Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
فَقُلْ: مَعْرِفَةُ الْعَبْدِ رَبَّهُ،
وَدِينَهُ وَنَبِيَّهُ مُحَمَّدًا صلى
الله عليه وسلم.
ÌTUMỌ̀
Tí wọ́n bá bi ọ́ léèrè wípé àwọn ìpìlẹ̀ mẹ́ta wo lódi ọ̀ranyàn kí gbogbo ọmọnìyàn
mọ̀ nípa wọn?
Fún wọn lésì wípé àwọn ni: ìmọ̀ ẹrú nípa olùtọ́jú rẹ̀ tíí se Ọlọ́hun, ẹ̀sìn
rẹ̀, àti òjísẹ́ tí wọ́n rán síi tíí se Muhammadu –kí àlékún íkẹ́ àti ìgẹ̀ Ọlọ́hun
máa báa.
فَإِذَا قِيلَ لَكَ: مَنْ رَبُّكَ؟
فَقُلْ: رَبِّيَ اللهُ الَّذِي رَبَّانِي
وَرَبَّى جَمِيعَ الْعَالَمِينَ بِنِعَمِهِ، وَهُوَ مَعْبُودِي لَيْسَ لِي
مَعْبُودٌ سِوَاهُ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )الْحَمْدُ
لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ( [الفاتحة: 2]. وَكُلُّ مَا سِوَى اللهِ
عَالَمٌ وَأَنَا وَاحِدٌ مِنْ ذَلِكَ الْعَالَمِ.
ÌTUMỌ̀
Tí wọ́n bá wáá bi ọ́ léèrè pé taani olùtọ́jú rẹ?
Dá wọn lóhùn wípé: Ọlọ́hun (Allahu) ni olùtọ́jú mi, òun náà ni olùtọ́jú gbogbo àgbááyé tí ń bẹ pẹ̀lú
orísírísí ìdẹ̀ra Rẹ̀. Òhun náà sì ni ẹni tó lẹ́tọ̀ sí ìjọsìn tèmi tí kò sí ẹlòmíràn
tó tún lẹ́tọ̀ síi. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́hun, Ọba Olùtọ́jú gbogbo àgbáńlá ayé) (Ọgbà ọ̀rọ̀ ìsí Alukurani [Suratu Al Faatiha], ẹsẹ 2). Eléyí ń túmọ̀ sí
wípé gbogbo oun tó bá ti yàtọ̀ sí Ọlọ́hun ni àgbááye, ọ̀kan sì ni èmi náà nínú
àgbááyé náà.
فَإِذَا قِيلَ لَكَ: بِمَ عَرَفْتَ
رَبَّكَ؟
فَقُلْ: بِآيَاتِهِ وَمَخْلُوقَاتِهِ
وَمِنْ آيَاتِهِ اللَّيْلُ وَالنَّهَارُ وَالشَّمْسُ وَالْقَمَرُ وَمِنْ
مَخْلُوقَاتِهِ السَّمَاوَاتُ السَّبْعُ وَالأَرَضُونَ السَّبْعُ وَمَنْ فِيهِنَّ
وَمَا بَيْنَهُمَا، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَمِنْ
آيَاتِهِ اللَّيْلُ وَالنَّهَارُ وَالشَّمْسُ وَالْقَمَرُ لَا تَسْجُدُوا
لِلشَّمْسِ وَلَا لِلْقَمَرِ وَاسْجُدُوا لِلَّهِ الَّذِي خَلَقَهُنَّ إِنْ
كُنْتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ( [فصلت: 37]، وقوله تعالى: )إِنَّ
رَبَّكُمُ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ
ثُمَّ اسْتَوَى عَلَى الْعَرْشِ يُغْشِي اللَّيْلَ النَّهَارَ يَطْلُبُهُ حَثِيثًا
وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ وَالنُّجُومَ مُسَخَّرَاتٍ بِأَمْرِهِ أَلَا لَهُ
الْخَلْقُ وَالْأَمْرُ تَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ(
[الأعراف: 54].
ÌTUMỌ̀
Tí wọ́n bá tún wáá bi ọ́ pé kíni o fi dá Ọlọ́hun rẹ mọ̀?
Sọ fún wọn wípé: pẹ̀lú àwọn isẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ẹ̀dá àràmọ̀ǹdà tódá ni
mo fi mọ̀ Ọ́n. Nínú àwọn oun ámì ìyanu rẹ̀ ni: òru, ọ̀sán, òòrùn, àti òsùpá.
Nínú àwọn ẹ̀dá àràmọ̀ǹdà tódá sì ni: àwọn sánmọ̀ méjèèje àti àwọn ilẹ̀ méjèèje
pẹ̀lú gbogbo oun tí ńbẹ nínú àti láàrin wọn. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí
ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Àtipé nínú àwọn oun isẹ́ ìyanu Rẹ̀ (Ọlọ́hun) ni òru àti ọ̀sán pẹ̀lú òòrùn
àti òsùpá. Nítorínáà, ẹ má se máa júbà fún òòrùn àti òsùpá, Ọlọ́hun (Allahu) tó
sẹ̀dá wọn ni kẹ́ẹ máa júbà fún tóbá jẹ́pé òun ni ẹ̀ ń sìn lódodo) (Ọgbà ọ̀rọ̀ ìfọ́síwẹ́wẹ́ [Suratu Fussilat], ẹsẹ 37). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí
ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Dájúdájú olùtọ́jú yín ni Ọlọ́hun tó sẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ní àlàfo ọjọ́
mẹ́fà, lẹ́yìn náà ni ó wáá gúnwà sórí ìtẹ́-ọlá (Araṣi) Rẹ̀, Ó sì ńfi ọ̀sán àti
òru bo ara wọn, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ń yára gbasẹ́ lọ́wọ́ ara wọn. Òhun (Ọlọ́hun)
náà ni ó tún sẹ̀dá òòrùn àti òsùpá àti àwọn íráwọ̀ tó fi àsẹ Rẹ́ tẹ̀wọ́n lórí
ba. Ẹtẹ́tí gbọ́, tỌlọ́hun (Allahu) ni ìsẹ̀dá àti àsẹ, mímọ́ Ọlọ́hun tí ń tọ́jú
gbogbo àgbáńlá ayé) (Ọgbà ọ̀rọ̀ àwọn alágbede méjì [Suratul Aaraafi], ẹsẹ
54).
وَالرَّبُ هُوَ الْمَعْبُودُ، وَالدَّلِيلُ
قَوْلُهُ تَعَالَى: )يَا أَيُّهَا
النَّاسُ اعْبُدُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ
لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ ^ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ فِرَاشًا
وَالسَّمَاءَ بِنَاءً وَأَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجَ بِهِ مِنَ
الثَّمَرَاتِ رِزْقًا لَكُمْ فَلَا تَجْعَلُوا لِلَّهِ أَنْدَادًا وَأَنْتُمْ
تَعْلَمُونَ(
[البقرة: 21 - 22]. قَالَ ابْنُ كَثِيرٍ رَحِمَهُ
اللهُ تَعَالَى: الخَالِقُ لهذه الأشياء هو المستحق للعبادة.
ÌTUMỌ̀
Ọlọ́hun Adẹ́dá yìí nàà ni Ó tọ́sí ìjọsìn òdodo, Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun
tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ̀yin ọmọnìyàn, ẹ máa jọ́sìn fún Ọlọ́hun tó sẹ̀dá yín àti gbogbo àwọn tó
siwájú yín bóyá ẹ́ẹ́le bẹ̀rù Ọlọ́hun ۞ Ọba tó tẹ́ ilẹ̀ funyín ní pẹrẹsẹ, tófi sánmọ̀ sààbò leyín lórí, Ó
tún wá ń rọ òjò kalẹ̀ láti sánmọ̀ náà, èyí tí ń sokùnfà kí orísìrísì èso jade
kóle máa jẹ́ ìpèsè jíjẹ àti mímu fúnyín. Torínáà, ẹ má se mórogún mọ́ Ọlọ̀hun tí ẹ̀yin náà sì mọ̀ pé kò lórogún). Olùmọ̀ àgbà Ibn Kaseer sọpé: “Èyí ń túmọ̀ sí wípé: ẹni tó sẹ̀dá gbogbo
ǹkan wọ̀nyí nìkan ni Ó lẹ́tọ́ sí ìjọsìn”.

No comments:
Post a Comment