Thursday, 21 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kejìlá)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
الْمَرْتَبَةُ الثَّانِيَةُ: الإِيمَانُ
Ìpele Èkejì: Ìgbàgbọ́ Òdodo (Íímáánì)

وَهُوَ بِضْعٌ وَسَبْعُونَ شُعْبَةً، فَأَعْلاهَا قَوْلُ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَأَدْنَاهَا إِمَاطَةُ الأَذَى عَنِ الطَّرِيقِ، وَالْحَيَاءُ شُعْبَةٌ مِنْ الإِيمَانِ.

Èkíké tàbí ìdá lọ́nà ààdọ́rin lé díẹ̀ ni ó pín sí. Èyí tí ó gba waju tó sì ga jù nínú àwọn ìdá yí ni gbólóhùn ìjẹ́rí “Laa Ilaaha Illaa Allahu”, èyí tó sì kéré jùlọ nínú wọn ni “mímú ohun ìpalára [Bí ọ̀páláńbá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ] kúró ní ojú ọ̀nà ìrìnsẹ̀ àwọn ohun abẹ̀mí. Ìtìjú gan nínú àwọn èkíké ìgbàgbọ́ lówà.

وَأَرْكَانُهُ سِتَّةٌ كَمَا فِي الحَدِيثِ: «أَنْ تُؤْمِنَ بِاللهِ، وَمَلائِكَتِهِ، وَكُتُبِهِ، وَرُسُلِهِ، وَالْيَوْمِ الآخِرِ، وَبِالْقَدَرِ خَيْرِهِ وَشَرِّهِ».

Mẹ́fà péré ni àwọn orígun ìgbàgbọ́ jẹ́, gẹ́gẹ́ bó ti se wà nínú ọ̀rọ̀ Ànábì (Hàdíìsì) tó sọ wípé: »Òun ni kí o ní ìgbàgbọ́ òdodo sí Ọlọ́hun, àti àwọn áńgẹ́lì (Màláíkà) Rẹ̀, àti àwọn ìwé òfin tí Ó fún àwọn òjísẹ́ Rẹ̀, àti àwọn òjísẹ́ Rẹ̀, àti ọjọ́ àgbéǹde àlùkìyáámọ̀, àti àkọsílẹ̀ (kádàrá), dáradára ni tàbí àìda«.

وَالدَّلِيلُ عَلَى هَذِهِ الأَرْكَانِ السِّتَةِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )لَيْسَ الْبِرَّ أَنْ تُوَلُّوا وُجُوهَكُمْ قِبَلَ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَلَكِنَّ الْبِرَّ مَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَالْمَلَائِكَةِ وَالْكِتَابِ وَالنَّبِيِّينَ( [البقرة: 177]. وَدَلِيلُ الْقَدَرِ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّا كُلَّ شَيْءٍ خَلَقْنَاهُ بِقَدَرٍ( [القمر: 49].

Ẹ̀rí lórí wípé sise àwọn òpó mẹ́fẹ̀ẹ̀fà yí ni ó gbé ìgbàgbọ́ dúró ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Ìgbàgbọ́ kò pin sórí dídojúkọ ibùyọ àti ibùwọ̀ òrùn, sùgbọ́n ẹni tí olùgbàgbọ́ tòótọ́ ni ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ ododo nínú Ọlọ́hun (Allahu), àti ọjọ́ àgbéǹde àlùkìyáámọ̀, àti àwọn áńgẹ́lì (Màláíkà), àti àwọn ìwé òfin tí Ó fún àwọn òjísẹ́, àti àwọn òjísẹ́).  (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ogédègbe Màálù [Suratul Bakọrati], ẹsẹ 177). Ẹ̀rí lórí wípé àkọsílẹ̀ (kádàrá) náà wà nínú orígun ìgbàgbọ́ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Oun gbogbo pata ni Àwa Ọlọ́hun ti parí àkọsílẹ̀ (kádàrá) lé lórí). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Òsùpá [Suratul Kọ́mọrì], ẹsẹ 49).

No comments:

The timeless lessons from Abū Bakr’s companionship with the Prophet ﷺ during the migration to Madinah

  كِتَابُ فَضَائِلِ الصَّحَابَةِ مَنَاقِبُ أَبِي بَكْرٍ رَضِي عَنْهُ بَابُ قَوْلِهِ تَعَالَى: ﴿إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ ا...