tí ẹ gbáyé se. Eléyẹn (Ìsirò) sì jẹ́ oun tí ó rọ Ọlọ́hun lọ́rùn). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ìyanra Ẹni jẹ [Suratut Tagaabuni], ẹsẹ 7).

وَأَرْسَلَ اللهُ جَمِيعَ الرُّسُلِ مُبَشِّرِينَ وَمُنْذِرِينَ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )رُسُلًا مُبَشِّرِينَ وَمُنْذِرِينَ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى اللَّهِ حُجَّةٌ بَعْدَ الرُّسُلِ( [النساء: 165]. َوَأَّولُهُمْ نُوحٌ عَلَيْهِ السَّلامُ، وَآخِرُهُمْ مُحَمَّدٌ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ. وَهُوَ خَاتَمُ النَّبِيِّينَ، وَالدَّلِيلُ عَلَى أَنَّ أَوَّلَهُمْ نُوحٌ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّا أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ كَمَا أَوْحَيْنَا إِلَى نُوحٍ وَالنَّبِيِّينَ مِنْ بَعْدِهِ( [النساء: 163]، وكل أمة بعث الله إليهم رسولا من نوح إلى محمد يَأْمُرُهُمْ بِعِبَادَةِ اللهِ وَحْدَهُ وَيَنْهَاهُمْ عَنْ عِبَادَةِ الطَّاغُوتِ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَلَقَدْ بَعَثْنَا فِي كُلِّ أُمَّةٍ رَسُولًا أَنِ اُعْبُدُوا اللَّهَ وَاجْتَنِبُوا( [النحل: 36].

Isẹ́ tí Ọlọ́hun firán gbogbo àwọn òjísẹ́ tí ó gbé dìde pata ni ìmaa fún àwọn ènìyàn ni ìró idunnu àti ìmaa kìwọ́n nílọ̀. Ẹ̀rí rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Àwọn òjísẹ́ wọ̀nyí ni àwọn tí A gbé dìde láti máa fún àwọn ẹni rere ní ìró ìdùnní, kí wọn ó sì máa se ìkìlọ̀ fún àwọn òbìlẹ̀jẹ́, kí ọmọnìyàn má lè rí àwíjàre kan lẹ́yìn tí Ọlọ́hun ti gbé òjísẹ́ dìde síwọn). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin [Suratun Nisaai], ẹsẹ 165). Àkọ́kọ́ àwọn òjísẹ́ yí ni “Nua”. Ìgbẹ̀yìn wọn ni òjísẹ́ ńla Muhammadu kí àlékún ìkẹ́ àti ìgẹ̀ Ọlọ́hun máa ba. Muhammadu sì ni òpin gbogbo àwọn Ànábì Ọlọ́hun. Ẹ̀rí lórí wípé “Nua” ni àkọ́kọ́ àwọn òjísẹ́ Ọlọ́hun ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Dájúdájú àwa (Ọlọ́hun) ni A mí sí ìwọ (Muhammadu) gẹ́gẹ́ bí A se mí sí “Nua” àti gbogbo àwọn ànábì tí wọ́n wá lẹ́yìn rẹ̀). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin [Suratun Nisaai], ẹsẹ 163). Gbogbo ìjọ tí Ọlọ́hun rán òjísẹ́ sí pátá láti orí ànábì “Nua” tó fi dé orí “Muhammadu” ni ó jẹ́ wípé oun tí wọ́n máá ń pa àwọn èèyàn wọn lásẹ ni ìjọsìn fỌ́lọhun nìkan soso, àti ìkọ̀ fún wọn níbi ìjọsìn fún ǹkan míràn lẹ́yìn Ọlọ́hun. Ẹ̀rí rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Paa, awa (Ọlọ́hun) ti gbé dìde sí gbogbo ìjọ kọ̀ọ̀kan òjísẹ́ kan tí yóò máa sọ fún wọn wípé Ọlọ́hun nìkan ni kí ẹ máa jọ́sìn fún, kí wọn ó sì jinna sí ìjọsìn fún ǹkan míràn tí ó yàtọ̀ sí Ọlọ́hun). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Oyin [Suratun Nahli], ẹsẹ 36).

وَافْتَرَضَ اللهُ عَلَى جَمِيعِ الْعِبَادِ الْكُفْرَ بِالطَّاغُوتِ وَالإِيمَانَ بِاللهِ. قَالَ ابْنُ الْقَيِّمِ رَحِمَهُ اللهُ تَعَالَى: "مَعْنَى الطَّاغُوتِ مَا تَجَاوَزَ بِهِ الْعَبْدُ حَدَّهُ مِنْ مَعْبُودٍ أَوْ مَتْبُوعٍ أَوْ مُطَاعٍ. وَالطَّوَاغِيتُ كَثِيرُونَ؛ وَرُؤُوسُهُمْ خَمْسَةٌ، إِبْلِيسُ لَعَنَهُ اللهُ، وَمَنْ عُبِدَ وَهُوَ رَاضٍ، وَمَنْ دَعَا النَّاسَ إِلَى عِبَادَةِ نَفْسِهِ، وَمَنْ ادَّعَى شَيْئًا مِنْ عِلْمِ الْغَيْبِ، وَمَنْ حَكَمَ بِغَيْرِ مَا أَنْزَلَ اللهُ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )لَا إِكْرَاهَ فِي الدِّينِ قَدْ تَبَيَّنَ الرُّشْدُ مِنَ الْغَيِّ فَمَنْ يَكْفُرْ بِالطَّاغُوتِ وَيُؤْمِنْ بِاللَّهِ فَقَدِ اسْتَمْسَكَ بِالْعُرْوَةِ الْوُثْقَى لَا انْفِصَامَ لَهَا وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ( [البقرة: 256]، وَهَذَا هُوَ مَعْنَى لا اله إِلا اللهُ. وَفِي الْحَدِيثِ: «رَأْسُ الأَمْرِ الإِسْلامِ وَعَمُودُهُ الصَّلاةُ وَذِرْوَةُ سَنَامِهِ الْجِهَادُ فِي سَبِيلِ اللهِ». وَاللهُ أعلم.

Ọlọ́hun (Allahu) se ìgbẹ́rùgbọnrí sí oun ìfẹ́ inú tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Ọlọ́hun, àti ìnígbàgbọ́ sí Ọlọ́hun nìkan soso ní ọ̀ranyàn fuń àwọn ẹrúsìn rẹ̀. Olùmọ̀ àgbà Ibnul Qayyimi –kí Ọlọ́hun lé kún ìkẹ́ rẹ̀- sọ nínú ọ̀rọ̀ tiwọn wípé: “Ìtumọ̀ “Taaguutu” ni oun tí ẹrú bá tasẹ̀ àgẹ̀ẹ̀rẹ̀ lòrí rẹ̀ níbi sísìn, tàbí títẹ̀lé, tàbí ìgbọràn sí lẹ́nu. Àwọn “taaguutu” yí wáá pọ̀ rẹpẹtẹ; àwọn olori wọn jẹ́ marun: “Bìlísì (Èsù) kí Ọlọ́hun gbé e jinna sí ìkẹ́, gbogbo ẹni tí ó bá yọ́nú sí kí wọn ó máa jọ́sìn fún un, gbogbo ẹni tí ó bá ń pe àwọn èèyàn lọ sí ibi ìjọsìn fuń un, ẹni tí ó bá ń pe àpèmọ́ra ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀, àti ẹni tí ó bá ń fi oun tí ó yàtọ̀ sí òfin Ọlọ́hun se ìdájọ́. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (kò sí ìfipámúni níbi ẹ̀sìn, nitoripé ọ̀nà òdodo ti fojú han lẹ́gbẹ́ ọ̀nà anù. Ẹni tí ó bá gbẹ́rùgbọnrí tàbí se (kèfèrí) sí ǹkan míràn tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Ọlọ́hun, paa, ó ti di okun Ọlọ́hun tí ó nípọn tí kò lè já mú. Ọlọ́hun Ọba tí ó ń gbọ́ tí ó sì nímọ̀ jùlọ ni). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ògédègbe Màálù [Suratul Bagbarati], ẹsẹ 256). Eléyí ni ìtumọ̀ “Laa ilaha illal lahu”. Ó tún wà nínú ọ̀rọ̀ (Hadiisi) Ànábì –kí àlékún ìkẹ́ àtí ìgẹ̀ máa báa- wípé: “Olórí gbogbo àláámọ̀rí pátá ni ìjupá jusẹ̀ sílẹ̀ (Ìsìláámù) fún Ọlọ́hun, Òpó tí ó sì gbé ẹ̀sìn dúró ní ìrun kíkí, Eyín ọ̀gàn rẹ̀ sì ni jíjagun sí ojú ọ̀nà Ọlọ́hun. Ọlọ́hun nìkan ni Ó nímọ̀ jùlọ.

Wednesday, 27 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹrìnlá)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
الأَصْلُ الثَّالِثُ
ÌPÌLẸ̀ ẸLẸ́Ẹ̀KEJÌ

مَعْرِفَةُ نَبِيِّكُمْ مُحَمَّدٍ صَلَّى اللهُ عليه وسلم
MÍMỌ̀ NÍPA ÀNÁBÌ YÍN TÍÍ SE MUHAMMADU (Kí Ọlọ́hun Lékún Ìkẹ́ àti Ìgẹ̀ Rẹ̀)

وَهُوَ مُحَمَّدُ بْنُ عَبْدِ اللهِ بْنِ عَبْدِ الْمُطَّلِبِ بْنِ هَاشِمٍ، وَهَاشِمٌ مِنْ قُرَيْشٍ، وَقُرَيْشٌ مِنَ الْعَرَبِ، وَالْعَرَبُ مِنْ ذُرِّيَّةِ إِسْمَاعِيلَ بْنِ إِبْرَاهِيمَ الْخَلِيلِ عَلَيْهِ وَعَلَى نَبِيِّنَا أَفْضَلُ الصَّلاةِ وَالسَّلامِ. وَلَهُ مِنَ الِعُمُرِ ثَلاثٌ وَسِتُّونَ سَنَةً؛ مِنْهَا أَرْبَعُونَ قَبْلَ النُّبُوَّةِ وَثَلاثٌ وعشرون نبيا رسولا.

Òun náà ni Muhammadu Ọmọ Abdullahi Ọmọ Abdul Muttalibi Ọmọ Haaṣimi. Haaṣimi sì jẹ́ ìran Kùráíṣí, Kùráíṣí sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Lárúbáwá, nígbà tí Lárúbáwá jẹ́ àrọmọdọ́mọ Ismaaiila Ọmọ Ibraaiimọ (Kí èyí tí ó lọ́lá jùlọ nínú ìkẹ́ àti ìgẹ̀ máa bá òhun àti Ànábì wa). Gbogbo ọjọ́ orí Ànábì sì jẹ́ ọdún mẹ́ta lé láàdọ́ta (63); Ó lo ogójì (40) síwájú kí ìmísí tóó bẹ̀rẹ̀ fun un, Ó sì fi ọdún mẹ́ta lé lógún (23) gba ìmísí àti jísẹ́ Ọlọ́hun.

نبئ باقرأ، وأرسل بالمدثر. وَبَلَدُهُ مَكَّةُ. بَعَثَهُ اللهُ بِالنِّذَارَةِ عَنِ الشِّرْكِ ويدعو إِلَى التَّوْحِيدِ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )يَا أَيُّهَا الْمُدَّثِّرُ ^ قُمْ فَأَنْذِرْ ^ وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ ^ وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ ^ وَالرُّجْزَ فَاهْجُرْ ^ وَلَا تَمْنُنْ تَسْتَكْثِرُ ^ وَلِرَبِّكَ فَاصْبِرْ( [المدثر: 1 - 7]. وَمَعْنَى "قُمْ فَأَنذِرْ": يُنْذِرُ عَنِ الشِّرْكِ وَيَدْعُو إلى التوحيد. "وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ": عَظِّمْهُ بِالتَّوْحِيدِ. "وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ": أَيْ طَهِّرْ أَعْمَالَكَ من الشِّرْكِ. "وَالرُّجْزَ فَاهْجُرْ": الرُّجْزَ: الأَصْنَامُ. وَهَجْرُهَا: تَرْكُهَا وأهلها، وَالْبَرَاءَةُ مِنْهَا وَأَهْلُهَا.

Ọgbà Ọ̀rọ̀ “Kàá” (Suratu Ikra tàbí Alaki) ni ìmísí fi bẹ̀rẹ̀ fún un, nígbà tí ìgbe dìde gẹ́gẹ́ bí òjísẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ọgbà Ọ̀rọ̀ Olùdasọbora (Suratul Muddassiri). Mákkà sì ni ìlú abínibí rẹ̀. Ọlọ́hun gbée dìde pẹ̀lú ìkininílọ̀ níbi ẹbọ àti ìmáa pèpè lọ síbi ìmú Ọlọ́hun (Allahu) lọ́kan soso. Ẹ̀rí lórí èyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyì wípé: (Ìrẹ olùdasọbora ^ Dìde láti máa ki àwọn èẹìyàn nílọ̀ ^ Ọlọ́hun asẹ̀dá rẹ nìkan sìni kí o máa bàbàrà ^ kí o sì tún máa se ìmọ́tótó tinú tòde rẹ ^ gbogbo oun tó bá sì jẹmọ́ oun ẹlẹ́gbin, kí o takété sí wọn ^ sì jinna sí ìrègún síse, èyí tí ó lè máa mú ọ bàbàra sàárá tí o ti se). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Olùdasọbora [Suratul Muddassiri], ẹsẹ 1-7). Ìtumọ gbólóhùn “Dìde láti máa ki àwọn èẹìyàn nílọ̀” nipé kí Ànábì máa se ìkìlọ̀ kúrò níbi ẹbọ, kí ó sì maa pèpè lọ síbi ìmú Ọlọ́hun lọ́kan soso. Gbólóhùn “Ọlọ́hun asẹ̀dá rẹ nìkan sìni kí o máa bàbàrà” ń túmọ̀ sí “Bàbàrà rẹ̀ pẹ̀lú ìmu lọ́kan soso”. Gbólóhùn “kí o sì tún máa se ìmọ́tótó tinú tòde rẹ” ń túmọ̀ sí “Se àfọ̀mọ́ àwọn ìsẹ́ rẹ kúrò níbi ẹbọ”. Gbólóhùn “Gbogbo oun tó bá sì jẹmọ́ oun ẹlẹ́gbin, kí o takété sí wọn”. “Oun ẹlẹ́gbin” ni “Àwọn òrìsà”. Jíjìnnà sí wọn sì ni “Ìtakété síwọn àti àwọn tí ó ń bọwọ́n, pẹ̀lú ìbọ́pábọ́sẹ̀ kúrò níbi sísìn wọ́n àti àwọn olùjọ́sìn fún wọn”. 

أَخَذَ عَلَى هَذَا عَشْرَ سِنِينَ يَدْعُو إِلَى التَّوْحِيدِ، وَبَعْدَ الْعَشْرِ عُرِجَ بِهِ إِلَى السَّمَاءِ وَفُرِضَتْ عَلَيْهِ الصَّلَواتُ الْخَمْسُ. وَصَلَّى فِي مَكَّةَ ثَلَاثَ سِنِينَ، وَبَعْدَهَا أَمَرَ بِالْهِجْرَةِ فِي الْمَدِينَةِ.

Ànábì lo ọdún mẹ́wá gbáko lórí ìpèpè lọ síbi ìmú Ọlọ́hun lọ́kan. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wà yẹn, Ọlọ́hun mú un gun òkè sánmọ̀ lọ, ibẹ́ ni wọ́n ti se ìrun wákàtí máàrún ní ọ̀ranyàn le òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lórí. Ó kírun fún ọdún mẹ́ta ní ìlú Mákkà, lẹ́yìn náà ni wọ́n pá làsẹ ìsípò padà (Híjírá) lọ sí ìlú Madiina.

وَالْهِجْرَةُ: الانْتِقَالُ مِنْ بَلَدِ الشِّرْكِ إِلَى بَلَدِ الإِسْلامِ. وَالْهِجْرَةُ فَرِيضَةٌ عَلَى هَذِهِ الأُمَّةِ مِنْ بَلَدِ الشِّرْكِ إِلَى بلد الإِسْلامِ، وَهِيَ بَاقِيَةٌ إِلَى أَنْ تَقُومَ السَّاعَةُ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّ الَّذِينَ تَوَفَّاهُمُ الْمَلَائِكَةُ ظَالِمِي أَنْفُسِهِمْ قَالُوا فِيمَ كُنْتُمْ قَالُوا كُنَّا مُسْتَضْعَفِينَ فِي الْأَرْضِ قَالُوا أَلَمْ تَكُنْ أَرْضُ اللَّهِ وَاسِعَةً فَتُهَاجِرُوا فِيهَا فَأُولَئِكَ مَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ وَسَاءَتْ مَصِيرًا ^ إِلَّا الْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ الرِّجَالِ وَالنِّسَاءِ وَالْوِلْدَانِ لَا يَسْتَطِيعُونَ حِيلَةً وَلَا يَهْتَدُونَ سَبِيلًا ^ فَأُولَئِكَ عَسَى اللَّهُ أَنْ يَعْفُوَ عَنْهُمْ وَكَانَ اللَّهُ عَفُوًّا غَفُورًا( [النساء: 97 - 99]. وَقَوْلُهُ تَعَالَى: )يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ أَرْضِي وَاسِعَةٌ فَإِيَّايَ فَاعْبُدُونِ( [العنكبوت: 56]. قَالَ البَغَوِيُّ رَحِمَهُ اللهُ: "سَبَبُ نُزُولِ هَذِهِ الآيَةِ فِي المُسْلِمِينَ الَّذِينَ فِي مَكَّةَ لَمْ يُهَاجِرُوا، نَادَاهُمُ اللهُ بِاسْمِ الإِيمَانِ".

Ìsípò padà (Híjírá) ni ìsí kúrò ní ìlú ẹbọ lọsí ilẹ̀ Ìsìláámù. Sísí kúrò ní ìlú ẹbọ lọ sí ilẹ̀  Ìsìláámù (Híjírá) yí sì pọn dandan fún àwọn ọmọlẹ́yìn ànábì. Ààyè sì gba síse rẹ̀ títí di ìgbà tí ayé kò níí jẹ́ ayé mọ́. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Dájúdájú àwọn tí àwọn Màláíkà gbẹ̀mí wọn lẹ́ni tí wọ́n sàbòsí ara wọn pẹ̀lú àìse híjírá pẹ̀lú àwọn musulumi, àwọn Màláíkà yí yóò máa fi wọ́n se yẹ̀yẹ́ wípé: “Ibo lẹ bá ẹ̀sìn dé?”, wọn yóò sì máa fesi wípé: “Àwa jẹ́ ẹni tí àwọn ará Mákkà dí lọ́wọ́ láti se ẹ̀sìn”. Àwọn Màláíkà náà yóó tún màa fún wọn lésì wípé: “Sé ilẹ̀ Ọlọ́hun kò wáá fẹ̀ debi tí ẹ fi lè sí lọ sí ibòmíràn?”. Nítorínáà, ibùdésí àwọn èèyàn yí ni iná jáǹnámà. Síọ̀ ibùdésí náà ^ Àyàfi àwọn tí wọ́n jẹ gaba lé lórí lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé, tí wọn kò ní ọ̀nà àbayọ kankan, tí wọn kò sì le dá mọ ọ̀nà ^ Óséése kí Ọlọ́hun se àmójú kúrò fún irú wọn. Ọlọ́hun jẹ́ Alámójú kúrò, Aláforíjìn jùlọ) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin [Suratun Nisaai], ẹsẹ 97-99). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Ẹ̀yin ẹrúsìn mi tó jẹ́ olúgbágbọ́ òdodo, dájúdájú ilẹ̀ èmi (Ọlọ́hun) tẹ́ pẹrẹsẹ. Torínáà, èmi (Ọlọ́hun) nìkan ni kí ẹ máa sìn). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Aláǹtakùn [Suratul Ankabuuti], ẹsẹ 56). Olúmọ́ Àgbà ọmọ bibi ilẹ̀ “baga” (Al bagawiyyu) –kí Ọlọ́hun kẹ́ wọn- sọpé:  “Okùnfà sísọ̀ kalẹ̀ ẹsẹ ọ̀rọ̀ (Aayati) yí ni dídúró àwọn kan ní ílú Mákka láì se Hijira, Ọlọ́hun fi orúkọ ìgbàgbọ́ pè wọ́n”.

وَالدَّلِيلُ عَلَى الْهِجْرَةِ مِنَ السُّنَّةِ قَوْلُهُ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «لا تَنْقَطِعُ الْهِجْرَةُ حَتَّى تَنْقَطِعَ التَّوْبَةُ وَلا تَنْقَطِعُ التَّوْبَةُ حَتَّى تَطْلُعَ الشَّمْسُ مِنْ مغربها».


Ẹ̀rí láti inú ọ̀rọ̀ Ànábì ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó lọ báyí wípé: »Ìyírapadà (Hijrah) kò níí dópin títí òpin yóò fi dé bá ìtúúbá, òpin kò sì le débá ìtúúbá títí tí òòrùn yóò fi yọ níbi tí ó ti ń wọ̀

Sunday, 24 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹtàlá)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
المرتبة الثالثة: الإحسان
Ìpele Ẹ̀kẹta: Ìse dáadáa (Ìhsàánù)

وَلَهُ رُكْنٌ وَاحِدٌ كَمَا فِي الَحِديثِ: «أَنْ تَعْبُدَ اللهَ كَأَنَّكَ تَرَاهُ فَإِنْ لَمْ تَكُنْ تَرَاهُ فَإِنَّهُ يَرَاكَ».

Orígun kan péré ni ti ìse dáadáa (Ìhsàánù) náà gẹ́gẹ́ bó ti se wà nínú ọ̀rọ̀ Ànábì (Hàdíìsì) tó sọ wípé: »Òun náà ni kí o máa sin Ọlọ́hun (Allahu) bíi pé ò ń ríI (Ọlọ́hun), tí oò bá wáá le sìn Ín (Ọlọ́hun) bíi pé ò ń ríI, sì máa sìn ín pẹ̀lú àmọ̀dájú wípé Òun ń rí ìrẹ).

وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّ اللَّهَ مَعَ الَّذِينَ اتَّقَوْا وَالَّذِينَ هُمْ مُحْسِنُونَ( [النحل: 128]، وقَوْلُهُ تَعَالَى: )وَتَوَكَّلْ عَلَى الْعَزِيزِ الرَّحِيمِ ^ الَّذِي يَرَاكَ حِينَ تَقُومُ ^ وَتَقَلُّبَكَ فِي السَّاجِدِينَ ^ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ( [الشعراء: 217 - 220]، وقَوْلُهُ تَعَالَى: )وَمَا تَكُونُ فِي شَأْنٍ وَمَا تَتْلُو مِنْهُ مِنْ قُرْآنٍ وَلَا تَعْمَلُونَ مِنْ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيْكُمْ شُهُودًا إِذْ تُفِيضُونَ فِيهِ( [يونس: 61].

Ẹ̀rí lórí wípé ìse dáadáa (Ìhsàánù) wà nínú àwọn ìpele ẹ̀sìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Dájúdájú Ọlọ́hun wà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ní ìpayà rẹ̀ àti àwọn tí wọ́n bá ńse dáadáa). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Kòkòrò Oyin [Suratun Nahli], ẹsẹ 128). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Kí o sì fi ara ti Ọlọ́hun Ọba alágbára aláànú jùlọ ^ Ọba tí Ó ń rí ìrẹ nígbà tí o bá gbé ìrun dúró ^ Àti ìgbà tí o bá ńlọ ìforíbalẹ̀ ^ Dájúdájú Ọlọ́hun (Allahu) ni ọba tí Ó tayọ oun gbogbo ní gbígbọ́ tí Ó sì ní ìmọ̀ jùlọ). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Akunrin [Suratus Shuaraai], ẹsẹ 217-220). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ tún lọ báyí wípé: (Kò sí ipòkípo kan tí ìrẹ ànábì wà, bẹ́ẹ̀ ni oò níí ka ọ̀rọ̀ kan nínú ìwé òfin Al kuraani, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò níí se isẹ́ kan àyàfi kó jẹ́ wípé àwa Ọlọ́hun (Allahu) ríi nígbà tí ẹ̀ ń sé). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ànábì Yuunusa [Suratu Yuunusa], ẹsẹ 61).

وَالدَّلِيلُ مِنَ السُّنَّةِ: حَدِيثُ جِبْرِيلَ الْمَشْهُورُ عَنْ عُمَرَ بنِ الْخَطَّابِ رَضِيَ اللهُ عَنْهُ قَالَ: «بينما نحن جُلُوسٌ عِنْدَ النَّبِيِّ -r- إِذْ طَلَعَ عَلَيْنَا رَجُلٌ شَدِيدُ بَيَاضِ الثِّيَابِ شَدِيدُ سَوَادِ الشَّعْرِ لا يُرَى عَلَيْهِ أَثَرُ السَّفَرِ وَلا يَعْرِفُهُ مِنَّا أَحَدٌ فَجَلَسَ إِلَى النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَأَسْنَدَ رُكْبَتَيْهِ إِلَى رُكْبَتَيْهِ وَوَضَعَ كَفَّيْهِ عَلَى فَخِذَيْهِ وَقَالَ: يَا مُحَمَّدُ أَخْبِرْنِي عَنِ الإِسْلامِ فَقَالَ: أَنْ تَشْهَدَ أَنْ لا اله إِلا اللهُ وَأَنَّ مُحَمَّدًا -r- رَسُولُ اللهِ، وَتُقِيمَ الصَّلاةَ، وَتُؤْتِيَ الزَّكَاةَ، وَتَصُومَ رَمَضَانَ، وَتَحُجَّ الْبَيْتَ إِنْ اسْتَطَعْتَ إِلَيْهِ سَبِيلا. قَالَ: صَدَقْتَ. فَعَجِبْنَا لَهُ يَسْأَلُهُ وَيُصَدِّقُهُ. قَالَ: أَخْبِرْنِي عَنِ الإِيمَانِ قَالَ: أَنْ تُؤْمِنَ بِاللهِ، وَمَلَائِكَتِهِ، وَكُتُبِهِ وَرُسُلِهِ وَالْيَوْمِ الآخِرِ، وَبِالْقَدَرِ خَيْرِهِ وَشَرِّهِ. قَالَ: أَخْبِرْنِي عَنِ الإِحْسَانِ. قَالَ: أَنْ تَعْبُدَ اللهَ كَأَنَّكَ تَرَاهُ، فَإِنْ لَمْ تَكُنْ تَرَاهُ، فَإِنَّهُ يَرَاكَ. قَالَ: أَخْبِرْنِي عَنِ السَّاعَةِ. قَالَ: مَا الْمَسْؤُولُ عَنْهَا بِأَعْلَمَ مِنَ السَّائِلِ. قَالَ: أَخْبِرْنِي عَنْ أَمَارَاتِهَا. قَالَ: أَنْ تَلِدَ الأَمَةُ رَبَّتَهَا، وَأَنْ تَرَى الْحُفَاةَ الْعُرَاةَ الْعَالَةَ رِعَاءَ الشَّاءِ يَتَطَاوَلُونَ فِي الْبُنْيَانِ. قَالَ: فَمَضَى، فَلَبِثْنَا مَلِيَّا. فَقَالَ: يَا عُمَرُ، أَتَدْرُونَ مَنِ السَّائِلِ؟ قُلْنَا: اللهُ وَرَسُولُهُ أَعْلَمُ، قَالَ: هَذَا جِبْرِيلُ، أَتَاكُمْ يُعَلِّمُكُمْ أَمْرَ دِينِكُم».

Ẹ̀rí láti inú ọ̀rọ̀ Ànábì ni hàdíìsì tí ó gbajúmọ̀ sí hàdíìsì màláíkà Jùbìríílà èyí tí Òmárù (Kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i) gbà wá báyí wípé: (Ní àlàfo wípé a jókó lọ́dọ̀ Ànábì ní ọjọ́kan, sàdéédé ni arákùnrin kan yọ síwa. Asọ arákùnrin náà funfun gbòò, irun orí rẹ̀ dúdú kirimu, a kò rí àmì arìnrìn àjò lára rẹ̀, ọ̀kankan kò sì mọ̀ ọ́n rí nínú àwa tí a wà níkàlẹ. Arákùnrin yí bá fìkàlẹ̀ síwájú Ànábì lẹ́ni tófi orúkún rẹ̀ ko orúnkún Ànábì, tó sì da àtẹlẹwọ́ rẹ̀ méjéèjì dé itan rẹ̀ méjéèjì. Ó wáá sọpé ìrẹ Muhammadu: “fún mi níró nípa Ìsìláámù”. Ànábí sì dáa lóhùn wípé: “Ìsìláámù ni kí o jẹ́rí à jẹ́ dọ́kàn wípé kòsí nkànkan tó lẹ́tọ́ sí ìjọsìn lódodo àyàfi Ọlọ́hun (Allahu), àti wípé Muhammadu òjísẹ́ Ọlọ́hun ni. Kí o sì tún máa gbé ìrun dúró fún Ọlọ́hun, àti kí o máa yọ sàká owó rẹ, àti kí o máa gba ààwẹ̀ Rámọ́láánà, àti kí o se ìjọsìn Hajji lọ sí ilé Ọlọ́hun ní ìlú Makka tí o bá ti lágbára à ti lọ”. Arákùnrin yí sì fesi wípé: “Òdodo lo sọ”. Èǹmọ̀ se wá látààrí wípé òun náà ni ń dáa tí ń gbèé. Arákùnrin yí tún tẹ̀ síwájú lẹ́ni tó sọpé: “Fún mi níró nípa ìgbàgbọ́ (Íímọ́ọ́nì)”. Ànábí sì tún dáa lóhùn wípé: “Ìgbàgbọ́ (Íímọ́ọ́nì) ni kí o ní ìgbàgbọ́ òdodo sí Ọlọ́hun, àti àwọn áńgẹ́lì (Màláíkà) Rẹ̀, àti àwọn ìwé òfin tí Ó fún àwọn òjísẹ́ Rẹ̀, àti àwọn òjísẹ́ Rẹ̀, àti ọjọ́ àgbéǹde àlùkìyáámọ̀, àti àkọsílẹ̀ (kádàrá), dáradára ni tàbí àìda”. Arákùnrin yí tún tẹ̀ síwájú lẹ́ni tó sọpé: “Fún mi níró nípa ìse dáadáa (Ihsaan)”. Ànábí tún dáhùn wípé: “ìse dáadáa (Ihsaan) ni kí o máa sin Ọlọ́hun (Allahu) bíi pé ò ń ríI (Ọlọ́hun), tí oò bá wáá le sìn Ín (Ọlọ́hun) bíi pé ò ń ríI, sì máa sìn ín pẹ̀lú àmọ̀dájú wípé Òun ń rí ìrẹ”. Arákùnrin yí tún ní: “Sọ fún mi nípa ìgbà tí ìgbéǹdé àlùkìyáámọ̀ yóò dé”. Ànábí dáhùn wípé: “Ẹni tí wọ́n ń bi kò tó ẹni tí ń bèèrè nímọ̀ nípa dide rẹ̀”. Arákùnrin yí bání: “Sọ àwọn àmì dide rẹ̀ fúnmi”. Ànábí sì dáhùn wípé: “Àwọn àmì dídé rẹ̀ ni kí àwọn ẹrú lobinrin ó máa bí àwọn tí yóò máa se ọ̀gá léwọn lórí, àti kí o máa rí àwọn aláìnì bàtà ní ẹsẹ̀, àti aláìní asọ lọ́rùn, otòsì èèyàn kí wọn ó máa la ilé alájà àjà mọ́lẹ̀”. Òmárù (Kí Ọlọ̀hun yọ́nú si) sọ wípé arákùnrin yí bá pẹ̀yìndà. Kò pẹ́ púpọ̀ sí ìgbà tó lọ ni Ànábì sọpé: “Ìrẹ Òmárù, ǹjẹ́ ẹ mọ arákùnrin oní ọ̀pọ̀lọpọ̀ íbèèrè tó wá yẹn bí?”. Gbogbo wa sì dáhun wípé: “Ọlọ́hun àti òjísẹ́ rẹ̀ nìkan ni wọ́n mọ̀ ọ́n”. Ànábì wáá sọpé: “Jùbìríílà ló wá tí ẹ rí un, ó wá láti wáá kọyín nípa àláámọ̀rí ẹ̀sìn yín ni”.

Thursday, 21 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kejìlá)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
الْمَرْتَبَةُ الثَّانِيَةُ: الإِيمَانُ
Ìpele Èkejì: Ìgbàgbọ́ Òdodo (Íímáánì)

وَهُوَ بِضْعٌ وَسَبْعُونَ شُعْبَةً، فَأَعْلاهَا قَوْلُ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَأَدْنَاهَا إِمَاطَةُ الأَذَى عَنِ الطَّرِيقِ، وَالْحَيَاءُ شُعْبَةٌ مِنْ الإِيمَانِ.

Èkíké tàbí ìdá lọ́nà ààdọ́rin lé díẹ̀ ni ó pín sí. Èyí tí ó gba waju tó sì ga jù nínú àwọn ìdá yí ni gbólóhùn ìjẹ́rí “Laa Ilaaha Illaa Allahu”, èyí tó sì kéré jùlọ nínú wọn ni “mímú ohun ìpalára [Bí ọ̀páláńbá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ] kúró ní ojú ọ̀nà ìrìnsẹ̀ àwọn ohun abẹ̀mí. Ìtìjú gan nínú àwọn èkíké ìgbàgbọ́ lówà.

وَأَرْكَانُهُ سِتَّةٌ كَمَا فِي الحَدِيثِ: «أَنْ تُؤْمِنَ بِاللهِ، وَمَلائِكَتِهِ، وَكُتُبِهِ، وَرُسُلِهِ، وَالْيَوْمِ الآخِرِ، وَبِالْقَدَرِ خَيْرِهِ وَشَرِّهِ».

Mẹ́fà péré ni àwọn orígun ìgbàgbọ́ jẹ́, gẹ́gẹ́ bó ti se wà nínú ọ̀rọ̀ Ànábì (Hàdíìsì) tó sọ wípé: »Òun ni kí o ní ìgbàgbọ́ òdodo sí Ọlọ́hun, àti àwọn áńgẹ́lì (Màláíkà) Rẹ̀, àti àwọn ìwé òfin tí Ó fún àwọn òjísẹ́ Rẹ̀, àti àwọn òjísẹ́ Rẹ̀, àti ọjọ́ àgbéǹde àlùkìyáámọ̀, àti àkọsílẹ̀ (kádàrá), dáradára ni tàbí àìda«.

وَالدَّلِيلُ عَلَى هَذِهِ الأَرْكَانِ السِّتَةِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )لَيْسَ الْبِرَّ أَنْ تُوَلُّوا وُجُوهَكُمْ قِبَلَ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَلَكِنَّ الْبِرَّ مَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَالْمَلَائِكَةِ وَالْكِتَابِ وَالنَّبِيِّينَ( [البقرة: 177]. وَدَلِيلُ الْقَدَرِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّا كُلَّ شَيْءٍ خَلَقْنَاهُ بِقَدَرٍ( [القمر: 49].

Ẹ̀rí lórí wípé sise àwọn òpó mẹ́fẹ̀ẹ̀fà yí ni ó gbé ìgbàgbọ́ dúró ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Ìgbàgbọ́ kò pin sórí dídojúkọ ibùyọ àti ibùwọ̀ òrùn, sùgbọ́n ẹni tí olùgbàgbọ́ tòótọ́ ni ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ ododo nínú Ọlọ́hun (Allahu), àti ọjọ́ àgbéǹde àlùkìyáámọ̀, àti àwọn áńgẹ́lì (Màláíkà), àti àwọn ìwé òfin tí Ó fún àwọn òjísẹ́, àti àwọn òjísẹ́).  (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ogédègbe Màálù [Suratul Bakọrati], ẹsẹ 177). Ẹ̀rí lórí wípé àkọsílẹ̀ (kádàrá) náà wà nínú orígun ìgbàgbọ́ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Oun gbogbo pata ni Àwa Ọlọ́hun ti parí àkọsílẹ̀ (kádàrá) lé lórí). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Òsùpá [Suratul Kọ́mọrì], ẹsẹ 49).

Tuesday, 19 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kọkànlá)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
وَدَلِيلُ الصَّلاةِ وَالزَّكَاةِ وَتَفْسِيرُ التَّوْحِيدِ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ حُنَفَاءَ وَيُقِيمُوا الصَّلَاةَ وَيُؤْتُوا الزَّكَاةَ  وَذَلِكَ دِينُ الْقَيِّمَةِ﴾ [البينة: 5].

Ẹ̀rí lórí “Ìrun kíkí, Sàká Owó yíyọ”, àti ìtumọ̀ “Ìmọ̀ Ọlọ́hun lọ́kan (At Taohiidu) ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Ọlọ́hun kò pa’wọ́n lásẹ ǹkankan tó kọjá kí wọ́n máa se àfọ̀mọ́ ìjọsìn wọn fún Ọlọ́hun nìkan soso láì kò mú orogún mọ́ Ọn, kí wọ́n sì máa gbé ìrun dúró fún Ọlọ́hun, kí wọ́n sì máa yọ Sàká Owó wọn. Eléyẹn sì ni ẹ̀sìn tó dúró tọ́). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ẹ̀rí tó Fojú Hàn [Suratul Bayyinati], ẹsẹ 5).

ودَلِيلُ الصِّيَامِ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ﴾ [البقرة: 183].

Ẹ̀rí lórí wípé Ààwẹ̀ “Rámáláánà” gbígbà wà nínú àwọn origun ẹ̀sìn Ìsìláámù ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Ẹ̀yin olùgbàgbọ́ ododo, Ọlọ́hun ti se ààwẹ̀ “Rámàláánà” gbígbà ní ọ̀ranyàn fun yín, gẹ́gẹ́ bí À ti sé ní ọ̀ranyàn lé àwọn tó siwájú yín lórí, boya yóó le jẹ́ okùnfà ìbẹ̀rù Ọlọ́hun fun yín). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ogédègbe Màálù [Suratul Bakọrati], ẹsẹ 183).

وَدَلِيلُ الْحَجِّ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿وَلِلَّهِ عَلَى النَّاسِ حِجُّ الْبَيْتِ مَنِ اسْتَطَاعَ إِلَيْهِ سَبِيلًا  وَمَنْ كَفَرَ فَإِنَّ اللَّهَ غَنِيٌّ عَنِ الْعَالَمِينَ﴾ [آل عمران: 97].

Ẹ̀rí lórí wípé sise àbẹ̀wò ilé Ọlọ́hun ní Mákà “Hajju” wà nínú àwọn origun ẹ̀sìn Ìsìláámù ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Ọlọ́hun (Allahu) pọ́n ní dandan lórí gbogbo ọmọnìyàn tỌ́lọ́hun bùkún tó sì lágbára, síse àbẹ̀wò ilé Ọlọ́hun ní Mákkà (Ìjọsìn Hájjù). Ẹni tó bá sì gbẹ́rù gbọnrí tó ní òhun kò sé é (Tó sì lágbára à ti sé é). kó lọ rèémọ̀ wípé Ọlọ́hun rọrọ̀, kò sì bùkáátà sí ìkankan nínú gbogbo ohun tó sẹ̀dá). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ àwọn aráálé Umuraana [Suratu Aali Umuraana], ẹsẹ 97).

Monday, 18 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹwà)

الأَصْلُ الثَّانِي
ÌPÌLẸ̀ ẸLẸ́Ẹ̀KEJÌ
مَعْرِفَةُ دِينِ الإِسْلَامِ بِالأَدِلَّةِ
MÍMỌ̀ NÍPA Ẹ̀SÌN PẸ̀LÚ ÀWỌN ÌTỌ́KA RẸ̀

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
وَهُوَ: الاسْتِسْلامُ للهِ بِالتَّوْحِيدِ، وَالانْقِيَادُ لَهُ بِالطَّاعَةِ، وَالْبَرَاءَةُ مِنَ الشِّرْكِ وَأَهْلِهِ. وَهُوَ ثَلاثُ مَرَاتِبَ: الإسْلامُ، وَالإِيمَانُ، وَالإِحْسَانُ. وَكُلُّ مَرْتَبَةٍ لَهَا أَرْكَانٌ.
Oun tí ń jẹ́ Ìsìláámù ni ìjupá jusẹ̀ sílẹ̀ fún Ọlọ́hun (Allahu) pẹ̀lú gbígbá lọ́kan soso, àti ìtẹríba pẹ̀lú ìyẹpẹrẹ ara ẹni fún àsẹ Rẹ̀, àti ìbọ́pábọ́sẹ̀ kúrò níbi àwọn isẹ́ àti àdìsọ́kàn ẹbọ àti àwọn ẹlẹ́bọ. Àwọn ìpele tí ẹ̀sìn Ìsìláámù ní jẹ́ mẹ́ta, àwọn náà ni: Ìjupá jusẹ̀ sílẹ̀ (Ìsìláámù), Ìgbàgbọ́ Òdodo (Íímáánì), Ìse daadaa (Ìhsàánù). Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpele wọ̀nyí ló sìní àwọn orìgun tirẹ̀.

المَرْتَبَةُ الأُولَى: الإِسْلَامُ
Ìpele Àkọ́kọ́: Ìjupá Jusẹ̀ Sílẹ̀ (Ìsìláámù)

فَأَرْكَانُ الإِسْلامِ خَمْسَةٌ: شَهَادَةُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللهِ، وَإِقَامُ الصلاة، وإِيتَاءُ الزَّكَاةِ، وَصَوْمُ رَمَضَانَ، وَحَجُّ بَيْتِ اللهِ الْحَرَامِ.

Àwọn orígun tó gbé Ìsìláámù dúró, marun péré ni: àkọ́kọ́ ni Ìjẹ́rí láti inú ọkàn pé kò sí ẹnìkan tó tọ́ sí ìjọsìn òdodo lẹ́yìn Ọlọ́hun (Allahu), àtipé Ànábì Muhammadu òjísẹ́ Ọlọ̀hun ni. Ìkejì ni Ìrun Kíkí. Ìkẹta ni Yíyọ Sàká Owó. Ìkẹrin ni Gbígba Ààwẹ̀ Rámáláánà. Ìkarùn ni Lílọ sí Ilé Ọlọ́hun fún ìjọsìn Hájjì.

فَدَلِيلُ الشَّهَادَةِ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿شَهِدَ اللَّهُ أَنَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ وَالْمَلَائِكَةُ وَأُولُو الْعِلْمِ قَائِمًا بِالْقِسْطِ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ﴾ [آل عمران: 18].
Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé Ìjẹ́rí láti inú ọkàn pé kò sí ẹnìkan tó tọ́ sí ìjọsìn òdodo lẹ́yìn Ọlọ́hun (Allahu) ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ọlọ́hun ń sé lófin wípé kòsí ẹlòmíràn tó tọ́sí ìjọsìn lẹ́yìn òhun Ọlọ́hun, àwọn Màláíkà àti àwọn olùmọ̀ tó dúró tọ́ náà sì ń jẹ́rí pé bẹ́ẹ̀ ni, kòsí ẹlòmíràn tó tọ́ sí ìjọsìn òdodo lẹ́yìn Ọlọ́hun ẹni tí títóbi rẹ̀ kò láfiwé, Ọba ọ̀jọ̀gbọ́n). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ àwọn aráálé Umuraana [Suratu Aali Umuraana], ẹsẹ 18).

وَمَعْنَاهَا: لَا مَعْبُودَ بِحَقٍّ إِلَّا اللهُ. وَحَدُّ النَّفْيِ مِنَ الإِثْبَاتِ "لَا إِلَهَ" نَافِيًا جَمِيعَ مَا يُعْبَدُ مِنْ دُونِ الله، "إِلَّا اللهُ" مُثْبِتًا الْعِبَادَةَ للهِ وَحْدَهُ لا شَرِيكَ لَهُ فِي عِبَادَتِهِ، كَمَا أَنَّهُ لَيْسَ لَهُ شَرِيكٌ فِي مُلْكِهِ.

Ìtumọ̀ ìjẹ́rí yí ni wípé kò sí ẹni tó tọ́ sí ìjọsìn òdodo yàtọ̀ sí Ọlọ́hun (Allahu). Ààlà kíkọ̀ àti àfirinlẹ̀ tó wà nínú gbólóhùn yí ni gbólóhùn “Laa ilaaha” tí ń dá lérí kíkọ̀ gbogbo ǹkan míràn tí wọ́n máá ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Ọlọ́hun, àti gbólóhùn “Illaa Allahu” tí ń dá lérí síse àfirinlẹ̀ ìjọsìn òdodo fún Ọlọ́hun ọ̀kan soso tí kò lórogún níbi àwọn isẹ́ ìjọsìn àti ọlá rẹ̀.

وَتَفْسِيرُهَا الَّذِي يُوَضِّحُهَا قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ إِنَّنِي بَرَاءٌ مِمَّا تَعْبُدُونَ ^ إِلَّا الَّذِي فَطَرَنِي فَإِنَّهُ سَيَهْدِينِ ^ وَجَعَلَهَا كَلِمَةً بَاقِيَةً فِي عَقِبِهِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ﴾ [الزخرف: 26-28]. وقَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ تَعَالَوْا إِلَى كَلِمَةٍ سَوَاءٍ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ أَلَّا نَعْبُدَ إِلَّا اللَّهَ وَلَا نُشْرِكَ بِهِ شَيْئًا وَلَا يَتَّخِذَ بَعْضُنَا بَعْضًا أَرْبَابًا مِنْ دُونِ اللَّهِ  فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقُولُوا اشْهَدُوا بِأَنَّا مُسْلِمُونَ﴾ [آل عمران: 64].

Àlàyé tó tún le tan ìmọ́lẹ̀ sí ìtumọ̀ gbólóhùn yí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun Ọba Àlekè Ọlá tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ sèrántí ìgbà tí Ànábì Ibrahimọ ńsọ fún bàbá àti àwọn ìjọ bàbá rẹ̀ wípé: dájúdájú èmí ń bọ́pá bọ́sẹ̀ kuro níbi gbogbo oun tí ẹ̀yin ń jọ́sìn fún ún ^ tó bá ti yàtọ̀ sí ohun tí Ọlọ̀hun asẹ̀dá mi pami lásẹ rẹ̀ (gẹ́gẹ́ bíi àwọn òrìsà tí ẹ̀yín ń sìn), torípé Òhun (Ọlọ́hun) nìkan ni ó lè tọ́mi sọ́nà íjọsìn ^ Ó tún wáá sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ de àrọmọdọ́mọ rẹ̀, kí àwọn ẹni anù inú wọn lè sẹ́rí padà soju ọ̀nà). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ọ̀sọ́ [Suratus Sukrufi], ẹsẹ 26-28). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun míràn tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (pe gbogbo àwọn tí Ọlọ́hun fún àwọn òjísẹ́ wọn ní ìwé òfin wípé: ẹ wáá gbọ́ ọ̀rọ̀ tóse déédé tí kò yàtọ̀ lọ́dọ apá kan wa sí òmíràn. Òun náà nipe a kò gbudọ̀ máa sin ǹkan míràn tó yàtọ̀ sí Ọlọ́hun (Allahu), a kò sì gbudọ̀ fi ǹkankan se orogún rẹ̀, àtipé apákan wa kò gbudọ̀ mú èkejì ní olùtẹ̀lé lẹ́yìn Ọlọ́hun. Tí wọ́n bá wáá sàìgbọràn, ẹ jẹ́ kí wọn ó mọ̀ wípé olújupá jusẹ̀ sílẹ̀ ni ẹ̀yin ń se). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ àwọn aráálé Umuraana [Suratu Aali Umuraana], ẹsẹ 64).

وَدِليلُ شَهَادَةِ أَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللهِ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿لَقَدْ جَاءَكُمْ رَسُولٌ مِنْ أَنْفُسِكُمْ عَزِيزٌ عَلَيْهِ مَا عَنِتُّمْ حَرِيصٌ عَلَيْكُمْ بِالْمُؤْمِنِينَ رَءُوفٌ رَحِيمٌ﴾ [التوبة: 128].

Ítọ́ka lórí wípé Ànábì Muhammadu òjísẹ́ Ọlọ́hun ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Pàá, òjísẹ́ kan láti inú yín ti dé wáá bayín, oun tí ó bá ń niyín lára jẹ́ n tí kò níí dùn mọ́ ọn, yóó sì maa àkólékàn àti ìbìkítà nípa ìmọ̀nà yín, yóò sì tún jẹ́ aláànú oníkẹ́ fún àwọn olùgbàgbọ́ òdodo). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ìtúúbá [Suratut Taobati], ẹsẹ 128).

وَمَعْنَى شَهَادَة أَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللهِ طَاعَتُهُ فِيمَا أَمَرَ، وَتَصْدِيقُهُ فِيمَا أَخْبَرَ، واجْتِنَابُ مَا نَهَى عَنْهُ وَزَجَرَ، وَأَلَّا يُعْبَدَ اللهُ إِلا بِمَا شَرَعَ.


Ìtumọ̀ ìjẹ́rí wípé Ànábì Muhammadu òjísẹ́ Ọlọ́hun ni: ìtẹ̀lé àsẹ rẹ̀, ìgbà oun tí ó bá múwá níró lódodo, àti ìjìnnà tefétefé sí oun tó bá kọ dínà sise rẹ̀, áígbudọ́ sin Ọlọ́hun àyàfi pẹ̀lú oun tó bá múwá lófin.

The timeless lessons from Abū Bakr’s companionship with the Prophet ﷺ during the migration to Madinah

  كِتَابُ فَضَائِلِ الصَّحَابَةِ مَنَاقِبُ أَبِي بَكْرٍ رَضِي عَنْهُ بَابُ قَوْلِهِ تَعَالَى: ﴿إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ ا...