Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
وَأَنْوَاعُ الْعِبَادَةِ الَّتِي أَمَرَ
اللهُ بِهَا مِثْلُ الإِسْلامِ وَالإِيمَانِ،
وَالإِحْسَانِ، وَمِنْهُ الدُّعَاءُ وَالْخَوْفُ وَالرَّجَاءُ وَالتَّوَكُّلُ
وَالرَّغْبَةُ، وَالرَّهْبَةُ، وَالْخُشُوعُ، وَالْخَشْيَةُ، وَالإِنَابَةُ،
وَالاسْتِعَانَةُ، والاستعاذة، والاستغاثة، والذبح، والنذر، وغير ذلك من
الْعِبَادَةِ الَّتِي أَمَرَ اللهُ بِهَا (كُلُّهَا للهِ)، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ
تَعَالَى: )وَأَنَّ الْمَسَاجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدْعُوا مَعَ اللَّهِ أَحَدًا( [الجن: 18].
ÌTUMỌ̀
Àwọn oníran jìran isẹ́ ìjọsìn tí Ọlọ́hun (Allahu) pa lásẹ
ni àwọn bíi: ìjupá jusẹ̀ sílẹ̀ fỌ́lọ́hun (Isilamu), ìgbágbọ́ (Iimaani), àti
ísedáadá. Nínú wọn tún ni ìdírẹ́bẹ Ọlọ́hun (Adua), ìpayà, ìrankàn, ìgbẹ́kẹ̀le,
ìgbiyèlé, ìfẹ́ láti sìn Ín, ìbẹ̀rù ẹ̀sẹ̀, ìbọ̀wọ̀, ìbẹ̀rù tí yóò mú ìbàbàrà
dani, ìsẹ́rí padà, wíwá ìrànwọ́, wíwá ìsọra, wíwá àbayọ, ìdúńbú, ìjẹ́jẹ́, àti
àwọn oníran ǹran isẹ́ ìjọsìn míràn tí Ọlọ́hun pàsẹ wọn. Gbogbo àwọn isẹ́ ìjọsìn
wọ̀nyí pátá gbudọ̀ jẹ́ tỌlọ́hun nìkan soso, ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Pàá, ti Ọlọ́hun nìkan soso ni gbogbo ààyè ìsìn àti ibù
fisìn, nítorí ẹ̀, ẹ má se tún máa sin ẹnìkẹni míràn ní àwọn ààyè náà tàbí fi àwọn
ibùsìn náà sin ẹlòmíràn lẹ́yìn Ọlọ́hun) (Ọgbà ọ̀rọ̀ àwọn àlùjànnú [Suratul Jinn], Ẹsẹ 18).
فَمَنْ صَرَفَ مِنْهَا
شَيْئًا لِغَيْرِ اللهِ فَهُوَ مُشْرِكٌ كَافِرٌ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى:
)وَمَنْ
يَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَهًا آخَرَ لَا بُرْهَانَ لَهُ بِهِ فَإِنَّمَا حِسَابُهُ
عِنْدَ رَبِّهِ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الْكَافِرُونَ( [المؤمنون: 117].
Nítorínáà,
ẹnikẹ́ni tóbá sẹ́rí ọ̀kan nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn wọ̀nyí sọ́dọ̀ ǹkan míràn tó
yàtọ̀ sí Ọlọ́hun, ọ̀sẹ̀bọ afigbá dóore Ọlọ́hun mọ́lẹ̀ (Kèfèrí) ni. Ẹ̀rí èyí ni ọ̀rọ̀
Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí: (Ẹnikẹ́ni
tóbá pe ǹkan míràn tí kò sẹ́rí ìjọsìn tó dájú fún pẹ̀lú Ọlọ́hun, oun tí yóò jẹ́
ẹ̀san rẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́hun rẹ̀ yóò lágbára, dájúdájú kèfèrí kò níí là lọ́jọ́
àgbéǹde àlùkìyáámọ̀) (Ọgbà
ọ̀rọ̀ àwọn olùgbàgbọ́ [Suratul Muuminuuna], ẹsẹ 117).
No comments:
Post a Comment