Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìbẹ̀rù tí yóò mú ìbàbàrà
dání wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí
wípé: (Ẹ má
se bàbàrà wọn, Èmi ni kí ẹ máa bàbàrà) (Ọgbà
Ọ̀rọ̀ Màálù [Suratul Bakarati], ẹsẹ 150).
وَدَلِيلُ الإِنَابَةِ
قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَأَنِيبُوا إِلَى رَبِّكُمْ وَأَسْلِمُوا لَهُ( [الزمر: 54].
Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìsẹ́rí padà wà nínú àwọn isẹ́
ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ sẹ́rí
padà sọ́dọ̀ adẹ́dá yín, kí ẹ sì jọ̀wọ́ ara yín fún Un) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Ìjọ Àlùjánnà àti Ina [Suratuz Zumar], ẹsẹ 54).
وَدَلِيلُ الاسْتِعَانَةِ
قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِيَّاكَ نَعْبُدُ وَإِيَّاكَ نَسْتَعِينُ( [الفاتحة: 5]. وفي الحديث: «إذا اسْتَعَنْتَ فَاسْتَعِنْ
بِاللهِ».
Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé títọrọ ìrànwọ́ wà nínú àwọn
isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ìwọ Ọlọ́hun
nìkan ni aó máa sìn, Ìrẹ nìkan sì ni aó máa wá ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀). (Ọgbà
Ọ̀rọ̀ Ìsí Àlùkúráánì [Suratul Faatihati], ẹsẹ 5). Ó tún wà nínú ọ̀rọ̀ ànábì (Hadiisi) wípé: »Tí o bá fẹ́ẹ́ wá ìrànwọ́, ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun nìkan ni kóo ti wáa«.
وَدَلِيلُ الاسْتِعَاذَةِ
قَوْلُهُ تَعَالَى: )قُلْ أَعُوذُ بِرَبِّ النَّاسِ ۞ مَلِكِ النَّاسِ( [الناس: 1 -2].
Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé títọrọ ìsọra wà nínú àwọn
isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ìrẹ ànábì, sọpé mofi Ọlọ́hun Adẹ́dá gbogbo ọmọnìyàn wá ìsọ́
۞ Ọba tó kápá gbogbo ọmọnìyàn). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ọmọnìyàn [Suratun Naasi], ẹsẹ 1-2).
وَدَلِيلُ الاسْتِغَاثَةِ
قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِذْ تَسْتَغِيثُونَ رَبَّكُمْ فَاسْتَجَابَ لَكُمْ( [الأنفال: 9].
Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé títọrọ ọ̀nà àbayọ wà nínú
àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹrántí
ìgbà tí ẹ̀ń tọrọ ọ̀nà àbayọ lọ́dọ̀ Ọlọ́hun Asẹ̀dá yín, tósì dayín lóhùn ìbèèrè
yín). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Èrè
Ogun [Suratul Anfaali], ẹsẹ 9).
ودليل الذبح قوله تعالى: )قُلْ
إِنَّ صَلَاتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ لَا
شَرِيكَ لَهُ وَبِذَلِكَ أُمِرْتُ وَأَنَا أَوَّلُ الْمُسْلِمِينَ( [الأنعام: 162 -163]. وَمِنَ
السُنَّةِ: «لعَنَ اللهُ مَنْ ذَبَحَ لِغَيْرِ اللهِ».
Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìdúńbú wà nínú àwọn isẹ́
ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Máa sọ
wípé dájúdájú ìjọsìn ìrun kíkí tí mò ń se àti ìgunran mi, ààyè mi àti ikú mi pẹ̀lú,
ti Ọlọ́hun Ọba tí kò lórogún Asẹ̀dá gbogbo àgbáńlá ayé nìkan soso ni, àtipé eléyí
ni Ọlọ́hun pamí lásẹ rẹ̀. Èmi sì jẹ́ àkọ́kọ́ àwọn olùgbà fỌ́lọ́hun lórí àwọn àsẹ
rẹ̀). (Ọgbà Àwọn Ẹran
[Suratul Anaai], ẹsẹ 162-163). Ó tún wà
nínú ọ̀rọ̀ ànábì (Hadiisi) wípé: »Ọlọhun sẹ́bi lé ẹni tóbá dúran fún ǹkan míràn lẹ́yìn Ọlọ́hun«.
وَدَلِيلُ النَّذْرِ
قَوْلُهُ تَعَالَى: )يُوفُونَ بِالنَّذْرِ وَيَخَافُونَ يَوْمًا كَانَ شَرُّهُ
مُسْتَطِيرًا( [الإنسان: 7].
Ẹ́rí
máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé ìjẹ́jẹ́ wà nínú àwọn isẹ́ ìjọsìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun
(Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Àwọn ẹrú
Ọlọ́hun tí igbadun yí yóò máa jẹ́ tiwọn ni àwọn tí wọ́n má ńmú ẹ̀jẹ́ wọn sẹ, tí
wọ́n sì tuń máa ńbẹ̀rù ọjọ́ tí wàhálà àti ìfòòró rẹ̀ kò níí fẹ́ẹ̀ dá ẹnìkansí). (Ọgbà
Ìran Ọmọnìyàn [Suratul Insaani], ẹsẹ 7).

No comments:
Post a Comment