Sunday, 24 September 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ USULU SALASA (ÌPÌLẸ̀ ÈSÌN MẸ́TA TÒ SE PÀTÀKÌ) (Ẹ̀Kọ́ Kẹtàlá)

Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
المرتبة الثالثة: الإحسان
Ìpele Ẹ̀kẹta: Ìse dáadáa (Ìhsàánù)

وَلَهُ رُكْنٌ وَاحِدٌ كَمَا فِي الَحِديثِ: «أَنْ تَعْبُدَ اللهَ كَأَنَّكَ تَرَاهُ فَإِنْ لَمْ تَكُنْ تَرَاهُ فَإِنَّهُ يَرَاكَ».

Orígun kan péré ni ti ìse dáadáa (Ìhsàánù) náà gẹ́gẹ́ bó ti se wà nínú ọ̀rọ̀ Ànábì (Hàdíìsì) tó sọ wípé: »Òun náà ni kí o máa sin Ọlọ́hun (Allahu) bíi pé ò ń ríI (Ọlọ́hun), tí oò bá wáá le sìn Ín (Ọlọ́hun) bíi pé ò ń ríI, sì máa sìn ín pẹ̀lú àmọ̀dájú wípé Òun ń rí ìrẹ).

وَالدَّلِيلُ قَوْلُهُ تَعَالَى: )إِنَّ اللَّهَ مَعَ الَّذِينَ اتَّقَوْا وَالَّذِينَ هُمْ مُحْسِنُونَ( [النحل: 128]، وقَوْلُهُ تَعَالَى: )وَتَوَكَّلْ عَلَى الْعَزِيزِ الرَّحِيمِ ^ الَّذِي يَرَاكَ حِينَ تَقُومُ ^ وَتَقَلُّبَكَ فِي السَّاجِدِينَ ^ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ( [الشعراء: 217 - 220]، وقَوْلُهُ تَعَالَى: )وَمَا تَكُونُ فِي شَأْنٍ وَمَا تَتْلُو مِنْهُ مِنْ قُرْآنٍ وَلَا تَعْمَلُونَ مِنْ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيْكُمْ شُهُودًا إِذْ تُفِيضُونَ فِيهِ( [يونس: 61].

Ẹ̀rí lórí wípé ìse dáadáa (Ìhsàánù) wà nínú àwọn ìpele ẹ̀sìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Dájúdájú Ọlọ́hun wà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ní ìpayà rẹ̀ àti àwọn tí wọ́n bá ńse dáadáa). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Kòkòrò Oyin [Suratun Nahli], ẹsẹ 128). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ báyí wípé: (Kí o sì fi ara ti Ọlọ́hun Ọba alágbára aláànú jùlọ ^ Ọba tí Ó ń rí ìrẹ nígbà tí o bá gbé ìrun dúró ^ Àti ìgbà tí o bá ńlọ ìforíbalẹ̀ ^ Dájúdájú Ọlọ́hun (Allahu) ni ọba tí Ó tayọ oun gbogbo ní gbígbọ́ tí Ó sì ní ìmọ̀ jùlọ). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Àwọn Akunrin [Suratus Shuaraai], ẹsẹ 217-220). Àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ tún lọ báyí wípé: (Kò sí ipòkípo kan tí ìrẹ ànábì wà, bẹ́ẹ̀ ni oò níí ka ọ̀rọ̀ kan nínú ìwé òfin Al kuraani, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò níí se isẹ́ kan àyàfi kó jẹ́ wípé àwa Ọlọ́hun (Allahu) ríi nígbà tí ẹ̀ ń sé). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ànábì Yuunusa [Suratu Yuunusa], ẹsẹ 61).

وَالدَّلِيلُ مِنَ السُّنَّةِ: حَدِيثُ جِبْرِيلَ الْمَشْهُورُ عَنْ عُمَرَ بنِ الْخَطَّابِ رَضِيَ اللهُ عَنْهُ قَالَ: «بينما نحن جُلُوسٌ عِنْدَ النَّبِيِّ -r- إِذْ طَلَعَ عَلَيْنَا رَجُلٌ شَدِيدُ بَيَاضِ الثِّيَابِ شَدِيدُ سَوَادِ الشَّعْرِ لا يُرَى عَلَيْهِ أَثَرُ السَّفَرِ وَلا يَعْرِفُهُ مِنَّا أَحَدٌ فَجَلَسَ إِلَى النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَأَسْنَدَ رُكْبَتَيْهِ إِلَى رُكْبَتَيْهِ وَوَضَعَ كَفَّيْهِ عَلَى فَخِذَيْهِ وَقَالَ: يَا مُحَمَّدُ أَخْبِرْنِي عَنِ الإِسْلامِ فَقَالَ: أَنْ تَشْهَدَ أَنْ لا اله إِلا اللهُ وَأَنَّ مُحَمَّدًا -r- رَسُولُ اللهِ، وَتُقِيمَ الصَّلاةَ، وَتُؤْتِيَ الزَّكَاةَ، وَتَصُومَ رَمَضَانَ، وَتَحُجَّ الْبَيْتَ إِنْ اسْتَطَعْتَ إِلَيْهِ سَبِيلا. قَالَ: صَدَقْتَ. فَعَجِبْنَا لَهُ يَسْأَلُهُ وَيُصَدِّقُهُ. قَالَ: أَخْبِرْنِي عَنِ الإِيمَانِ قَالَ: أَنْ تُؤْمِنَ بِاللهِ، وَمَلَائِكَتِهِ، وَكُتُبِهِ وَرُسُلِهِ وَالْيَوْمِ الآخِرِ، وَبِالْقَدَرِ خَيْرِهِ وَشَرِّهِ. قَالَ: أَخْبِرْنِي عَنِ الإِحْسَانِ. قَالَ: أَنْ تَعْبُدَ اللهَ كَأَنَّكَ تَرَاهُ، فَإِنْ لَمْ تَكُنْ تَرَاهُ، فَإِنَّهُ يَرَاكَ. قَالَ: أَخْبِرْنِي عَنِ السَّاعَةِ. قَالَ: مَا الْمَسْؤُولُ عَنْهَا بِأَعْلَمَ مِنَ السَّائِلِ. قَالَ: أَخْبِرْنِي عَنْ أَمَارَاتِهَا. قَالَ: أَنْ تَلِدَ الأَمَةُ رَبَّتَهَا، وَأَنْ تَرَى الْحُفَاةَ الْعُرَاةَ الْعَالَةَ رِعَاءَ الشَّاءِ يَتَطَاوَلُونَ فِي الْبُنْيَانِ. قَالَ: فَمَضَى، فَلَبِثْنَا مَلِيَّا. فَقَالَ: يَا عُمَرُ، أَتَدْرُونَ مَنِ السَّائِلِ؟ قُلْنَا: اللهُ وَرَسُولُهُ أَعْلَمُ، قَالَ: هَذَا جِبْرِيلُ، أَتَاكُمْ يُعَلِّمُكُمْ أَمْرَ دِينِكُم».

Ẹ̀rí láti inú ọ̀rọ̀ Ànábì ni hàdíìsì tí ó gbajúmọ̀ sí hàdíìsì màláíkà Jùbìríílà èyí tí Òmárù (Kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i) gbà wá báyí wípé: (Ní àlàfo wípé a jókó lọ́dọ̀ Ànábì ní ọjọ́kan, sàdéédé ni arákùnrin kan yọ síwa. Asọ arákùnrin náà funfun gbòò, irun orí rẹ̀ dúdú kirimu, a kò rí àmì arìnrìn àjò lára rẹ̀, ọ̀kankan kò sì mọ̀ ọ́n rí nínú àwa tí a wà níkàlẹ. Arákùnrin yí bá fìkàlẹ̀ síwájú Ànábì lẹ́ni tófi orúkún rẹ̀ ko orúnkún Ànábì, tó sì da àtẹlẹwọ́ rẹ̀ méjéèjì dé itan rẹ̀ méjéèjì. Ó wáá sọpé ìrẹ Muhammadu: “fún mi níró nípa Ìsìláámù”. Ànábí sì dáa lóhùn wípé: “Ìsìláámù ni kí o jẹ́rí à jẹ́ dọ́kàn wípé kòsí nkànkan tó lẹ́tọ́ sí ìjọsìn lódodo àyàfi Ọlọ́hun (Allahu), àti wípé Muhammadu òjísẹ́ Ọlọ́hun ni. Kí o sì tún máa gbé ìrun dúró fún Ọlọ́hun, àti kí o máa yọ sàká owó rẹ, àti kí o máa gba ààwẹ̀ Rámọ́láánà, àti kí o se ìjọsìn Hajji lọ sí ilé Ọlọ́hun ní ìlú Makka tí o bá ti lágbára à ti lọ”. Arákùnrin yí sì fesi wípé: “Òdodo lo sọ”. Èǹmọ̀ se wá látààrí wípé òun náà ni ń dáa tí ń gbèé. Arákùnrin yí tún tẹ̀ síwájú lẹ́ni tó sọpé: “Fún mi níró nípa ìgbàgbọ́ (Íímọ́ọ́nì)”. Ànábí sì tún dáa lóhùn wípé: “Ìgbàgbọ́ (Íímọ́ọ́nì) ni kí o ní ìgbàgbọ́ òdodo sí Ọlọ́hun, àti àwọn áńgẹ́lì (Màláíkà) Rẹ̀, àti àwọn ìwé òfin tí Ó fún àwọn òjísẹ́ Rẹ̀, àti àwọn òjísẹ́ Rẹ̀, àti ọjọ́ àgbéǹde àlùkìyáámọ̀, àti àkọsílẹ̀ (kádàrá), dáradára ni tàbí àìda”. Arákùnrin yí tún tẹ̀ síwájú lẹ́ni tó sọpé: “Fún mi níró nípa ìse dáadáa (Ihsaan)”. Ànábí tún dáhùn wípé: “ìse dáadáa (Ihsaan) ni kí o máa sin Ọlọ́hun (Allahu) bíi pé ò ń ríI (Ọlọ́hun), tí oò bá wáá le sìn Ín (Ọlọ́hun) bíi pé ò ń ríI, sì máa sìn ín pẹ̀lú àmọ̀dájú wípé Òun ń rí ìrẹ”. Arákùnrin yí tún ní: “Sọ fún mi nípa ìgbà tí ìgbéǹdé àlùkìyáámọ̀ yóò dé”. Ànábí dáhùn wípé: “Ẹni tí wọ́n ń bi kò tó ẹni tí ń bèèrè nímọ̀ nípa dide rẹ̀”. Arákùnrin yí bání: “Sọ àwọn àmì dide rẹ̀ fúnmi”. Ànábí sì dáhùn wípé: “Àwọn àmì dídé rẹ̀ ni kí àwọn ẹrú lobinrin ó máa bí àwọn tí yóò máa se ọ̀gá léwọn lórí, àti kí o máa rí àwọn aláìnì bàtà ní ẹsẹ̀, àti aláìní asọ lọ́rùn, otòsì èèyàn kí wọn ó máa la ilé alájà àjà mọ́lẹ̀”. Òmárù (Kí Ọlọ̀hun yọ́nú si) sọ wípé arákùnrin yí bá pẹ̀yìndà. Kò pẹ́ púpọ̀ sí ìgbà tó lọ ni Ànábì sọpé: “Ìrẹ Òmárù, ǹjẹ́ ẹ mọ arákùnrin oní ọ̀pọ̀lọpọ̀ íbèèrè tó wá yẹn bí?”. Gbogbo wa sì dáhun wípé: “Ọlọ́hun àti òjísẹ́ rẹ̀ nìkan ni wọ́n mọ̀ ọ́n”. Ànábì wáá sọpé: “Jùbìríílà ló wá tí ẹ rí un, ó wá láti wáá kọyín nípa àláámọ̀rí ẹ̀sìn yín ni”.

No comments:

The timeless lessons from Abū Bakr’s companionship with the Prophet ﷺ during the migration to Madinah

  كِتَابُ فَضَائِلِ الصَّحَابَةِ مَنَاقِبُ أَبِي بَكْرٍ رَضِي عَنْهُ بَابُ قَوْلِهِ تَعَالَى: ﴿إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ ا...