Thursday, 14 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹsàn)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
وَدَلِيلُ الْخَشْيَةِ قَوْلُهُ تعالى: )فَلَا تَخْشَوْهُمْ وَاخْشَوْنِي( [البقرة: 150].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìbẹ̀rù tí yóò mú ìbàbàrà dání wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ má se bàbàrà wọn, Èmi ni kí ẹ máa bàbàrà) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Màálù [Suratul Bakarati], ẹsẹ 150).

وَدَلِيلُ الإِنَابَةِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَأَنِيبُوا إِلَى رَبِّكُمْ وَأَسْلِمُوا لَهُ( [الزمر: 54].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìsẹ́rí padà wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ sẹ́rí padà sọ́dọ̀ adẹ́dá yín, kí ẹ sì jọ̀wọ́ ara yín fún Un) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Ìjọ Àlùjánnà àti Ina [Suratuz Zumar], ẹsẹ 54).

وَدَلِيلُ الاسْتِعَانَةِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِيَّاكَ نَعْبُدُ وَإِيَّاكَ نَسْتَعِينُ( [الفاتحة: 5]. وفي الحديث: «إذا اسْتَعَنْتَ فَاسْتَعِنْ بِاللهِ».

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé títọrọ ìrànwọ́ wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ìwọ Ọlọ́hun nìkan ni aó máa sìn, Ìrẹ nìkan sì ni aó máa wá ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ìsí Àlùkúráánì [Suratul Faatihati], ẹsẹ 5). Ó tún wà nínú ọ̀rọ̀ ànábì (Hadiisi) wípé: »Tí o bá fẹ́ẹ́ wá ìrànwọ́, ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun nìkan ni kóo ti wáa«.

وَدَلِيلُ الاسْتِعَاذَةِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )قُلْ أَعُوذُ بِرَبِّ النَّاسِ ۞ مَلِكِ النَّاسِ( [الناس: 1 -2].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé títọrọ ìsọra wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ìrẹ ànábì, sọpé mofi Ọlọ́hun Adẹ́dá gbogbo ọmọnìyàn wá ìsọ́ ۞ Ọba tó kápá gbogbo ọmọnìyàn). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ọmọnìyàn [Suratun Naasi], ẹsẹ 1-2).

وَدَلِيلُ الاسْتِغَاثَةِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِذْ تَسْتَغِيثُونَ رَبَّكُمْ فَاسْتَجَابَ لَكُمْ( [الأنفال: 9].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé títọrọ ọ̀nà àbayọ wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹrántí ìgbà tí ẹ̀ń tọrọ ọ̀nà àbayọ lọ́dọ̀ Ọlọ́hun Asẹ̀dá yín, tósì dayín lóhùn ìbèèrè yín). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Èrè Ogun [Suratul Anfaali], ẹsẹ 9).

ودليل الذبح قوله تعالى: )قُلْ إِنَّ صَلَاتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ لَا شَرِيكَ لَهُ وَبِذَلِكَ أُمِرْتُ وَأَنَا أَوَّلُ الْمُسْلِمِينَ( [الأنعام: 162 -163]. وَمِنَ السُنَّةِ: «لعَنَ اللهُ مَنْ ذَبَحَ لِغَيْرِ اللهِ».

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìdúńbú wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Máa sọ wípé dájúdájú ìjọsìn ìrun kíkí tí mò ń se àti ìgunran mi, ààyè mi àti ikú mi pẹ̀lú, ti Ọlọ́hun Ọba tí kò lórogún Asẹ̀dá gbogbo àgbáńlá ayé nìkan soso ni, àtipé eléyí ni Ọlọ́hun pamí lásẹ rẹ̀. Èmi sì jẹ́ àkọ́kọ́ àwọn olùgbà fỌ́lọ́hun lórí àwọn àsẹ rẹ̀). (Ọgbà Àwọn Ẹran [Suratul Anaai], ẹsẹ 162-163). Ó tún wà nínú ọ̀rọ̀ ànábì (Hadiisi) wípé: »Ọlọhun sẹ́bi lé ẹni tóbá dúran fún ǹkan míràn lẹ́yìn Ọlọ́hun«.  

وَدَلِيلُ النَّذْرِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )يُوفُونَ بِالنَّذْرِ وَيَخَافُونَ يَوْمًا كَانَ شَرُّهُ مُسْتَطِيرًا( [الإنسان: 7].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìjẹ́jẹ́ wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Àwọn ẹrú Ọlọ́hun tí igbadun yí yóò máa jẹ́ tiwọn ni àwọn tí wọ́n má ńmú ẹ̀jẹ́ wọn sẹ, tí wọ́n sì tuń máa ńbẹ̀rù ọjọ́ tí wàhálà àti ìfòòró rẹ̀ kò níí fẹ́ẹ̀ dá ẹnìkansí). (Ọgbà Ìran Ọmọnìyàn [Suratul Insaani], ẹsẹ 7).

Sunday, 10 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹjọ)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَقَالَ رَبُّكُمُ ادْعُونِي أَسْتَجِبْ لَكُمْ إِنَّ الَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِي سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ( [غافر: 60]، وَفِي الْحَدِيثِ «الدُّعَاءُ مخ الْعِبَادَةِ».

ÌTUMỌ̀
Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìdírẹ́bẹ Ọlọ́hun (Adua) síse wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ọlọ́hun asẹ̀dá yín tún ń sọ̀pé: “Ẹ pèmí, wun ó sì jẹyín. Dájúdájú gbogbo àwọn tí wọ́n bá ńse yànǹga pẹ̀lu sísìn mí yóò wọ ọ̀gbun iná (jahannama) niti ìyẹpẹrẹ). (Ọgbà ọ̀rọ̀ aláforíjìn [Suratul Gaafiri], ẹsẹ 60). Ó tún wà nínú ọ̀rọ̀ ànábì (Hadiisi) wípé: »ìdírẹ́bẹ Ọlọ́hun (Àdúà) ni ọkàn ìjọsìn«.

وَدَلِيلُ الْخَوْفِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )فَلَا تَخَافُوهُمْ وَخَافُونِ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ( [آل عمران: 175].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìpayà wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ má se kó ìpayà àwọn èsù èèyàn yí sọ́kàn, èmi ni kí ẹ máa bẹ̀rù tóbá jẹ́pé onígbàgbọ́ tòótọ́ niyín} (Ọgbà Ọ̀rọ̀ àwọn aráálé Umuraana [Suratu Aali Umuraana], ẹsẹ 175).

ودليل الرجاء قوله تعالى: )فَمَنْ كَانَ يَرْجُوا لِقَاءَ رَبِّهِ فَلْيَعْمَلْ عَمَلًا صَالِحًا وَلَا يُشْرِكْ بِعِبَادَةِ رَبِّهِ أَحَدًا( [الكهف: 110].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìrankàn wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹnikẹ́ni tó bá ńrankàn ẹ̀san rere nígbà tóbá pàdé Ọlọ́hun rẹ̀, kó yáa mú isẹ́ẹre se, kósì má se mú ẹníkẹ́ni lórogún pẹ̀lú adẹ́dá rẹ̀ níbi isẹ́ ìjọsìn rẹ̀). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ihò Àpata [Sursatul Kahfi], ẹsẹ 110).

ودَلِيلُ التَّوَكُلِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَعَلَى اللَّهِ فَتَوَكَّلُوا إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ( [المائدة: 23]. وقوله تعالى: )وَمَنْ يَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ فَهُوَ حَسْبُهُ( [الطلاق: 3].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìgbẹ́kẹ̀le wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ọlọ́hun nìkan ni kẹ́ẹ gbáralé tóbá jẹ́ onígbàgbọ́ tòótọ́ niyín}. (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Tábìlì Oúnjẹ [Suratul Maaidati], ẹsẹ 23). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹni tóbá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́hun (Allahu), òhun (Allahu) yóó sì to ẹni náà). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ìkọ̀sílẹ̀ [Suratut Tọlaaki], ẹsẹ 23).

وَدَلِيلُ الرَّغْبَةِ وَالرَّهْبَةِ وَالْخُشُوعِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّهُمْ كَانُوا يُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَيَدْعُونَنَا رَغَبًا وَرَهَبًا وَكَانُوا لَنَا خَاشِعِينَ( [الأنبياء: 90].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìfẹ́ láti súnmọ́, ìbẹ̀rù ẹ̀sẹ̀, àti ìbọ̀wọ̀ wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Dájúdájú àwọn ẹni Ọlọ́hun tí A kà síwájú yìí máa ń yára salápáǹtètè lọ sibi àwọn isẹ́ rere, wọ́n sì máá ń pèWá pẹ̀lú ìrankàn sísúnmọ́ Wa àti ìsáfún sísẹ̀ Wá, Àwa Ọlọ́hun (Allahu) nìkan ni wọń sì máá ń bọ̀wọ̀ fún). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Ànábì Ọlọ́hun [Suratul Anbiyaai], ẹsẹ 90).

Saturday, 9 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Keje)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
وَأَنْوَاعُ الْعِبَادَةِ الَّتِي أَمَرَ اللهُ بِهَا مِثْلُ الإِسْلامِ وَالإِيمَانِ، وَالإِحْسَانِ، وَمِنْهُ الدُّعَاءُ وَالْخَوْفُ وَالرَّجَاءُ وَالتَّوَكُّلُ وَالرَّغْبَةُ، وَالرَّهْبَةُ، وَالْخُشُوعُ، وَالْخَشْيَةُ، وَالإِنَابَةُ، وَالاسْتِعَانَةُ، والاستعاذة، والاستغاثة، والذبح، والنذر، وغير ذلك من الْعِبَادَةِ الَّتِي أَمَرَ اللهُ بِهَا (كُلُّهَا للهِ)، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَأَنَّ الْمَسَاجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدْعُوا مَعَ اللَّهِ أَحَدًا( [الجن: 18].
ÌTUMỌ̀
Àwọn oníran jìran isẹ́ ìjọsìn tí Ọlọ́hun (Allahu) pa lásẹ ni àwọn bíi: ìjupá jusẹ̀ sílẹ̀ fỌ́lọ́hun (Isilamu), ìgbágbọ́ (Iimaani), àti ísedáadá. Nínú wọn tún ni ìdírẹ́bẹ Ọlọ́hun (Adua), ìpayà, ìrankàn, ìgbẹ́kẹ̀le, ìgbiyèlé, ìfẹ́ láti sìn Ín, ìbẹ̀rù ẹ̀sẹ̀, ìbọ̀wọ̀, ìbẹ̀rù tí yóò mú ìbàbàrà dani, ìsẹ́rí padà, wíwá ìrànwọ́, wíwá ìsọra, wíwá àbayọ, ìdúńbú, ìjẹ́jẹ́, àti àwọn oníran ǹran isẹ́ ìjọsìn míràn tí Ọlọ́hun pàsẹ wọn. Gbogbo àwọn isẹ́ ìjọsìn wọ̀nyí pátá gbudọ̀ jẹ́ tỌlọ́hun nìkan soso, ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Pàá, ti Ọlọ́hun nìkan soso ni gbogbo ààyè ìsìn àti ibù fisìn, nítorí ẹ̀, ẹ má se tún máa sin ẹnìkẹni míràn ní àwọn ààyè náà tàbí fi àwọn ibùsìn náà sin ẹlòmíràn lẹ́yìn Ọlọ́hun) (Ọgbà ọ̀rọ̀ àwọn àlùjànnú [Suratul Jinn], Ẹsẹ 18).

فَمَنْ صَرَفَ مِنْهَا شَيْئًا لِغَيْرِ اللهِ فَهُوَ مُشْرِكٌ كَافِرٌ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَمَنْ يَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَهًا آخَرَ لَا بُرْهَانَ لَهُ بِهِ فَإِنَّمَا حِسَابُهُ عِنْدَ رَبِّهِ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الْكَافِرُونَ( [المؤمنون: 117].

Nítorínáà, ẹnikẹ́ni tóbá sẹ́rí ọ̀kan nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn wọ̀nyí sọ́dọ̀ ǹkan míràn tó yàtọ̀ sí Ọlọ́hun, ọ̀sẹ̀bọ afigbá dóore Ọlọ́hun mọ́lẹ̀ (Kèfèrí) ni. Ẹ̀rí èyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí: (Ẹnikẹ́ni tóbá pe ǹkan míràn tí kò sẹ́rí ìjọsìn tó dájú fún pẹ̀lú Ọlọ́hun, oun tí yóò jẹ́ ẹ̀san rẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́hun rẹ̀ yóò lágbára, dájúdájú kèfèrí kò níí là lọ́jọ́ àgbéǹde àlùkìyáámọ̀) (Ọgbà ọ̀rọ̀ àwọn olùgbàgbọ́ [Suratul Muuminuuna], ẹsẹ 117).

Monday, 4 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹfà)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá

فَإِذَا قِيلَ لَكَ: مَا الأُصُولُ الثَّلاثَةُ التِي يَجِبُ عَلَى الإِنْسَانِ مَعْرِفَتُهَا؟
فَقُلْ: مَعْرِفَةُ الْعَبْدِ رَبَّهُ، وَدِينَهُ وَنَبِيَّهُ مُحَمَّدًا  صلى الله عليه وسلم.
ÌTUMỌ̀
Tí wọ́n bá bi ọ́ léèrè wípé àwọn ìpìlẹ̀ mẹ́ta wo lódi ọ̀ranyàn kí gbogbo ọmọnìyàn mọ̀ nípa wọn?
Fún wọn lésì wípé àwọn ni: ìmọ̀ ẹrú nípa olùtọ́jú rẹ̀ tíí se Ọlọ́hun, ẹ̀sìn rẹ̀, àti òjísẹ́ tí wọ́n rán síi tíí se Muhammadu –kí àlékún íkẹ́ àti ìgẹ̀ Ọlọ́hun máa báa.

فَإِذَا قِيلَ لَكَ: مَنْ رَبُّكَ؟
فَقُلْ: رَبِّيَ اللهُ الَّذِي رَبَّانِي وَرَبَّى جَمِيعَ الْعَالَمِينَ بِنِعَمِهِ، وَهُوَ مَعْبُودِي لَيْسَ لِي مَعْبُودٌ سِوَاهُ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ( [الفاتحة: 2]. وَكُلُّ مَا سِوَى اللهِ عَالَمٌ وَأَنَا وَاحِدٌ مِنْ ذَلِكَ الْعَالَمِ.

ÌTUMỌ̀
Tí wọ́n bá wáá bi ọ́ léèrè pé taani olùtọ́jú rẹ?
Dá wọn lóhùn wípé: Ọlọ́hun (Allahu) ni olùtọ́jú mi, òun náà ni  olùtọ́jú gbogbo àgbááyé tí ń bẹ pẹ̀lú orísírísí ìdẹ̀ra Rẹ̀. Òhun náà sì ni ẹni tó lẹ́tọ̀ sí ìjọsìn tèmi tí kò sí ẹlòmíràn tó tún lẹ́tọ̀ síi. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́hun, Ọba Olùtọ́jú gbogbo àgbáńlá ayé) (Ọgbà ọ̀rọ̀ ìsí Alukurani [Suratu Al Faatiha], ẹsẹ 2). Eléyí ń túmọ̀ sí wípé gbogbo oun tó bá ti yàtọ̀ sí Ọlọ́hun ni àgbááye, ọ̀kan sì ni èmi náà nínú àgbááyé náà.

فَإِذَا قِيلَ لَكَ: بِمَ عَرَفْتَ رَبَّكَ؟
فَقُلْ: بِآيَاتِهِ وَمَخْلُوقَاتِهِ وَمِنْ آيَاتِهِ اللَّيْلُ وَالنَّهَارُ وَالشَّمْسُ وَالْقَمَرُ وَمِنْ مَخْلُوقَاتِهِ السَّمَاوَاتُ السَّبْعُ وَالأَرَضُونَ السَّبْعُ وَمَنْ فِيهِنَّ وَمَا بَيْنَهُمَا، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَمِنْ آيَاتِهِ اللَّيْلُ وَالنَّهَارُ وَالشَّمْسُ وَالْقَمَرُ لَا تَسْجُدُوا لِلشَّمْسِ وَلَا لِلْقَمَرِ وَاسْجُدُوا لِلَّهِ الَّذِي خَلَقَهُنَّ إِنْ كُنْتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ( [فصلت: 37]، وقوله تعالى: )إِنَّ رَبَّكُمُ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَى عَلَى الْعَرْشِ يُغْشِي اللَّيْلَ النَّهَارَ يَطْلُبُهُ حَثِيثًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ وَالنُّجُومَ مُسَخَّرَاتٍ بِأَمْرِهِ أَلَا لَهُ الْخَلْقُ وَالْأَمْرُ تَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ( [الأعراف: 54].

ÌTUMỌ̀
Tí wọ́n bá tún wáá bi ọ́ pé kíni o fi dá Ọlọ́hun rẹ mọ̀?
Sọ fún wọn wípé: pẹ̀lú àwọn isẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ẹ̀dá àràmọ̀ǹdà tódá ni mo fi mọ̀ Ọ́n. Nínú àwọn oun ámì ìyanu rẹ̀ ni: òru, ọ̀sán, òòrùn, àti òsùpá. Nínú àwọn ẹ̀dá àràmọ̀ǹdà tódá sì ni: àwọn sánmọ̀ méjèèje àti àwọn ilẹ̀ méjèèje pẹ̀lú gbogbo oun tí ńbẹ nínú àti láàrin wọn. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Àtipé nínú àwọn oun isẹ́ ìyanu Rẹ̀ (Ọlọ́hun) ni òru àti ọ̀sán pẹ̀lú òòrùn àti òsùpá. Nítorínáà, ẹ má se máa júbà fún òòrùn àti òsùpá, Ọlọ́hun (Allahu) tó sẹ̀dá wọn ni kẹ́ẹ máa júbà fún tóbá jẹ́pé òun ni ẹ̀ ń sìn lódodo) (Ọgbà ọ̀rọ̀ ìfọ́síwẹ́wẹ́ [Suratu Fussilat], ẹsẹ 37). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Dájúdájú olùtọ́jú yín ni Ọlọ́hun tó sẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ní àlàfo ọjọ́ mẹ́fà, lẹ́yìn náà ni ó wáá gúnwà sórí ìtẹ́-ọlá (Araṣi) Rẹ̀, Ó sì ńfi ọ̀sán àti òru bo ara wọn, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ń yára gbasẹ́ lọ́wọ́ ara wọn. Òhun (Ọlọ́hun) náà ni ó tún sẹ̀dá òòrùn àti òsùpá àti àwọn íráwọ̀ tó fi àsẹ Rẹ́ tẹ̀wọ́n lórí ba. Ẹtẹ́tí gbọ́, tỌlọ́hun (Allahu) ni ìsẹ̀dá àti àsẹ, mímọ́ Ọlọ́hun tí ń tọ́jú gbogbo àgbáńlá ayé) (Ọgbà ọ̀rọ̀ àwọn alágbede méjì [Suratul Aaraafi], ẹsẹ 54).

وَالرَّبُ هُوَ الْمَعْبُودُ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )يَا أَيُّهَا النَّاسُ اعْبُدُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ ^ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ فِرَاشًا وَالسَّمَاءَ بِنَاءً وَأَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجَ بِهِ مِنَ الثَّمَرَاتِ رِزْقًا لَكُمْ فَلَا تَجْعَلُوا لِلَّهِ أَنْدَادًا وَأَنْتُمْ تَعْلَمُونَ( [البقرة: 21 - 22]. قَالَ ابْنُ كَثِيرٍ رَحِمَهُ اللهُ تَعَالَى: الخَالِقُ لهذه الأشياء هو المستحق للعبادة.

ÌTUMỌ̀

Ọlọ́hun Adẹ́dá yìí nàà ni Ó tọ́sí ìjọsìn òdodo, Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ̀yin ọmọnìyàn, ẹ máa jọ́sìn fún Ọlọ́hun tó sẹ̀dá yín àti gbogbo àwọn tó siwájú yín bóyá ẹ́ẹ́le bẹ̀rù Ọlọ́hun ۞ Ọba tó tẹ́ ilẹ̀ funyín ní pẹrẹsẹ, tófi sánmọ̀ sààbò leyín lórí, Ó tún wá ń rọ òjò kalẹ̀ láti sánmọ̀ náà, èyí tí ń sokùnfà kí orísìrísì èso jade kóle máa jẹ́ ìpèsè jíjẹ àti mímu fúnyín. Torínáà, ẹ má se mórogún mọ́ Ọlọ̀hun tí ẹ̀yin náà sì mọ̀ pé kò lórogún). Olùmọ̀ àgbà Ibn Kaseer sọpé: “Èyí ń túmọ̀ sí wípé: ẹni tó sẹ̀dá gbogbo ǹkan wọ̀nyí nìkan ni Ó lẹ́tọ́ sí ìjọsìn”. 

Saturday, 2 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kàrún)


Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá

اعْلَمْ -أَرْشَدَكَ اللهُ لِطَاعَتِهِ- أَنَّ الْحَنِيفِيَّةَ مِلَّةَ إِبْرَاهِيمَ: أَنْ تَعْبُدَ اللهَ وَحْدَهُ مُخْلِصًا لَهُ الدِّينَ. وَبِذَلِكَ أَمَرَ اللهُ جَمِيعَ النَّاسِ، وَخَلَقَهُمْ لَهَا؛ كَمَا قَالَ اللهُ تَعَالَى: )وَمَا خَلَقْتُ الْجِنَّ وَالْإِنْسَ إِلَّا لِيَعْبُدُونِ( [الذاريات: 56]. وَمَعْنَى يَعْبُدُونِ: يُوَحِّدُونِ.

ÌTUMỌ̀
Lọrèémọ̀ -Ọlọ́hun (Allahu) yóò tọ́ írẹ sọ́nà ìtẹ̀lé àsẹ rẹ̀- wípé dájúdájú ìláná tótọ́ tíí se ìlànà ànábì Ibrahimu ni kí o máa sin Ọlọ́hun (Allahu) níkan soso lẹ́ni tí yóo máa sàfọ̀mọ́ ìjọsìn Fún un. Eléyẹn síni Ọlọ́hun pa lásẹ fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn, tó sì torí rẹ̀ dáwọn, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́hun tóga jùlọ tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Èmi [Ọlọ́hun] kó sẹ̀dá àlùjànnú àtí ọmọnìyàn lásán bí kòse kí wọ́n le máa fi ìjọsìn fún èmi nìkan soo) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Afẹ́rẹ́ [Suratu Al Daariyaati], ẹsẹ 56). Ìtumọ̀ gbólóhùn “Yaabuduuni” tówà níparì ẹsẹ ọ̀rọ̀ náà ń túmọ̀ sí ‘mímú mi láàso níbi ìjọsìn’.

وَأَعْظَمُ مَا أَمَرَ اللهُ بِهِ التَّوْحيِدُ، وَهُوَ إِفْرَادُ اللهِ بِالْعِبَادَةِ.
وَأَعْظَمُ مَا نَهَى عَنْه الشِّركُ وَهُوَ دَعْوَةُ غَيْرِهِ مَعَهُ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَاعْبُدُوا اللَّهَ وَلَا تُشْرِكُوا بِهِ شَيْئًا( [النساء: 36].

ÌTUMỌ̀
Oun tó fi ń ga júlọ nínú àsẹ Ọlọ́hun (Allahu) ni ìmu lọ́kan soso (At taohiidu) tíí se ìmú Ọlọ́hun láàso níbi ìjọsìn.

Bẹ́ẹ̀ni éyí toga jùlọ nínú másèé (Èèwọ̀) Ọlọ́hun ni ímú orogún mọ́ Ọn, tíí se ìmaa tún pe ǹkan míràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ máa sin Ọlọ́hun láìgbọdọ̀ mú ǹkankan lórogún pẹ̀lu rẹ̀) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìrin [Suratu An Nisaai], Ẹsẹ 36).

Wednesday, 30 August 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹrin)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
الثَّانِيَةُ: أَنَّ الله لا يَرْضَى أَنْ يُشْرَكَ معه أحدً في عبادته، لا مَلَكٌ مُقَرَّبٌ، وَلا نَبِيٌّ مُرْسَلٌ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿وَأَنَّ الْمَسَاجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدْعُوا مَعَ اللَّهِ أَحَدًا [الجن: 18].

ÌTUMỌ̀
Ẹ̀kejì: òun ni wípé dájúdájú Ọlọ́hun (Allahu) kò níí yọ́nú sí ìmú ẹnikẹ́ni ní orogún pẹ̀lú rẹ̀ níbi isẹ́ ìjọsìn Fún un, kì bá ǹ jẹ́ màláíká tó sùnmọ́ Ọn, tàbí ọ̀kan nínú àwọn ànábì tó fi isẹ́ rán. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Dájúdájú, ti Ọlọ́hun nìkan soso ni gbogbo ààyè ìsìn àti ibù fisìn, nítorí náà, ẹ má se tún máa sin ẹnìkẹni míràn ní àwọn ààyè náà tàbí fi àwọn ibùsìn náà sin ẹlòmíràn lẹ́yìn Ọlọ́hun) (Ọgbà ọ̀rọ̀ àlùjànnú [Suratul Jinni], Ẹsẹ 18).


الثَّالِثَةُ: أَنَّ مَنْ أَطَاعَ الرَّسُولَ وَوَحَّدَ اللهَ، لا يجوز له موالاة من حادَّ الله وَرَسُولَهُ، وَلَوْ كَانَ أَقْرَبَ قَرِيبٍ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تعالى: ﴿لَا تَجِدُ قَوْمًا يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ يُوَادُّونَ مَنْ حَادَّ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَوْ كَانُوا آبَاءَهُمْ أَوْ أَبْنَاءَهُمْ أَوْ إِخْوَانَهُمْ أَوْ عَشِيرَتَهُمْ أُولَئِكَ كَتَبَ فِي قُلُوبِهِمُ الْإِيمَانَ وَأَيَّدَهُمْ بِرُوحٍ مِنْهُ وَيُدْخِلُهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ أُولَئِكَ حِزْبُ اللَّهِ أَلَا إِنَّ حِزْبَ اللَّهِ هُمُ الْمُفْلِحُونَ [المجادلة: 22].

ÌTUMỌ̀
Ẹ̀kẹta: nipé ẹni tó bá ń tẹ̀le òjísẹ́ Ọlọ́hun (Allahu) lódodo, tó sì gbà Ọlọ́hun lọ́kan soso, kò tọ́ fún un láti mú olùkọ tọlọ́hun àti òjísẹ́ rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ ààyò. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Oò le rí ọ̀kankan nínú àwọn èèyàn tó ní ígbàgbọ́ òdodo sí Ọlọ́hun àti ọjọ́ ìkẹhìn tí yóò maa sọ̀rẹ́ ààyò pẹ̀lú àwọn ọ̀tá Ọlọ́hun àti òjísẹ rẹ̀, kódà kí wọ́n jẹ́ bàbá, tàbí ọmọ, tábí ọmọ ìyá, tàbí mọ̀lẹ́bí fún wọn. Irú àwọn wọ̀nnì ni Ọlọ́hun se àfirinlẹ̀ ìgbàgbọ̀ sínú ọkàn wọn tí Ó tún se ìkúnwọ fún wọn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí yóò sì tún fiwọ́n wọ ọgbà ìdẹ̀ra (Àlùjánnà) tí àwọn akérémọdò ń sàn lábẹ́ rẹ́ lẹ́ni tí yóò se gbére nínú rẹ́, látààrí pé Ọlọ́hun (Allahu) yọ́nú síwọn, àwọn náà sì yọ́nú sí I (Allahu). Àwọn wọ̀nnì ni a le pè ní ọmọ ogun Ọlọ́hun (Allahu), Ẹ tẹ́tí gbọ́, àwọn ọmọ ogun Ọlọ́hun (Allahu) ni ẹni ọlà) (Ọgbá ọ̀rọ̀ irin [Suratul Hadiid], Ẹsẹ 22).

Monday, 28 August 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹta)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá

اعْلَمْ -رَحِمَكَ اللهُ- أَنَّه يَجِبُ عَلَى كُلِّ مُسْلِمٍ وَمُسْلِمَةٍ تَعَلُّمُ هَذِهِ الثَّلاثِ مَسَائِل والْعَمَلُ بِهِنَّ:
الأُولَى: أَنَّ اللهَ خَلَقَنَا وَرَزَقَنَا وَلَمْ يَتْرُكْنَا هَمَلا، بَلْ أَرْسَلَ إِلَيْنَا رَسُولاً، فَمَنْ أَطَاعَهُ دَخَلَ الجَنَّةَ، وَمَنْ عَصَاهُ دَخَلَ النَّارَ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿إِنَّا أَرْسَلْنَا إِلَيْكُمْ رَسُولًا شَاهِدًا عَلَيْكُمْ كَمَا أَرْسَلْنَا إِلَى فِرْعَوْنَ رَسُولًا فَعَصَى فِرْعَوْنُ الرَّسُولَ فَأَخَذْنَاهُ أَخْذًا وَبِيلًا [المزمل: 15 - 16].


ÌTUMỌ̀
Lọrèémọ̀ -Ọlọ́hun (Allahu) yóò kẹ́ ọ- wípé ó tún di ọ̀ranyàn lé gbogbo mùsùlùmí lọ́kùnrin lóbìnrin lórí ì mọ̀ nípa àwọn àláámọ̀rí mẹ́ta tó ń bọ̀yí pẹ̀lú sí sisẹ́ tọ̀wọ́n:

Ákọ́kọ́: ni wípé Ọlọ́hun (Allahu) ni ó sẹ̀dá wa, òun náà sì ni ó ń se íjẹ ìmu (Arísìkí) fún wa, kò tún wáá fiwá kalẹ̀ lásán, ó tún rán òjísẹ́ kan síwa, ẹnikéni tó bá tẹ̀le ìlànà rẹ̀ ti fi ọgbà ìdẹ̀ra (Àlùjánnà) se ìfà jẹ, ẹnikéni tó bá sì yapa ilànà rẹ̀ ti lùgbàdì iná. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Pàá a ti rán an sí yín òjísẹ́ kan tí yóò máa jẹ́ ẹlẹ́rì leyín lórí gẹ́gẹ́ bí a ti se rán òjísẹ́ sí Fíríáónà sùgbọ́n tí ó kọ etí ikún sí òjísẹ́ wa, a wáá torí rẹ̀ fi ọwọ́ agbára apanirun múu). (Suratu Musamilu, 15-16).

Tuesday, 22 August 2017

Ìtumọ̀ Tírà Usulu Salasa (Ìpìlẹ̀ Èsìn Mẹ́ta tò se pàtàkì) (Ẹ̀kọ́ Kejì)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
قَالَ الشَّافِعِيُّ -رَحِمَهُ اللهُ تَعَالَى-: "لَوْ مَا أَنْزَلَ اللهُ حُجَّةً عَلَى خَلْقِهِ إِلَّا َهذِهِ السُّورَةَ لَكَفَتْهُم.
وَقَالَ البُخَارِيُّ -رَحِمَهُ اللهُ-: بَابٌ: الْعِلْمُ قَبْلَ القَوْلِ وَالْعَمَلِ.
وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿فَاعْلَمْ أَنَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ وَاسْتَغْفِرْ لِذَنْبِكَ وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَات وَاللَّهُ يَعْلَمُ مُتَقَلَّبَكُمْ وَمَثْوَاكُمْ﴾ [محمد: 19]. فَبَدَأَ بِالْعِلَمِ قَبْلَ الْقَوْلِ وَالْعَمَلِ.
ÌTUMỌ̀
Olùmọ̀ Àgbà, Asíwájú Ṣafiiyu –kí Ọlọ́hun lékún ìkẹ́ wọn- sọpé: “tí Ọlọ́hun Ọba (Allahu) kò bá sọ ọgbà ọ̀rọ̀ (Suuratu) míràn kalẹ̀ fún àwọn ẹ́dá rẹ̀ lòrí àwọn ìpìlẹ̀ mẹ́ẹ́rẹ̀rin yìí tó kọjá eléyìí, ó ti tó fún wọn”.


Olùmọ̀ Àgbà, Asíwájú Buhariyyu - kí Ọlọ́hun lékún ìkẹ́ wọn- náà tún fi se àkọlé ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Aayatu) tó ń bọ̀ yìí, ọ́rọ̀ rẹ̀ tó sọ pé: “ákórí ẹsẹ ọ̀rọ̀ (Aayatu) tó ń bọ̀ yí ni wípé: ìmọ̀ gbudọ̀ síwájú èyíkéyí ọ̀rọ̀ àti ìse”. Ẹ̀rí eléyí sì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Kọ́kọ́ lọrèémọ̀ wípé kò sí ẹnikẹ́ni tó lẹ́tọ́ sí ìjọsìn òdodo yàtọ̀ sí Ọlọ́hun (Allahu), lẹ́yìn náà kí o máa wá àforíjìn ẹ̀sẹ̀ fún ara rẹ àti fún gbogbo ódodo lọ́kùnrin àti lóbìnrin). Èyí nipé, Ọlọ́hun (Allahu) fi ìmọ̀ siwájú ọ̀rọ̀ àti íse.

Friday, 18 August 2017

Ìtumọ̀ Tírà Usulu Salasa (Ìpìlẹ̀ Èsìn Mẹ́ta tò se pàtàkì) (Ẹ̀kọ́ Kínní)


Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
اعْلَمْ -رَحِمَكَ اللهُ- أَنَّهُ يَجِبُ عَلَيْنَا تَعَلُّمُ أَرْبَعِ مَسَائِلَ:
الأُولى: العِلْمُ- وَهُوَ مَعْرِفَةُ اللهِ، وَمَعْرِفَةُ نَبِيِّهِ، وَمَعْرِفَةُ دِينِ الإِسْلَامِ بِالأَدِلَّةِ.
الثانية: العَمَلُ بِهِ.
الثالثة: الدَّعْوَةُ إِلَيْهِ.
الرابعة: الصَّبْرُ عَلَى الأَذَى فِيهِ.
وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَالْعَصْرِ ۞ إِنَّ الْإِنْسَانَ لَفِي خُسْرٍ ۞ إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَتَوَاصَوْا بِالْحَقِّ وَتَوَاصَوْا بِالصَّبْرِ(

ÌTUMỌ̀
Lọrèémọ̀ -Ọlọ́hun (Allahu) yóò kẹ́ ọ- wípé ó di ọ̀ranyàn lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lórí ì wámọ̀ nìpa àwọn àláámọ̀rí mẹ́ẹ́rin kan:
Alákọ̀kọ́: Ìmọ̀ – òun náà ni níní ìmọ̀ tó jindò nípa Ọlọ́hun (Allahu), òjísẹ́ rẹ̀, àti ẹ̀sìn Isilaamu pẹ̀lú ìtọ́ka.
Ẹlẹ́ẹ̀kejì: ì fi sisẹ́ se.
Ẹlẹ́ẹ̀kẹta: ì pèpè lọ síbẹ̀.
Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin: àmúmọ́ra lóri gbogbo ẹ̀gin tó lè jẹyọ lórí ípèpè síbẹ̀.

Ẹ̀rí mọ́ọ jẹ́mi ǹsó lórí àwọn nkan wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ̀hun (Allahu) tí ìtumọ́ rẹ̀ lọ báyí wípé:
(Mo fi ìgbà ìrọ̀lẹ́ ayé búra ^ dájúdájú ìran ọmọnìyàn yóò máa yí nínú òfò ní àsìkò náà ^ àyàfi àwọn tó bání ìgbàgbọ́ àní dọ́kàn tí wọ́n sì se àwọn isẹ́ rere tí wọ́n tún wá ń pèpè lọ síbi òdodo àti àtẹ̀mọra)  




The timeless lessons from Abū Bakr’s companionship with the Prophet ﷺ during the migration to Madinah

  كِتَابُ فَضَائِلِ الصَّحَابَةِ مَنَاقِبُ أَبِي بَكْرٍ رَضِي عَنْهُ بَابُ قَوْلِهِ تَعَالَى: ﴿إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ ا...