Ọ̀rọ̀ Olùkọ̀wé Ní Èdè Lárúbáwá
وَدَلِيلُ
الصَّلاةِ وَالزَّكَاةِ وَتَفْسِيرُ التَّوْحِيدِ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا
اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ حُنَفَاءَ وَيُقِيمُوا الصَّلَاةَ وَيُؤْتُوا
الزَّكَاةَ وَذَلِكَ دِينُ الْقَيِّمَةِ﴾
[البينة: 5].
وَدَلِيلُ
الصَّلاةِ وَالزَّكَاةِ وَتَفْسِيرُ التَّوْحِيدِ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا
اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ حُنَفَاءَ وَيُقِيمُوا الصَّلَاةَ وَيُؤْتُوا
الزَّكَاةَ وَذَلِكَ دِينُ الْقَيِّمَةِ﴾
[البينة: 5].
Ẹ̀rí lórí “Ìrun kíkí, Sàká Owó yíyọ”,
àti ìtumọ̀ “Ìmọ̀ Ọlọ́hun lọ́kan (At Taohiidu) ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ
bayi wípé: (Ọlọ́hun kò pa’wọ́n lásẹ ǹkankan tó kọjá kí wọ́n máa se àfọ̀mọ́ ìjọsìn wọn fún
Ọlọ́hun nìkan soso láì kò mú orogún mọ́ Ọn, kí wọ́n sì máa gbé ìrun dúró fún Ọlọ́hun,
kí wọ́n sì máa yọ Sàká Owó wọn. Eléyẹn sì ni ẹ̀sìn tó dúró tọ́). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ẹ̀rí tó Fojú Hàn [Suratul
Bayyinati], ẹsẹ 5).
ودَلِيلُ
الصِّيَامِ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿يَا
أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى
الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ﴾ [البقرة: 183].
Ẹ̀rí lórí wípé Ààwẹ̀ “Rámáláánà” gbígbà
wà nínú àwọn origun ẹ̀sìn Ìsìláámù ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé:
(Ẹ̀yin olùgbàgbọ́ ododo, Ọlọ́hun ti se ààwẹ̀ “Rámàláánà” gbígbà ní ọ̀ranyàn
fun yín, gẹ́gẹ́ bí À ti sé ní ọ̀ranyàn lé àwọn tó siwájú yín lórí, boya yóó le
jẹ́ okùnfà ìbẹ̀rù Ọlọ́hun fun yín). (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ogédègbe Màálù [Suratul Bakọrati], ẹsẹ
183).
وَدَلِيلُ
الْحَجِّ قَوْلُهُ تَعَالَى: ﴿وَلِلَّهِ
عَلَى النَّاسِ حِجُّ الْبَيْتِ مَنِ اسْتَطَاعَ إِلَيْهِ سَبِيلًا وَمَنْ كَفَرَ فَإِنَّ اللَّهَ غَنِيٌّ عَنِ
الْعَالَمِينَ﴾ [آل عمران: 97].
Ẹ̀rí lórí wípé sise àbẹ̀wò
ilé Ọlọ́hun ní Mákà “Hajju” wà nínú àwọn origun ẹ̀sìn Ìsìláámù ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun
tí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ bayi wípé: (Ọlọ́hun (Allahu) pọ́n ní
dandan lórí gbogbo ọmọnìyàn tỌ́lọ́hun bùkún tó sì lágbára, síse àbẹ̀wò ilé Ọlọ́hun
ní Mákkà (Ìjọsìn Hájjù). Ẹni tó bá sì gbẹ́rù gbọnrí tó ní òhun kò sé é (Tó sì lágbára
à ti sé é). kó lọ rèémọ̀ wípé Ọlọ́hun rọrọ̀, kò sì bùkáátà sí ìkankan nínú gbogbo
ohun tó sẹ̀dá). (Ọgbà Ọ̀rọ̀
àwọn aráálé Umuraana [Suratu Aali Umuraana], ẹsẹ 97).
No comments:
Post a Comment