Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
ÌPÌLẸ̀ ẸLẸ́Ẹ̀KEJÌ
مَعْرِفَةُ
نَبِيِّكُمْ مُحَمَّدٍ صَلَّى اللهُ عليه وسلم
MÍMỌ̀ NÍPA ÀNÁBÌ YÍN TÍÍ SE MUHAMMADU (Kí Ọlọ́hun Lékún
Ìkẹ́ àti Ìgẹ̀ Rẹ̀)
وَهُوَ مُحَمَّدُ بْنُ
عَبْدِ اللهِ بْنِ عَبْدِ الْمُطَّلِبِ بْنِ هَاشِمٍ، وَهَاشِمٌ مِنْ قُرَيْشٍ،
وَقُرَيْشٌ مِنَ الْعَرَبِ، وَالْعَرَبُ مِنْ ذُرِّيَّةِ إِسْمَاعِيلَ بْنِ
إِبْرَاهِيمَ الْخَلِيلِ عَلَيْهِ وَعَلَى نَبِيِّنَا أَفْضَلُ الصَّلاةِ
وَالسَّلامِ. وَلَهُ مِنَ الِعُمُرِ ثَلاثٌ وَسِتُّونَ سَنَةً؛ مِنْهَا
أَرْبَعُونَ قَبْلَ النُّبُوَّةِ وَثَلاثٌ وعشرون نبيا رسولا.
Òun
náà ni Muhammadu Ọmọ Abdullahi Ọmọ Abdul Muttalibi Ọmọ Haaṣimi. Haaṣimi sì jẹ́
ìran Kùráíṣí, Kùráíṣí sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Lárúbáwá, nígbà tí Lárúbáwá jẹ́
àrọmọdọ́mọ Ismaaiila Ọmọ Ibraaiimọ (Kí èyí tí ó lọ́lá jùlọ nínú ìkẹ́ àti ìgẹ̀
máa bá òhun àti Ànábì wa). Gbogbo ọjọ́ orí Ànábì sì jẹ́ ọdún mẹ́ta lé láàdọ́ta
(63); Ó lo ogójì (40) síwájú kí ìmísí tóó bẹ̀rẹ̀ fun un, Ó sì fi ọdún mẹ́ta lé
lógún (23) gba ìmísí àti jísẹ́ Ọlọ́hun.
نبئ باقرأ، وأرسل بالمدثر.
وَبَلَدُهُ مَكَّةُ. بَعَثَهُ اللهُ بِالنِّذَارَةِ عَنِ الشِّرْكِ ويدعو إِلَى
التَّوْحِيدِ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )يَا أَيُّهَا الْمُدَّثِّرُ ^ قُمْ فَأَنْذِرْ ^ وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ ^ وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ ^ وَالرُّجْزَ فَاهْجُرْ ^ وَلَا تَمْنُنْ تَسْتَكْثِرُ ^ وَلِرَبِّكَ فَاصْبِرْ( [المدثر: 1 - 7]. وَمَعْنَى "قُمْ فَأَنذِرْ":
يُنْذِرُ عَنِ الشِّرْكِ وَيَدْعُو إلى التوحيد. "وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ":
عَظِّمْهُ بِالتَّوْحِيدِ. "وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ": أَيْ
طَهِّرْ أَعْمَالَكَ من الشِّرْكِ. "وَالرُّجْزَ فَاهْجُرْ":
الرُّجْزَ: الأَصْنَامُ. وَهَجْرُهَا: تَرْكُهَا وأهلها، وَالْبَرَاءَةُ مِنْهَا
وَأَهْلُهَا.
Ọgbà Ọ̀rọ̀
“Kàá” (Suratu Ikra tàbí
Alaki) ni ìmísí fi bẹ̀rẹ̀ fún un, nígbà tí ìgbe dìde gẹ́gẹ́ bí òjísẹ́ bẹ̀rẹ̀
pẹ̀lú Ọgbà Ọ̀rọ̀ Olùdasọbora (Suratul Muddassiri). Mákkà sì ni ìlú abínibí rẹ̀.
Ọlọ́hun gbée dìde pẹ̀lú ìkininílọ̀ níbi ẹbọ àti ìmáa pèpè lọ síbi ìmú Ọlọ́hun
(Allahu) lọ́kan soso. Ẹ̀rí lórí èyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyì
wípé: (Ìrẹ olùdasọbora ^ Dìde láti máa ki àwọn èẹìyàn nílọ̀ ^ Ọlọ́hun
asẹ̀dá rẹ nìkan sìni kí o máa bàbàrà ^ kí o sì tún máa se ìmọ́tótó tinú tòde rẹ ^ gbogbo oun tó bá sì jẹmọ́ oun ẹlẹ́gbin, kí o
takété sí wọn ^ sì jinna sí ìrègún síse, èyí tí ó lè máa
mú ọ bàbàra sàárá tí o ti se). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Olùdasọbora [Suratul Muddassiri],
ẹsẹ 1-7). Ìtumọ gbólóhùn “Dìde láti máa ki àwọn èẹìyàn nílọ̀” nipé kí
Ànábì máa se ìkìlọ̀ kúrò níbi ẹbọ, kí ó sì maa pèpè lọ síbi ìmú Ọlọ́hun lọ́kan
soso. Gbólóhùn “Ọlọ́hun asẹ̀dá rẹ nìkan sìni kí o máa bàbàrà” ń túmọ̀
sí “Bàbàrà rẹ̀ pẹ̀lú ìmu lọ́kan soso”. Gbólóhùn “kí o sì tún máa se
ìmọ́tótó tinú tòde rẹ” ń túmọ̀ sí “Se àfọ̀mọ́ àwọn ìsẹ́ rẹ kúrò níbi ẹbọ”.
Gbólóhùn “Gbogbo oun tó bá sì jẹmọ́ oun ẹlẹ́gbin, kí o takété sí wọn”. “Oun
ẹlẹ́gbin” ni “Àwọn òrìsà”. Jíjìnnà sí wọn sì ni “Ìtakété síwọn
àti àwọn tí ó ń bọwọ́n, pẹ̀lú ìbọ́pábọ́sẹ̀ kúrò níbi sísìn wọ́n àti àwọn olùjọ́sìn
fún wọn”.
أَخَذَ عَلَى هَذَا عَشْرَ
سِنِينَ يَدْعُو إِلَى التَّوْحِيدِ، وَبَعْدَ الْعَشْرِ عُرِجَ بِهِ إِلَى
السَّمَاءِ وَفُرِضَتْ عَلَيْهِ الصَّلَواتُ الْخَمْسُ. وَصَلَّى فِي مَكَّةَ ثَلَاثَ
سِنِينَ، وَبَعْدَهَا أَمَرَ بِالْهِجْرَةِ فِي الْمَدِينَةِ.
Ànábì lo ọdún mẹ́wá gbáko lórí ìpèpè lọ síbi ìmú Ọlọ́hun
lọ́kan. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wà yẹn, Ọlọ́hun mú un gun òkè sánmọ̀ lọ, ibẹ́ ni wọ́n ti
se ìrun wákàtí máàrún ní ọ̀ranyàn le òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lórí. Ó kírun
fún ọdún mẹ́ta ní ìlú Mákkà, lẹ́yìn náà ni wọ́n pá làsẹ ìsípò padà (Híjírá) lọ
sí ìlú Madiina.
وَالْهِجْرَةُ: الانْتِقَالُ
مِنْ بَلَدِ الشِّرْكِ إِلَى بَلَدِ الإِسْلامِ. وَالْهِجْرَةُ فَرِيضَةٌ عَلَى
هَذِهِ الأُمَّةِ مِنْ بَلَدِ الشِّرْكِ إِلَى بلد الإِسْلامِ، وَهِيَ بَاقِيَةٌ
إِلَى أَنْ تَقُومَ السَّاعَةُ. وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّ
الَّذِينَ تَوَفَّاهُمُ الْمَلَائِكَةُ ظَالِمِي أَنْفُسِهِمْ قَالُوا فِيمَ
كُنْتُمْ قَالُوا كُنَّا مُسْتَضْعَفِينَ فِي الْأَرْضِ قَالُوا أَلَمْ تَكُنْ
أَرْضُ اللَّهِ وَاسِعَةً فَتُهَاجِرُوا فِيهَا فَأُولَئِكَ مَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ
وَسَاءَتْ مَصِيرًا ^ إِلَّا الْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ الرِّجَالِ وَالنِّسَاءِ
وَالْوِلْدَانِ لَا يَسْتَطِيعُونَ حِيلَةً وَلَا يَهْتَدُونَ سَبِيلًا ^ فَأُولَئِكَ عَسَى
اللَّهُ أَنْ يَعْفُوَ عَنْهُمْ وَكَانَ اللَّهُ عَفُوًّا غَفُورًا( [النساء: 97 - 99].
وَقَوْلُهُ تَعَالَى: )يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ أَرْضِي وَاسِعَةٌ فَإِيَّايَ
فَاعْبُدُونِ( [العنكبوت: 56]. قَالَ
البَغَوِيُّ رَحِمَهُ اللهُ: "سَبَبُ نُزُولِ هَذِهِ الآيَةِ فِي المُسْلِمِينَ
الَّذِينَ فِي مَكَّةَ لَمْ يُهَاجِرُوا، نَادَاهُمُ اللهُ بِاسْمِ الإِيمَانِ".
Ìsípò padà (Híjírá) ni ìsí kúrò ní ìlú ẹbọ lọsí ilẹ̀
Ìsìláámù. Sísí kúrò ní ìlú ẹbọ lọ sí ilẹ̀
Ìsìláámù (Híjírá) yí sì pọn dandan fún àwọn ọmọlẹ́yìn ànábì. Ààyè sì gba
síse rẹ̀ títí di ìgbà tí ayé kò níí jẹ́ ayé mọ́. Ẹ̀rí eléyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí
ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Dájúdájú àwọn tí àwọn Màláíkà gbẹ̀mí wọn lẹ́ni tí wọ́n
sàbòsí ara wọn pẹ̀lú àìse híjírá pẹ̀lú àwọn musulumi, àwọn Màláíkà yí yóò máa
fi wọ́n se yẹ̀yẹ́ wípé: “Ibo lẹ bá ẹ̀sìn dé?”, wọn yóò sì máa fesi wípé: “Àwa jẹ́
ẹni tí àwọn ará Mákkà dí lọ́wọ́ láti se ẹ̀sìn”. Àwọn Màláíkà náà yóó tún màa
fún wọn lésì wípé: “Sé ilẹ̀ Ọlọ́hun kò wáá fẹ̀ debi tí ẹ fi lè sí lọ sí
ibòmíràn?”. Nítorínáà, ibùdésí àwọn èèyàn yí ni iná jáǹnámà. Síọ̀ ibùdésí náà ^ Àyàfi àwọn tí wọ́n jẹ gaba lé lórí lọ́kùnrin, lóbìnrin,
lọ́mọdé, tí wọn kò ní ọ̀nà àbayọ kankan, tí wọn kò sì le dá mọ ọ̀nà ^ Óséése kí Ọlọ́hun se àmójú kúrò fún irú wọn. Ọlọ́hun jẹ́
Alámójú kúrò, Aláforíjìn jùlọ) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin [Suratun Nisaai], ẹsẹ 97-99). Àti
ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Ẹ̀yin ẹrúsìn mi tó jẹ́ olúgbágbọ́ òdodo, dájúdájú ilẹ̀
èmi (Ọlọ́hun) tẹ́ pẹrẹsẹ. Torínáà, èmi (Ọlọ́hun) nìkan ni kí ẹ máa sìn). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Aláǹtakùn [Suratul Ankabuuti], ẹsẹ 56).
Olúmọ́ Àgbà ọmọ bibi ilẹ̀ “baga” (Al bagawiyyu) –kí Ọlọ́hun kẹ́ wọn- sọpé: “Okùnfà sísọ̀ kalẹ̀ ẹsẹ ọ̀rọ̀ (Aayati) yí ni
dídúró àwọn kan ní ílú Mákka láì se Hijira, Ọlọ́hun fi orúkọ ìgbàgbọ́ pè wọ́n”.
وَالدَّلِيلُ عَلَى
الْهِجْرَةِ مِنَ السُّنَّةِ قَوْلُهُ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «لا تَنْقَطِعُ
الْهِجْرَةُ حَتَّى تَنْقَطِعَ التَّوْبَةُ وَلا تَنْقَطِعُ التَّوْبَةُ حَتَّى
تَطْلُعَ الشَّمْسُ مِنْ مغربها».
Ẹ̀rí láti inú ọ̀rọ̀ Ànábì ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí
ó lọ báyí wípé: »Ìyírapadà (Hijrah)
kò níí dópin títí òpin yóò fi dé bá ìtúúbá, òpin kò sì le débá ìtúúbá títí tí
òòrùn yóò fi yọ níbi tí ó ti ń wọ̀.«

No comments:
Post a Comment