Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
اعْلَمْ -رَحِمَكَ اللهُ-
أَنَّه يَجِبُ عَلَى كُلِّ مُسْلِمٍ وَمُسْلِمَةٍ تَعَلُّمُ هَذِهِ الثَّلاثِ
مَسَائِل والْعَمَلُ بِهِنَّ:
الأُولَى: أَنَّ اللهَ خَلَقَنَا وَرَزَقَنَا وَلَمْ يَتْرُكْنَا هَمَلا،
بَلْ أَرْسَلَ إِلَيْنَا رَسُولاً، فَمَنْ أَطَاعَهُ دَخَلَ الجَنَّةَ، وَمَنْ
عَصَاهُ دَخَلَ النَّارَ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿إِنَّا أَرْسَلْنَا إِلَيْكُمْ رَسُولًا
شَاهِدًا عَلَيْكُمْ كَمَا أَرْسَلْنَا إِلَى فِرْعَوْنَ رَسُولًا فَعَصَى
فِرْعَوْنُ الرَّسُولَ فَأَخَذْنَاهُ أَخْذًا وَبِيلًا﴾ [المزمل: 15 - 16].
ÌTUMỌ̀
Lọrèémọ̀ -Ọlọ́hun (Allahu) yóò kẹ́ ọ- wípé ó tún di ọ̀ranyàn
lé gbogbo mùsùlùmí lọ́kùnrin lóbìnrin lórí ì mọ̀ nípa àwọn àláámọ̀rí mẹ́ta tó ń
bọ̀yí pẹ̀lú sí sisẹ́ tọ̀wọ́n:
Ákọ́kọ́: ni wípé
Ọlọ́hun (Allahu) ni ó sẹ̀dá wa, òun náà sì ni ó ń se íjẹ ìmu (Arísìkí) fún wa,
kò tún wáá fiwá kalẹ̀ lásán, ó tún rán òjísẹ́ kan síwa, ẹnikéni tó bá tẹ̀le ìlànà
rẹ̀ ti fi ọgbà ìdẹ̀ra (Àlùjánnà) se ìfà jẹ, ẹnikéni tó bá sì yapa ilànà rẹ̀ ti
lùgbàdì iná. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Pàá a ti rán an sí yín òjísẹ́ kan tí yóò máa jẹ́ ẹlẹ́rì leyín
lórí gẹ́gẹ́ bí a ti se rán òjísẹ́ sí Fíríáónà sùgbọ́n tí ó kọ etí ikún sí òjísẹ́
wa, a wáá torí rẹ̀ fi ọwọ́ agbára apanirun múu). (Suratu Musamilu, 15-16).
No comments:
Post a Comment