الأَصْلُ
الثَّانِي
ÌPÌLẸ̀ ẸLẸ́Ẹ̀KEJÌ
مَعْرِفَةُ دِينِ
الإِسْلَامِ بِالأَدِلَّةِ
MÍMỌ̀ NÍPA Ẹ̀SÌN PẸ̀LÚ ÀWỌN ÌTỌ́KA RẸ̀
Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
وَهُوَ: الاسْتِسْلامُ للهِ
بِالتَّوْحِيدِ، وَالانْقِيَادُ لَهُ بِالطَّاعَةِ، وَالْبَرَاءَةُ مِنَ الشِّرْكِ
وَأَهْلِهِ. وَهُوَ ثَلاثُ مَرَاتِبَ: الإسْلامُ، وَالإِيمَانُ، وَالإِحْسَانُ. وَكُلُّ
مَرْتَبَةٍ لَهَا أَرْكَانٌ.
Oun tí ń jẹ́ Ìsìláámù ni ìjupá jusẹ̀ sílẹ̀ fún Ọlọ́hun (Allahu) pẹ̀lú gbígbá
lọ́kan soso, àti ìtẹríba pẹ̀lú ìyẹpẹrẹ ara ẹni fún àsẹ Rẹ̀, àti ìbọ́pábọ́sẹ̀
kúrò níbi àwọn isẹ́ àti àdìsọ́kàn ẹbọ àti àwọn ẹlẹ́bọ. Àwọn ìpele tí ẹ̀sìn
Ìsìláámù ní jẹ́ mẹ́ta, àwọn náà ni: Ìjupá jusẹ̀ sílẹ̀ (Ìsìláámù), Ìgbàgbọ́
Òdodo (Íímáánì), Ìse daadaa (Ìhsàánù). Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpele wọ̀nyí ló sìní àwọn
orìgun tirẹ̀.
المَرْتَبَةُ
الأُولَى: الإِسْلَامُ
Ìpele
Àkọ́kọ́: Ìjupá Jusẹ̀ Sílẹ̀ (Ìsìláámù)
فَأَرْكَانُ الإِسْلامِ خَمْسَةٌ:
شَهَادَةُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللهِ،
وَإِقَامُ الصلاة، وإِيتَاءُ الزَّكَاةِ، وَصَوْمُ رَمَضَانَ، وَحَجُّ بَيْتِ
اللهِ الْحَرَامِ.
Àwọn orígun tó gbé
Ìsìláámù dúró, marun péré ni: àkọ́kọ́ ni Ìjẹ́rí láti inú ọkàn
pé kò sí ẹnìkan tó tọ́ sí ìjọsìn òdodo lẹ́yìn Ọlọ́hun (Allahu), àtipé Ànábì
Muhammadu òjísẹ́ Ọlọ̀hun ni. Ìkejì ni Ìrun Kíkí. Ìkẹta ni Yíyọ Sàká Owó. Ìkẹrin
ni Gbígba Ààwẹ̀ Rámáláánà. Ìkarùn ni Lílọ sí Ilé Ọlọ́hun fún ìjọsìn Hájjì.
فَدَلِيلُ الشَّهَادَةِ قَوْلُهُ
تَعَالَى: ﴿شَهِدَ اللَّهُ أَنَّهُ
لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ وَالْمَلَائِكَةُ وَأُولُو الْعِلْمِ قَائِمًا بِالْقِسْطِ
لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ﴾ [آل عمران: 18].
Ẹ́rí máa jẹ́mi ǹsó lórí wípé Ìjẹ́rí láti inú ọkàn pé kò sí ẹnìkan tó tọ́ sí ìjọsìn òdodo lẹ́yìn Ọlọ́hun
(Allahu) ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun (Allahu) tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ
báyí wípé: (Ọlọ́hun
ń sé lófin wípé kòsí ẹlòmíràn tó tọ́sí ìjọsìn lẹ́yìn òhun Ọlọ́hun, àwọn
Màláíkà àti àwọn olùmọ̀ tó dúró tọ́ náà sì ń jẹ́rí pé bẹ́ẹ̀ ni, kòsí ẹlòmíràn
tó tọ́ sí ìjọsìn òdodo lẹ́yìn Ọlọ́hun ẹni tí títóbi rẹ̀ kò láfiwé, Ọba ọ̀jọ̀gbọ́n). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ àwọn aráálé Umuraana [Suratu Aali Umuraana], ẹsẹ 18).
وَمَعْنَاهَا: لَا مَعْبُودَ بِحَقٍّ إِلَّا
اللهُ. وَحَدُّ النَّفْيِ مِنَ الإِثْبَاتِ "لَا إِلَهَ" نَافِيًا جَمِيعَ
مَا يُعْبَدُ مِنْ دُونِ الله، "إِلَّا اللهُ" مُثْبِتًا الْعِبَادَةَ
للهِ وَحْدَهُ لا شَرِيكَ لَهُ فِي عِبَادَتِهِ، كَمَا أَنَّهُ لَيْسَ لَهُ
شَرِيكٌ فِي مُلْكِهِ.
Ìtumọ̀ ìjẹ́rí yí
ni wípé kò sí ẹni tó tọ́ sí ìjọsìn òdodo yàtọ̀ sí Ọlọ́hun (Allahu). Ààlà kíkọ̀
àti àfirinlẹ̀ tó wà nínú gbólóhùn yí ni gbólóhùn “Laa ilaaha” tí ń dá lérí kíkọ̀
gbogbo ǹkan míràn tí wọ́n máá ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Ọlọ́hun, àti gbólóhùn
“Illaa Allahu” tí ń dá lérí síse àfirinlẹ̀ ìjọsìn òdodo fún Ọlọ́hun ọ̀kan soso
tí kò lórogún níbi àwọn isẹ́ ìjọsìn àti ọlá rẹ̀.
وَتَفْسِيرُهَا
الَّذِي يُوَضِّحُهَا قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ إِنَّنِي بَرَاءٌ
مِمَّا تَعْبُدُونَ ^ إِلَّا الَّذِي فَطَرَنِي فَإِنَّهُ
سَيَهْدِينِ ^
وَجَعَلَهَا كَلِمَةً بَاقِيَةً فِي عَقِبِهِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ﴾ [الزخرف: 26-28]. وقَوْلُهُ
تَعَالَى: ﴿قُلْ يَا أَهْلَ
الْكِتَابِ تَعَالَوْا إِلَى كَلِمَةٍ سَوَاءٍ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ أَلَّا
نَعْبُدَ إِلَّا اللَّهَ وَلَا نُشْرِكَ بِهِ شَيْئًا وَلَا يَتَّخِذَ بَعْضُنَا
بَعْضًا أَرْبَابًا مِنْ دُونِ اللَّهِ
فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقُولُوا اشْهَدُوا بِأَنَّا مُسْلِمُونَ﴾ [آل
عمران: 64].
Àlàyé
tó tún le tan ìmọ́lẹ̀ sí ìtumọ̀ gbólóhùn yí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun Ọba Àlekè Ọlá tí
ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Ẹ
sèrántí ìgbà tí Ànábì Ibrahimọ ńsọ fún bàbá àti àwọn ìjọ bàbá rẹ̀ wípé:
dájúdájú èmí ń bọ́pá bọ́sẹ̀ kuro níbi gbogbo oun tí ẹ̀yin ń jọ́sìn fún ún ^ tó bá ti yàtọ̀ sí ohun tí Ọlọ̀hun asẹ̀dá mi pami lásẹ rẹ̀ (gẹ́gẹ́
bíi àwọn òrìsà tí ẹ̀yín ń sìn), torípé Òhun (Ọlọ́hun) nìkan ni ó lè tọ́mi sọ́nà
íjọsìn ^ Ó tún wáá sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ de àrọmọdọ́mọ rẹ̀, kí àwọn ẹni
anù inú wọn lè sẹ́rí padà soju ọ̀nà). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ọ̀sọ́ [Suratus Sukrufi], ẹsẹ 26-28). Àti ọ̀rọ̀
Ọlọ́hun míràn tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (pe gbogbo àwọn tí Ọlọ́hun fún àwọn òjísẹ́ wọn ní ìwé òfin
wípé: ẹ wáá gbọ́ ọ̀rọ̀ tóse déédé tí kò yàtọ̀ lọ́dọ apá kan wa sí òmíràn. Òun
náà nipe a kò gbudọ̀ máa sin ǹkan míràn tó yàtọ̀ sí Ọlọ́hun (Allahu), a kò sì
gbudọ̀ fi ǹkankan se orogún rẹ̀, àtipé apákan wa kò gbudọ̀ mú èkejì ní olùtẹ̀lé
lẹ́yìn Ọlọ́hun. Tí wọ́n bá wáá sàìgbọràn, ẹ jẹ́ kí wọn ó mọ̀ wípé olújupá jusẹ̀
sílẹ̀ ni ẹ̀yin ń se). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ àwọn aráálé Umuraana [Suratu Aali Umuraana], ẹsẹ 64).
وَدِليلُ شَهَادَةِ أَنَّ مُحَمَّدًا
رَسُولُ اللهِ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿لَقَدْ
جَاءَكُمْ رَسُولٌ مِنْ أَنْفُسِكُمْ عَزِيزٌ عَلَيْهِ مَا عَنِتُّمْ حَرِيصٌ
عَلَيْكُمْ بِالْمُؤْمِنِينَ رَءُوفٌ رَحِيمٌ﴾ [التوبة: 128].
Ítọ́ka lórí wípé Ànábì Muhammadu òjísẹ́ Ọlọ́hun ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀
rẹ̀ lọ báyí wípé: (Pàá, òjísẹ́ kan láti inú yín ti dé wáá bayín, oun tí ó bá ń niyín lára jẹ́
n tí kò níí dùn mọ́ ọn, yóó sì maa àkólékàn àti ìbìkítà nípa ìmọ̀nà yín, yóò sì
tún jẹ́ aláànú oníkẹ́ fún àwọn olùgbàgbọ́ òdodo). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ìtúúbá [Suratut Taobati], ẹsẹ 128).
وَمَعْنَى شَهَادَة أَنَّ مُحَمَّدًا
رَسُولُ اللهِ طَاعَتُهُ فِيمَا أَمَرَ، وَتَصْدِيقُهُ فِيمَا أَخْبَرَ،
واجْتِنَابُ مَا نَهَى عَنْهُ وَزَجَرَ، وَأَلَّا يُعْبَدَ اللهُ إِلا بِمَا
شَرَعَ.
Ìtumọ̀ ìjẹ́rí wípé Ànábì Muhammadu
òjísẹ́ Ọlọ́hun ni: ìtẹ̀lé àsẹ rẹ̀, ìgbà oun tí ó bá múwá níró lódodo, àti
ìjìnnà tefétefé sí oun tó bá kọ dínà sise rẹ̀, áígbudọ́ sin Ọlọ́hun àyàfi pẹ̀lú
oun tó bá múwá lófin.

No comments:
Post a Comment