Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
اعْلَمْ -أَرْشَدَكَ
اللهُ لِطَاعَتِهِ- أَنَّ الْحَنِيفِيَّةَ مِلَّةَ إِبْرَاهِيمَ: أَنْ
تَعْبُدَ اللهَ وَحْدَهُ مُخْلِصًا لَهُ الدِّينَ. وَبِذَلِكَ أَمَرَ اللهُ
جَمِيعَ النَّاسِ، وَخَلَقَهُمْ لَهَا؛ كَمَا قَالَ اللهُ تَعَالَى: )وَمَا
خَلَقْتُ الْجِنَّ وَالْإِنْسَ إِلَّا لِيَعْبُدُونِ(
[الذاريات: 56]. وَمَعْنَى يَعْبُدُونِ: يُوَحِّدُونِ.
ÌTUMỌ̀
Lọrèémọ̀ -Ọlọ́hun (Allahu) yóò tọ́ írẹ sọ́nà ìtẹ̀lé àsẹ rẹ̀-
wípé dájúdájú ìláná tótọ́ tíí se ìlànà ànábì Ibrahimu ni kí o máa sin Ọlọ́hun
(Allahu) níkan soso lẹ́ni tí yóo máa sàfọ̀mọ́ ìjọsìn Fún un. Eléyẹn síni Ọlọ́hun
pa lásẹ fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn, tó sì torí rẹ̀ dáwọn, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́hun tóga
jùlọ tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Èmi [Ọlọ́hun] kó sẹ̀dá àlùjànnú àtí ọmọnìyàn lásán bí
kòse kí wọ́n le máa fi ìjọsìn fún èmi nìkan soo) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Afẹ́rẹ́ [Suratu Al Daariyaati], ẹsẹ 56).
Ìtumọ̀ gbólóhùn “Yaabuduuni” tówà níparì ẹsẹ ọ̀rọ̀ náà ń túmọ̀ sí ‘mímú mi
láàso níbi ìjọsìn’.
وَأَعْظَمُ مَا أَمَرَ اللهُ بِهِ
التَّوْحيِدُ، وَهُوَ إِفْرَادُ اللهِ بِالْعِبَادَةِ.
وَأَعْظَمُ مَا نَهَى عَنْه
الشِّركُ وَهُوَ دَعْوَةُ غَيْرِهِ مَعَهُ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَاعْبُدُوا
اللَّهَ وَلَا تُشْرِكُوا بِهِ شَيْئًا(
[النساء: 36].
ÌTUMỌ̀
Oun tó
fi ń ga júlọ nínú àsẹ Ọlọ́hun (Allahu) ni ìmu lọ́kan soso (At taohiidu) tíí se
ìmú Ọlọ́hun láàso níbi ìjọsìn.
Bẹ́ẹ̀ni
éyí toga jùlọ nínú másèé (Èèwọ̀) Ọlọ́hun ni ímú orogún mọ́ Ọn, tíí se ìmaa tún
pe ǹkan míràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ̀rí
eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ máa sin Ọlọ́hun láìgbọdọ̀ mú ǹkankan lórogún pẹ̀lu rẹ̀) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìrin [Suratu An Nisaai], Ẹsẹ 36).

No comments:
Post a Comment