Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
الثَّانِيَةُ: أَنَّ الله لا يَرْضَى أَنْ يُشْرَكَ معه أحدً في عبادته، لا
مَلَكٌ مُقَرَّبٌ، وَلا نَبِيٌّ مُرْسَلٌ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿وَأَنَّ الْمَسَاجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدْعُوا
مَعَ اللَّهِ أَحَدًا﴾ [الجن: 18].
ÌTUMỌ̀
Ẹ̀kejì: òun ni wípé dájúdájú Ọlọ́hun (Allahu) kò níí yọ́nú sí ìmú ẹnikẹ́ni
ní orogún pẹ̀lú rẹ̀ níbi isẹ́ ìjọsìn Fún un, kì bá ǹ jẹ́ màláíká tó sùnmọ́ Ọn,
tàbí ọ̀kan nínú àwọn ànábì tó fi isẹ́ rán. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀
rẹ̀ lọ báyí wípé: (Dájúdájú, ti Ọlọ́hun nìkan soso ni gbogbo ààyè ìsìn àti ibù
fisìn, nítorí náà, ẹ má se tún máa sin ẹnìkẹni míràn ní àwọn ààyè náà tàbí fi àwọn
ibùsìn náà sin ẹlòmíràn lẹ́yìn Ọlọ́hun) (Ọgbà ọ̀rọ̀ àlùjànnú [Suratul Jinni], Ẹsẹ 18).
الثَّالِثَةُ: أَنَّ مَنْ أَطَاعَ الرَّسُولَ وَوَحَّدَ اللهَ، لا يجوز له موالاة
من حادَّ الله وَرَسُولَهُ، وَلَوْ كَانَ أَقْرَبَ قَرِيبٍ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ
تعالى: ﴿لَا تَجِدُ قَوْمًا يُؤْمِنُونَ
بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ يُوَادُّونَ مَنْ حَادَّ اللَّهَ وَرَسُولَهُ
وَلَوْ كَانُوا آبَاءَهُمْ أَوْ أَبْنَاءَهُمْ أَوْ إِخْوَانَهُمْ أَوْ
عَشِيرَتَهُمْ أُولَئِكَ كَتَبَ فِي قُلُوبِهِمُ الْإِيمَانَ وَأَيَّدَهُمْ
بِرُوحٍ مِنْهُ وَيُدْخِلُهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ
خَالِدِينَ فِيهَا رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ أُولَئِكَ حِزْبُ
اللَّهِ أَلَا إِنَّ حِزْبَ اللَّهِ هُمُ الْمُفْلِحُونَ﴾ [المجادلة: 22].
ÌTUMỌ̀
Ẹ̀kẹta: nipé ẹni tó bá ń tẹ̀le
òjísẹ́ Ọlọ́hun (Allahu) lódodo, tó sì gbà Ọlọ́hun lọ́kan soso, kò tọ́ fún un
láti mú olùkọ tọlọ́hun àti òjísẹ́ rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ ààyò. Ẹ̀rí
eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Oò le
rí ọ̀kankan nínú àwọn èèyàn tó ní ígbàgbọ́ òdodo sí Ọlọ́hun àti ọjọ́ ìkẹhìn tí
yóò maa sọ̀rẹ́ ààyò pẹ̀lú àwọn ọ̀tá Ọlọ́hun àti òjísẹ rẹ̀, kódà kí wọ́n jẹ́
bàbá, tàbí ọmọ, tábí ọmọ ìyá, tàbí mọ̀lẹ́bí fún wọn. Irú àwọn wọ̀nnì ni Ọlọ́hun
se àfirinlẹ̀ ìgbàgbọ̀ sínú ọkàn wọn tí Ó tún se ìkúnwọ fún wọn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀
láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí yóò sì tún fiwọ́n wọ ọgbà ìdẹ̀ra (Àlùjánnà) tí àwọn akérémọdò
ń sàn lábẹ́ rẹ́ lẹ́ni tí yóò se gbére nínú rẹ́, látààrí pé Ọlọ́hun (Allahu) yọ́nú
síwọn, àwọn náà sì yọ́nú sí I (Allahu). Àwọn wọ̀nnì ni a le pè ní ọmọ ogun Ọlọ́hun
(Allahu), Ẹ tẹ́tí gbọ́, àwọn ọmọ ogun Ọlọ́hun (Allahu) ni ẹni ọlà)
(Ọgbá ọ̀rọ̀ irin [Suratul Hadiid], Ẹsẹ 22).
No comments:
Post a Comment