Sunday, 10 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹjọ)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَقَالَ رَبُّكُمُ ادْعُونِي أَسْتَجِبْ لَكُمْ إِنَّ الَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِي سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ( [غافر: 60]، وَفِي الْحَدِيثِ «الدُّعَاءُ مخ الْعِبَادَةِ».

ÌTUMỌ̀
Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìdírẹ́bẹ Ọlọ́hun (Adua) síse wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ọlọ́hun asẹ̀dá yín tún ń sọ̀pé: “Ẹ pèmí, wun ó sì jẹyín. Dájúdájú gbogbo àwọn tí wọ́n bá ńse yànǹga pẹ̀lu sísìn mí yóò wọ ọ̀gbun iná (jahannama) niti ìyẹpẹrẹ). (Ọgbà ọ̀rọ̀ aláforíjìn [Suratul Gaafiri], ẹsẹ 60). Ó tún wà nínú ọ̀rọ̀ ànábì (Hadiisi) wípé: »ìdírẹ́bẹ Ọlọ́hun (Àdúà) ni ọkàn ìjọsìn«.

وَدَلِيلُ الْخَوْفِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )فَلَا تَخَافُوهُمْ وَخَافُونِ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ( [آل عمران: 175].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìpayà wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ má se kó ìpayà àwọn èsù èèyàn yí sọ́kàn, èmi ni kí ẹ máa bẹ̀rù tóbá jẹ́pé onígbàgbọ́ tòótọ́ niyín} (Ọgbà Ọ̀rọ̀ àwọn aráálé Umuraana [Suratu Aali Umuraana], ẹsẹ 175).

ودليل الرجاء قوله تعالى: )فَمَنْ كَانَ يَرْجُوا لِقَاءَ رَبِّهِ فَلْيَعْمَلْ عَمَلًا صَالِحًا وَلَا يُشْرِكْ بِعِبَادَةِ رَبِّهِ أَحَدًا( [الكهف: 110].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìrankàn wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹnikẹ́ni tó bá ńrankàn ẹ̀san rere nígbà tóbá pàdé Ọlọ́hun rẹ̀, kó yáa mú isẹ́ẹre se, kósì má se mú ẹníkẹ́ni lórogún pẹ̀lú adẹ́dá rẹ̀ níbi isẹ́ ìjọsìn rẹ̀). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ihò Àpata [Sursatul Kahfi], ẹsẹ 110).

ودَلِيلُ التَّوَكُلِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَعَلَى اللَّهِ فَتَوَكَّلُوا إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ( [المائدة: 23]. وقوله تعالى: )وَمَنْ يَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ فَهُوَ حَسْبُهُ( [الطلاق: 3].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìgbẹ́kẹ̀le wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ọlọ́hun nìkan ni kẹ́ẹ gbáralé tóbá jẹ́ onígbàgbọ́ tòótọ́ niyín}. (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Tábìlì Oúnjẹ [Suratul Maaidati], ẹsẹ 23). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹni tóbá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́hun (Allahu), òhun (Allahu) yóó sì to ẹni náà). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ìkọ̀sílẹ̀ [Suratut Tọlaaki], ẹsẹ 23).

وَدَلِيلُ الرَّغْبَةِ وَالرَّهْبَةِ وَالْخُشُوعِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّهُمْ كَانُوا يُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَيَدْعُونَنَا رَغَبًا وَرَهَبًا وَكَانُوا لَنَا خَاشِعِينَ( [الأنبياء: 90].

Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìfẹ́ láti súnmọ́, ìbẹ̀rù ẹ̀sẹ̀, àti ìbọ̀wọ̀ wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Dájúdájú àwọn ẹni Ọlọ́hun tí A kà síwájú yìí máa ń yára salápáǹtètè lọ sibi àwọn isẹ́ rere, wọ́n sì máá ń pèWá pẹ̀lú ìrankàn sísúnmọ́ Wa àti ìsáfún sísẹ̀ Wá, Àwa Ọlọ́hun (Allahu) nìkan ni wọń sì máá ń bọ̀wọ̀ fún). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Ànábì Ọlọ́hun [Suratul Anbiyaai], ẹsẹ 90).

No comments:

The timeless lessons from Abū Bakr’s companionship with the Prophet ﷺ during the migration to Madinah

  كِتَابُ فَضَائِلِ الصَّحَابَةِ مَنَاقِبُ أَبِي بَكْرٍ رَضِي عَنْهُ بَابُ قَوْلِهِ تَعَالَى: ﴿إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ ا...