Ọ̀RỌ̀
ÌSIWÁJÚ
)تِلْكَ
حُدُودُ اللَّهِ فَلَا تَعْتَدُوهَا( [البقرة: 229].
(Àwọn wọ̀n un nì ni ààlà Ọlọ́hun
(Allahu), Ẹ má se rékọjá wọn) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ògédègbe Màálù [Suratu
Bakarati], ẹsẹ 229).
بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَنِ الرَّحِيمِ
اَلْحَمْدُ
لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ، وَالصَّلَاةُ وَالسَّلَامُ عَلَى سَيِّدِنَا
مُحَمَّدٍ خَاتَمِ النَّبِيِّينَ وَإِمَامِ الْمُرْسَلِينَ.
Pẹ̀lú orúkọ Ọlọ̀hun Àjọkẹ́ Ayé, Àsàkẹ́ Ọ̀run ni mo fi bẹ̀rẹ̀ ìwé
yí. Gbogbo ìran ọpẹ́ jẹ́ ti Ọlọ́hun, Asẹ̀dá gbogbo àgbáńlá ayé. Ìkẹ́ àti ìgẹ̀
kí ó máa bá asíwájú wa Ànábì Muhammadu, ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn ànábì Ọlọ́hun àti
asíwájú gbogbo àwọn òjísẹ́ Ọlọ́hun.
(أَوَّلُ
مَا يَجِبُ عَلَى الْمُكَلَّفِ): تَصْحِيحُ إِيمَانِهِ ثُمَّ مَعْرِفَةُ مَا
يُصْلِحُ بِهِ فَرْضَ عَيْنِهِ كَأَحْكَامِ الصَّلَاةِ وَالطَّهَارَةِ
وَالصِّيَامِ.
(Àkọ́kọ́ oun tó pọn dandan fún ẹni tí wọ́n ti la okùn ẹ̀sin bọ̀ lọ́rùn):
òun ni síse àtunse ìgbàgbọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni mímọ àwọn oun tí ó le jẹ́ kí àwọn
isẹ́ tí ó di ọ̀ranyàn síse fún ẹnìkọ̀ọ̀kan dára. Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ìdájọ́ ìrun,
ìmọ́tótó, àti ààwẹ̀.
(وَيَجِبُ) عَلَيْهِ أَنْ يُحَافِظَ عَلَى حُدُودِ اللَّهِ وَيَقِفَ
عِنْدَ أَمْرِهِ وَنَهْيِهِ وَيَتُوبَ إِلَى اللَّهِ سُبْحَانَهُ قَبْلَ أَنْ
يَسْخَطَ عَلَيْهِ.
Ó tún di ọ̀ranyà fún un láti máa kíyèsí àwọn ààlà Ọlọ̀hun, kí ó sì
má tayọ àsẹ Ọlọ̀hun, pẹ̀lú kíkóra dúró níbi oun èèwọ̀ rẹ̀. Kí ó sì yára sẹ́rí
padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun (Túúbá) kí Ó tóó bínù sìi.
(وَشُرُوطُ اَلتَّوْبَةِ) النَّدَمُ عَلَى مَا فَاتَ، وَالنِّيَّةُ
أَنْ لَا يَعُودَ إِلَى ذَنْبٍ فِيمَا بَقِيَ عَلَيْهِ مِنْ عُمُرِهِ، وَأَنْ
يَتْرُكَ الْمَعْصِيَةَ فِي سَاعَتِهَا إِنْ كَانَ مُتَلَبِّسًا بِهَا، وَلَا
يَحِلُّ لَهُ أَنْ يُؤَخِّرَ التَّوْبَةَ، وَلَا يَقُولُ: حَتَّى يَهْدِيَنِي
اللَّهُ فَإِنَّهُ مِنْ عَلَامَاتِ الشَّقَاءِ وَالْخِذْلَانِ وَطَمْسِ
الْبَصِيرَةِ.
Àwọn májẹ̀mu ìtúúbá náà ni: Ìkábàmọ̀ lórí oun tí ó ti kọjá,
ìdàmùrè wípé òun kò níí padà sí ìdí ẹ̀sẹ̀ ní ìgbà tókù tí yóò lò láyé, fífi ìwà
ẹ̀sẹ̀ náà sílẹ̀ ní àkókó ìtúúbá tó bá jẹ́ wípé ìwà ẹ̀sẹ̀ náà ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀
lákókò ìtúúbá. Kò sí lẹ́tọ́ fún ẹrú láti fi ìtúúbá falẹ̀. Kí ó jìnnà sí ìmáa sọpé:
ó di ìgbà tí Ọlọ́hun bá tọ́mi sọ́nà, nítorípé ìmáa fi ìtúúbá falẹ̀, nínú àmì
‘òfò’, ‘ìpòfo’, àti ‘gbígba ìmọ́lẹ̀ ìgbàgbọ́’ ara ẹni ni.
(وَيَجِبُ) عَلَيْهِ حِفْظُ لِسَانِهِ مِنَ الْفَحْشَاءِ
وَالْمُنْكَرِ، وَالْكَلَامِ الْقَبِيحِ، وَأَيْمَانِ الطَّلَاقِ، وَانتْهَارِ
الْمُسْلِمِ وَإِهَانَتِهِ، وَسَبِّهِ وَتَخْوِيفِهِ فِي غَيْرِ حَقٍّ شَرْعِيٍّ.
Ó tún di ọ̀ranyàn fún un kí ó máa sọ́ ahọ́n rẹ̀
kùrò níbi àwọn ọ̀rọ̀ àlùfààṣá àti àwọn isẹ́ ẹ̀kọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ burúkú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀
ìbura pẹ̀lú ìkọ̀sílẹ̀, àti ìmaaké mọ́ Mùsùlùmí pẹ̀lu ìyẹpẹrẹ rẹ̀, ìmaa bú
Mùsùlùmí àti ìmaa dẹ́rù bàá láì ní ẹ̀tọ́.
(وَيَجِبُ)
عَلَيْهِ حِفْظُ بَصَرِهِ عَنِ النَّظَرِ إِلَى الْحَرَامِ، وَلَا يَحِلُّ لَهُ
أَنْ يَنْظُرَ إِلَى مُسْلِمٍ بِنَظْرَةٍ تُؤْذِيهِ إِلَّا أَنْ يَكُونَ فَاسِقًا
فَيَجِبُ هِجْرَانُهُ.
Ó tún di ọ̀ranyàn le lórí kí ó máa kíyèsí ìríran
rẹ̀ níbi mímáa fi wo oun èèwọ̀. Kò sì tún lẹ́tọ́ fún un kí ó máa fi wo Mùsùlùmí
ní wiwo tí ó lè pá lára (fojú tẹ́ńbẹ́lú) àyàfi tí ó bá jẹ́ olùfojú sílẹ̀ rọ́lu
ẹ̀sẹ̀, ìyàn án lódì yóò jẹ́ ọ̀rayàn le lórí.
(وَيَجِبُ) عَلَيْهِ
حِفْظُ جَمِيعِ جَوَارِحِهِ مَا اسْتَطَاعَ، وَأَنْ يُحِبَّ لِلَّهِ وَيُبْغِضَ
لَهُ وَيَرْضَى لَهُ وَيَغْضَبَ لَهُ، وَيَأْمُرَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَى عَنِ
الْمُنْكَرِ.
Ó tún jẹ́ ọ̀ranyàn fùn un, ìkíyèsí
gbogbo àgọ́ ara rẹ̀ pẹ̀lú bí ó bá se ní agbára mọ. Gẹ́gẹ́ bí ó ti se jẹ́ ọ̀ranyàn
fún un kí ìfẹ́ níní àti ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀, ìyọ́nú àti ìbínú rẹ̀ máa jẹ́ tori Ọlọ́hun.
Ó sì tún di ọ̀ranyàn fún un kí ó máa pàsẹ dáadáa, kí ó sì máa kọ àìdára.
وَيَحْرُمُ
عَلَيْهِ الْكَذِبُ وَالْغِيبَةُ وَالنَّمِيمَةُ وَالْكِبْرُ وَالْعُجْبُ
وَالرِّيَاءُ وَالسُّمْعَةُ وَالْحَسَدُ وَالْبُغْضُ وَرُؤْيَةُ الْفَضْلِ عَلَى
الْغَيْرِ، وَالْهَمْزُ وَاللَّمْزُ وَالْعَبَثُ وَالسُّخْرِيَةُ، وَالزِّنَا،
وَالنَّظَرُ إِلَى الْأَجْنَبِيَّةِ، وَالتَّلَذُّذُ بِكَلَامِهَا، وَأَكْلُ
أَمْوَالِ النَّاسِ بِغَيْرِ طِيبِ نَفْسٍ وَالْأَكْلُ بِالشَّفَاعَةِ أَوْ
بِالدِّينِ وَتَأْخِيرُ الصَّلَاةِ عَنْ أَوْقَاتِهَا. وَلَا يَحِلُّ لَهُ
صُحْبَةُ فَاسِقٍ، وَلَا مُجَالَسَتُهُ لِغَيْرِ ضَرُورَةٍ، وَلَا يَطْلُبُ رِضَا
الْمَخْلُوقِينَ بِسَخَطِ اَلْخَالِقِ، قَالَ اللَّهُ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَى: )وَاللَّهُ
وَرَسُولُهُ أَحَقُّ أَنْ يُرْضُوهُ إِنْ كَانُوا مُؤْمِنِينَ(. [التوبة: 62]. وَقَالَ عَلَيْهِ الصَّلَاةُ
وَالسَّلَامُ: «لَا طَاعَةَ لِمَخْلُوقٍ فِي مَعْصِيَّةِ الْخَالِقِ».
Èèwọ̀ sì ni ó jẹ́ fún un, irọ́
pipa, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn sísọ, òfófó síse, ìgbéraga, ìjọraẹnilójú, àsehàn, sekágbọ́mi,
ìpẹ̀gàn, inúnibíni, ìmaaaripé ènìyàn lọ́lá ju ẹlòmíràn lọ, ìmáabúni loju ẹni,
ìmáabúni lẹ́yìn ẹni, ìmaa fẹ̀sìn se awẹ́wa, ìwà àgbèrè, ìmáa tẹjú mọ́ àwọn
obìnrin tí kò lẹ́tọ́ sí, ìmáa fi ohùn wọn dọ́fun tòló, ìmáa jẹ dúkìá àwọn èèyàn
láì dùn mọ́ wọn nínú, ìmáa fi ìbani wá ìpẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́hun tàbí ẹ̀sìn jẹun,
ìmáa fi ìrun lọ́ra kọjá àkókò rẹ̀. Kò sì lẹ́tọ́ fún un kí ó máa bá pòkíì èèyàn
sọ̀rẹ́, ìmáa jókó pẹ̀lú rẹ̀ láì ní ìdí pàtàkì (Làlúrí).kò sì lẹ́tọ́ fún un kí ó
máa wá ìyọ́nú ọmọnìyàn pẹ̀lú ìbínú Ọlọ́hun, nitori ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ìtumọ̀ rẹ̀
lọ báyí wípé: (Ọlọ́hun nìkan àti òjísẹ́ rẹ̀ ni lẹ́tọ́ kí wọ́n
yọ́ nínú tí ó bá jẹ́ wípé olùgbàgbọ́ tòótọ́ ni wọ́n jẹ́) (Ọgbà Ọ̀rọ̀ Ìtúúbá [Suratut Taobati], ẹsẹ 62). Ànábì (kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun
máa báa) náà tún sọ wípé: “Ìtẹ̀lé éyíkéyí nínú àwọn ẹ̀dá níbi oun tí ó le múni sẹ
Ọlọ́hun adẹ́dá, kò lẹ́tọ́”.
وَلَا يَحِلُّ لَهُ أَنْ يَفْعَلَ فِعْلًا حَتَّى يَعْلَمَ حُكْمَ
اللَّهِ فِيهِ وَيَسْأَلَ الْعُلَمَاءَ وَيَقْتَدِيَ بِالْمُتَّبِعِينَ لِسُنَّةِ
مُحَمَّدٍ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ اَلَّذِينَ يَدُلُّونَ عَلَى طَاعَةِ
اللَّهِ، وَيُحَذِّرُونَ مِنَ اتِّبَاعِ الشَّيْطَانِ.
Kò tún tọ́ fún ẹni tí wọ́n ti lakùn ẹ̀sìn bọ̀ lọ́rùn kí ó se isẹ́
kan títí yóò fi mọ ìdájọ́ Ọlọ́hun lórí rẹ̀, tí yóò sì fi bi àwọn olùmọ̀ ẹ̀sìn léèrè nípa rẹ̀, tí yóò sì kọ́se àwọn tí ó bá
ń tẹ̀lé ìlànà Ànábì (kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun
máa báa) nínú wọn, àwọn tí wọ́n máá ń tọ́ka èèyàn sí ìtẹ̀lé Ọlọ́hun, tí wọn sì
máá ń ki èèyàn nílọ̀ níbi ìtẹ̀lé ìlànà èsù (Sètáánì).
وَلَا يَرْضَى لِنَفْسِهِ
مَا رَضِيَهُ الْمُفْلِسُونَ الَّذِينَ ضَاعَتْ أَعْمَارُهُمْ فِي غَيْرِ طَاعَةِ
اللَّهِ تَعَالَى، فَيَا حَسْرَتَهُمْ وَيَا طُولَ بُكَائِهِمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ،
نَسْأَلُ اللَّهَ أَنْ يُوَفِّقَنَا لِاتِّبَاعِ سُنَّةِ نَبِيِّنَا وَشَفِيعِنَا
وَسَيِّدِنَا مُحَمَّدٍ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ.
Ẹni tí
wọ́n ti la okun ẹ̀sìn bọ̀ lọ́rùn kò sì gbudọ̀ jẹ́ ẹni tí ó jẹ́ pé oun tí yóò
maa dá lọ́rùn ni oun tí ó bá ń dá pòkíì (Aláse dànù) lọ́rùn, àwọn tí wọ́n se ọjọ́
ayé wọn lófò lórí oun tí ó yàtọ̀ sí ìtẹ̀lé Ọlọ́hun. Báwo ni àbámọ̀ wọn yóò se
tó, bawo ni ẹkún wọn yóò se pọ̀ tó lọ́jọ́ ìgbéǹde àlùkìyáómọ. À ń bẹ Ọlọ́hun
(Allahu) kí ó fi wá se kòǹgẹ́ ìtẹ̀lé ìlànà Ànábì, Olùsìpẹ̀, àti Asíwájú
wa Muhammadu kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa báa.

No comments:
Post a Comment