Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
فَلَمَّا اسْتَقَرَّ فِي
الْمَدِينَةِ أُمِرَ بِبَقِيَّةِ شَرَائِعِ الإِسْلامِ مِثلِ الزَّكَاةِ،
وَالصَّوْمِ، وَالْحَجِّ، وَالأَذَانِ، وَالْجِهَادِ، وَالأَمْرِ بِالْمَعْرُوفِ،
وَالنَّهْيِ عَنِ الْمُنْكَرِ، وَغَيْرِ ذَلِكَ مِنْ شَرَائِعِ الإِسْلامِ. أَخَذَ
عَلَى هَذَا عَشْرَ سِنِينَ. وَتُوُفِّيَ صَلواتُ اللهِ وَسَلامُهُ عَلَيْهِ
وَدِينُهُ بَاقٍ، وَهَذَا دِينُهُ، لا خَيْرَ إِلا دَلَّ الأُمَّةَ عَلَيْهِ وَلا
شَرَّ إِلا حَذَّرَهَا مِنْهُ، وَالْخَيْرُ الَّذِي دَلَّهَا عَلَيْهِ التَّوْحِيدُ
وَجَمِيعُ مَا يُحِبُّهُ اللهُ وَيَرْضَاهُ، وَالشَّرُ الَّذِي حَذَّرَهَا مِنْهُ
الشِّرْكُ وَجَمِيعُ مَا يَكْرَهُ اللهُ وَيَأْبَاهُ.
Nígbà tí Ànábì gúnlẹ̀ sí
Màdíínà, wọ́n paá lásẹ àwọn òfin ẹ̀sìn yókù, bíi Sàká Owó yíyọ, Ààwẹ̀ gbígbà,
Ìjọsìn Hajji, Ìrun pípè, Ogun jíjà, Ìpàsẹ dáadáa àti Ìkọ Àìdaa, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀
lọ nínú àwọn Òfin Ẹ̀sìn. Ọdún mẹ́wá gbáko ni eléyá gbà. Ànábì –kí àlékún ìkẹ́
àti ìgẹ̀ Ọlọ́hun máa bá a- ti kú, ẹ̀sìn rẹ̀ sì sẹ́kù. Àwọn oun tí ó ti síwájú
yí sì ni ẹ̀sìn rẹ̀. Kò sí ǹkankan tí oore wà níbẹ̀ àyàfi kí ó tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn
rẹ̀ níka sí i, kò sì sí ǹkankan tí ó jẹ́ aburú àyàfi kí ó kìwọ́n nílọ̀ nipa rẹ̀.
Àwọn oun rere tí ó tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níka sí ni: “Ìmú Ọlọ́hun lọ́kan soso,
àti gbogbo oun tí Ọlọ́hun bá ní ìfẹ́ sí, tí Ó sì yọ́nú sí”. Àwọn oun aburú tí ó
sì lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jìnnà sí ni: “Ẹbọ síse, àti èyíkéyí oun tí Ó bá kọ̀,
tí kÒ sì nífẹ́ sí”.
بَعَثَهُ الله في النَّاسِ
كَافَّةً، وَافْتَرَضَ طَاعَتَهُ عَلَى جَمِيعِ الثَّقَلَيْنِ الْجِنِّ وَالإِنْسِ.
وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ
جَمِيعًا( [الأعراف: 158].
Gbogbo ìran èèyàn pátá ni Ọlọ́hun rán Ànábì sí, Ó sì se
ìtẹ̀le ní ọ̀ranyàn fún gbogbo ìran èèyàn àti alujannnu. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun
tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ìrẹ Ànábì, sọpé: “Ẹ̀yin ọmọnìyàn, òjísẹ́ Ọlọ́hun ni mo jẹ́
sí gbogbo yín pátá). (Ọgbà ọ̀rọ̀ àwọn
alágbede méjì [Suratul Aaraafi], ẹsẹ 158).
وَكَمَّلَ اللهُ بِهِ
الدِّينَ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ
نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الْإِسْلَامَ دِينًا( [المائدة: 3].
Ànábì yí ni Ọlọ́hun fi pé ẹ̀sìn Ìsìláámù. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀
Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ní òní yí, èmi (Ọlọ́hun) ti pé ẹ̀sìn yín fún yín, mo sì
ti parí ìdẹ̀ra mi leyin lórí, Ìsìláámù ni mo sì yọ́nú sí lẹ́sìn fún yín). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Tábìlì
Óunjẹ [Suratul Maaidati], ẹsẹ 3).
وَالدَّلِيلُ عَلَى مَوْتِهِ
صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّكَ مَيِّتٌ وَإِنَّهُمْ مَيِّتُونَ ^ ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عِنْدَ رَبِّكُمْ
تَخْتَصِمُونَ( [الزمر: 30 - 31]. وَالنَّاسُ إِذَا مَاتُواْ يُبْعَثُونَ، وَالدَّلِيلُ
قَوْلُهُ تَعَالَى: )مِنْهَا خَلَقْنَاكُمْ وَفِيهَا نُعِيدُكُمْ وَمِنْهَا نُخْرِجُكُمْ
تَارَةً أُخْرَى( [طه: 55]، وقَوْلُهُ تَعَالَى: )وَاللَّهُ أَنْبَتَكُمْ مِنَ الْأَرْضِ نَبَاتًا ^ ثُمَّ يُعِيدُكُمْ
فِيهَا وَيُخْرِجُكُمْ إِخْرَاجًا( [نوح: 17 - 18]. وَبَعْدَ الْبَعْثِ مُحَاسَبُونَ وَمَجْزِيُّونَ
بِأَعْمَالِهِمْ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ لِيَجْزِيَ
الَّذِينَ أَسَاءُوا بِمَا عَمِلُوا وَيَجْزِيَ الَّذِينَ أَحْسَنُوا بِالْحُسْنَى( [النجم: 31]. وَمَنْ
كَذَّبَ بِالْبَعْثِ كَفَرَ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )زَعَمَ
الَّذِينَ كَفَرُوا أَنْ لَنْ يُبْعَثُوا قُلْ بَلَى وَرَبِّي لَتُبْعَثُنَّ ثُمَّ
لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلْتُمْ وَذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ( [التغابن: 7].
Ẹ̀rí lórí ikú Ànábì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ
bayi wípé: (Dájúdájú ìwọ Ànábì yóò kú, kò sì sí iyèméjì pé àwọn
aláìgbọràn náà yóò kú ^ lẹ́yìn náà, ẹó dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun yín ní ọjọ́ ìgbéǹde
àlùkíyáámọ̀ lọ rèé yanjú gbogbo oun tí ń dá họ́ù họ́ù kalẹ̀ láàrin yín). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Ìjọ Ìjọ [Suratuz Zumar], ẹsẹ 30-31).
Ìgbéǹde yóó sì sẹlẹ̀ sí ọmọ èèyàn lẹ́yìn ikú. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí
ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Láti inú iyẹ̀pẹ̀ ni A ti sẹ̀dá yín, inú rẹ̀ náà ni A yóò
sì dayín padà sí, láti inú rẹ̀ náà ni A yóò si ti gbéyin dìde ní ìgbà míràn). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Tọọhaa [Suratu Tọọhaa], ẹsẹ 55). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun
tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ọlọ́hun (Allahu) ni Ó fàyín yọ láti inú ilẹ̀ ní ti fífàyọ
^ Lẹ́yìn náà, yóò dayín padà sí inú rẹ̀, yóó tún wáá
muyín jáde níti mímú jáde). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ànábì Nua [Suratu Nuuha], ẹsẹ 17-18). Lẹ́yìn
àgbéǹde, ọmọ ènìyàn yóò se ìṣirò, wọn yóò sì gbẹ̀san isẹ́ wọn. Ẹ̀rí
lórí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Ti Ọlọ́hun (Allahu) nìkan ni gbogbo oun tí ń bẹ ní sánmọ̀
àti ilẹ̀, kí Ọlọ́hun le san àwọn ẹni aburú le gbẹ̀san isẹ́ wọn, kí Ó sì le fi
dáradára san àwọn ẹnire lẹ́san). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ìràwọ̀ [Suratun Najmi], ẹsẹ 31). Ẹni
tí ó bà sì pe ìgbéǹde nírọ́ ti se kèfèrí. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀
rẹ̀ lọ bayi wípé: (Àwọn aláìgbàgbọ́ (Kèfèrí) lérò wípé wọn kò níí gbé àwọn
dìde lẹ́yìn ikú. Sọ (Ìrẹ Ànábì) fún wọn wípé: “Kò rí bí ẹ se ń ró”. Ọlọ́hun
yóò gbeyín dìde. lẹ́yìn náà, yóò tún sanyín lẹ́san isẹ́ tí ẹ gbáyé se. Eléyẹn
(Ìsirò) sì jẹ́ oun tí ó rọ Ọlọ́hun lọ́rùn). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ìyanra Ẹni jẹ [Suratut Tagaabuni], ẹsẹ
7).
وَأَرْسَلَ اللهُ جَمِيعَ
الرُّسُلِ مُبَشِّرِينَ وَمُنْذِرِينَ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )رُسُلًا
مُبَشِّرِينَ وَمُنْذِرِينَ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى اللَّهِ حُجَّةٌ
بَعْدَ الرُّسُلِ( [النساء: 165]. َوَأَّولُهُمْ نُوحٌ عَلَيْهِ السَّلامُ،
وَآخِرُهُمْ مُحَمَّدٌ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ. وَهُوَ خَاتَمُ
النَّبِيِّينَ، وَالدَّلِيلُ عَلَى أَنَّ أَوَّلَهُمْ نُوحٌ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّا
أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ كَمَا أَوْحَيْنَا إِلَى نُوحٍ وَالنَّبِيِّينَ مِنْ
بَعْدِهِ( [النساء: 163]، وكل أمة
بعث الله إليهم رسولا من نوح إلى محمد يَأْمُرُهُمْ بِعِبَادَةِ اللهِ وَحْدَهُ
وَيَنْهَاهُمْ عَنْ عِبَادَةِ الطَّاغُوتِ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )وَلَقَدْ
بَعَثْنَا فِي كُلِّ أُمَّةٍ رَسُولًا أَنِ اُعْبُدُوا اللَّهَ وَاجْتَنِبُوا( [النحل: 36].
Isẹ́ tí Ọlọ́hun firán gbogbo àwọn òjísẹ́ tí ó gbé dìde
pata ni ìmaa fún àwọn ènìyàn ni ìró idunnu àti ìmaa kìwọ́n nílọ̀. Ẹ̀rí rẹ̀ ni ọ̀rọ̀
Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Àwọn òjísẹ́ wọ̀nyí ni àwọn tí A gbé dìde láti máa fún àwọn
ẹni rere ní ìró ìdùnní, kí wọn ó sì máa se ìkìlọ̀ fún àwọn òbìlẹ̀jẹ́, kí ọmọnìyàn
má lè rí àwíjàre kan lẹ́yìn tí Ọlọ́hun ti gbé òjísẹ́ dìde síwọn). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin [Suratun Nisaai], ẹsẹ 165). Àkọ́kọ́
àwọn òjísẹ́ yí ni “Nua”. Ìgbẹ̀yìn wọn ni òjísẹ́ ńla Muhammadu kí àlékún ìkẹ́
àti ìgẹ̀ Ọlọ́hun máa ba. Muhammadu sì ni òpin gbogbo àwọn Ànábì Ọlọ́hun. Ẹ̀rí
lórí wípé “Nua” ni àkọ́kọ́ àwọn òjísẹ́ Ọlọ́hun ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ
bayi wípé: (Dájúdájú àwa (Ọlọ́hun) ni A mí sí ìwọ (Muhammadu) gẹ́gẹ́
bí A se mí sí “Nua” àti gbogbo àwọn ànábì tí wọ́n wá lẹ́yìn rẹ̀). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin [Suratun Nisaai], ẹsẹ 163).
Gbogbo ìjọ tí Ọlọ́hun rán òjísẹ́ sí pátá láti orí ànábì “Nua” tó fi dé orí
“Muhammadu” ni ó jẹ́ wípé oun tí wọ́n máá ń pa àwọn èèyàn wọn lásẹ ni ìjọsìn fỌ́lọhun
nìkan soso, àti ìkọ̀ fún wọn níbi ìjọsìn fún ǹkan míràn lẹ́yìn Ọlọ́hun. Ẹ̀rí rẹ̀
ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Paa, awa (Ọlọ́hun) ti gbé dìde sí gbogbo ìjọ kọ̀ọ̀kan
òjísẹ́ kan tí yóò máa sọ fún wọn wípé Ọlọ́hun nìkan ni kí ẹ máa jọ́sìn fún, kí
wọn ó sì jinna sí ìjọsìn fún ǹkan míràn tí ó yàtọ̀ sí Ọlọ́hun). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Oyin [Suratun Nahli], ẹsẹ 36).
وَافْتَرَضَ اللهُ عَلَى
جَمِيعِ الْعِبَادِ الْكُفْرَ بِالطَّاغُوتِ وَالإِيمَانَ بِاللهِ. قَالَ ابْنُ
الْقَيِّمِ رَحِمَهُ اللهُ تَعَالَى: "مَعْنَى الطَّاغُوتِ مَا تَجَاوَزَ
بِهِ الْعَبْدُ حَدَّهُ مِنْ مَعْبُودٍ أَوْ مَتْبُوعٍ أَوْ مُطَاعٍ.
وَالطَّوَاغِيتُ كَثِيرُونَ؛ وَرُؤُوسُهُمْ خَمْسَةٌ، إِبْلِيسُ لَعَنَهُ اللهُ،
وَمَنْ عُبِدَ وَهُوَ رَاضٍ، وَمَنْ دَعَا النَّاسَ إِلَى عِبَادَةِ نَفْسِهِ،
وَمَنْ ادَّعَى شَيْئًا مِنْ عِلْمِ الْغَيْبِ، وَمَنْ حَكَمَ بِغَيْرِ مَا
أَنْزَلَ اللهُ، وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )لَا إِكْرَاهَ فِي الدِّينِ قَدْ تَبَيَّنَ الرُّشْدُ مِنَ الْغَيِّ
فَمَنْ يَكْفُرْ بِالطَّاغُوتِ وَيُؤْمِنْ بِاللَّهِ فَقَدِ اسْتَمْسَكَ
بِالْعُرْوَةِ الْوُثْقَى لَا انْفِصَامَ لَهَا وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ( [البقرة: 256]، وَهَذَا هُوَ
مَعْنَى لا اله إِلا اللهُ. وَفِي الْحَدِيثِ: «رَأْسُ الأَمْرِ الإِسْلامِ
وَعَمُودُهُ الصَّلاةُ وَذِرْوَةُ سَنَامِهِ الْجِهَادُ فِي سَبِيلِ اللهِ».
وَاللهُ أعلم.
Ọlọ́hun
(Allahu) se ìgbẹ́rùgbọnrí sí oun ìfẹ́ inú tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Ọlọ́hun,
àti ìnígbàgbọ́ sí Ọlọ́hun nìkan soso ní ọ̀ranyàn fuń àwọn ẹrúsìn rẹ̀. Olùmọ̀
àgbà Ibnul Qayyimi –kí Ọlọ́hun lé kún ìkẹ́ rẹ̀- sọ nínú ọ̀rọ̀ tiwọn wípé: “Ìtumọ̀
“Taaguutu” ni oun tí ẹrú bá tasẹ̀ àgẹ̀ẹ̀rẹ̀ lòrí rẹ̀ níbi sísìn, tàbí títẹ̀lé,
tàbí ìgbọràn sí lẹ́nu. Àwọn “taaguutu” yí wáá pọ̀ rẹpẹtẹ; àwọn olori wọn jẹ́
marun: “Bìlísì (Èsù) kí Ọlọ́hun gbé e jinna sí ìkẹ́, gbogbo ẹni tí ó bá yọ́nú
sí kí wọn ó máa jọ́sìn fún un, gbogbo ẹni tí ó bá ń pe àwọn èèyàn lọ sí ibi ìjọsìn
fuń un, ẹni tí ó bá ń pe àpèmọ́ra ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀, àti ẹni tí ó bá ń fi oun tí
ó yàtọ̀ sí òfin Ọlọ́hun se ìdájọ́. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ
bayi wípé: (kò sí
ìfipámúni níbi ẹ̀sìn, nitoripé ọ̀nà òdodo ti fojú han lẹ́gbẹ́ ọ̀nà anù. Ẹni tí
ó bá gbẹ́rùgbọnrí tàbí se (kèfèrí) sí ǹkan míràn tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Ọlọ́hun,
paa, ó ti di okun Ọlọ́hun tí ó nípọn tí kò lè já mú. Ọlọ́hun Ọba tí ó ń gbọ́
tí ó sì nímọ̀ jùlọ ni). (Ọgbà
Ọ̀rọ̀ Ògédègbe Màálù [Suratul Bagbarati], ẹsẹ 256). Eléyí ni ìtumọ̀ “Laa ilaha
illal lahu”. Ó tún wà nínú ọ̀rọ̀ (Hadiisi) Ànábì –kí àlékún ìkẹ́ àtí ìgẹ̀ máa
báa- wípé: “Olórí gbogbo àláámọ̀rí pátá ni ìjupá jusẹ̀ sílẹ̀ (Ìsìláámù) fún Ọlọ́hun,
Òpó tí ó sì gbé ẹ̀sìn dúró ní ìrun kíkí, Eyín ọ̀gàn rẹ̀ sì ni jíjagun sí ojú ọ̀nà
Ọlọ́hun”. Ọlọ́hun nìkan ni Ó nímọ̀ jùlọ.

No comments:
Post a Comment