Thursday, 12 October 2017

ÌTUMỌ̀ TÍRÀ ÁHLÀRÍ (Ẹ̀kọ́ Kejì)

فَصْلٌ فِي الطَّهَارَةِ
ÌPÍN TÍ Ó Ń SÀLÀYÉ ÌMỌ́TÓTÓ

الطَّهَارَةُ قِسْمَانِ: طَهَارَةُ حَدَثٍ، وَطَهَارَةُ خَبَثٍ، وَلَا يَصِحُّ الْجَمِيعُ إِلَّا بِالْمَاءِ الطَّاهِرِ الْمُطَهِّرِ، وَهُوَ الَّذِي لَمْ يَتَغَيَّرْ لَوْنُهُ أَوْ طَعْمُهُ أَوْ رَائِحَتُهُ بِمَا يُفَارِقُهُ غَالِبًا كَالزَّيْتِ وَالسَّمْنِ وَالدَّسَمِ كُلِّهِ وَالْوَذَحِ وَالصَّابُونِ وَالْوَسَخِ وَنَحْوِهِ، وَلَا بَأْسَ بِالتُّرَابِ وَالْحَمْأَةِ وَالسَّبَخَةِ وَالْآجُرِّ وَنَحْوِهِ.

Ìmọ́tótó pín sí mèjì: Ìmọ́ra níbi ẹ̀gbin, àti íha ẹ̀gbin dànù. Mímú ẹ̀gbin méjéèjì kúrò kò leè ní àlàáfíà àyàfi pẹ̀lu omi tí ó mọ́, tí ó tún le mọ́ ǹkan. Òun (Omi tí ó mọ́, tí ó tún le mọ́ ǹkan) náà ni èyí tí kò yí padà ní ‘Àwọ̀’, tàbí ní ‘Ìtọ́wò’, tàbí ní ‘Òórùn’, pẹ̀lú oun tí ó sepé kò sí nínù àláádà kí ò jẹ́ àbùdá omi tí ó bá dàsí i. Gẹ́gẹ́ bí epo, magarin, gbogbo ìran ọ̀rá, òógùn ìtọ̀ àti ìgbẹ́ ẹranko, ọsẹ, ìdọ̀tí, àti àwọn oun tí ó bá tún dàbí wọn. Kò sí aburu níbi fífi omi tí ó yí padà pẹ̀lú oun tí kìí fi ìgbà kankan yà á se ìmọ́tótó. Gẹ́gẹ́ bì iyẹ̀ẹ̀pẹ̀, amọ̀, ẹrẹ̀, bíríkì, àti àwọn oun tí ó bá jọ wọ́n.

فَصْلٌ: إِذَا تَعَيَّنَتِ النَّجَاسَةُ غُسِلَ مَحَلُّهَا، فَإِنِ الْتَبَسَتْ غُسِلَ الثَّوْبُ كُلُّهُ. وَمَنْ شَكَّ فِي إِصَابَةِ النَّجَاسَةِ نَضَحَ، وَإِنْ أَصَابَهُ شَيْءٌ شَكَّ فِي نَجَاسَتِهِ فَلَا نَضْحَ عَلَيْهِ، وَمَنْ تَذَكَّرَ اَلنَّجَاسَةَ وَهُوَ فِي الصَّلَاةِ قَطَعَ إِلَّا أَنْ يَخَافَ خُرُوجَ الْوَقْتِ. وَمَنْ صَلَّى بِهَا نَاسِيًا وَتَذَكَّرَ بَعْدَ السَّلَامِ أَعَادَ فِي الْوَقْتِ.

Ẹ̀kọ́ Míràn: Tí ààyè ẹ̀gbin bá fojú hàn, ààyè náà di ọ̀ranyàn fífọ̀. Tí ó bá wá dojú rú, odidi asọ dọ̀ranyàn fífọ̀. Ẹni tí ó bá wá ń se iyèméjì lórí pé ẹ̀gbin ta sí ààyè kan, yóò fi omi wọ́n ààyè náà. Tí ó bá wá ń se iyèméjì lórí íjẹ́ ẹ̀gbin oun tí ó ta sí i, kò bùkátà fífi omi wọ́n. Ẹni tí ó bá rántí pé ẹ̀gbin wà lára òun nígbà tí ó ti wà lórí ìrun, ó gbudọ̀ jà ìrun náà, àyàfi tí ó bá ń bẹ̀rù kí àkókò ìrun náà jáde. Ẹni tí ó bá wáá gbàgbé kírun pẹ̀lú ẹ̀gbin lára, tí kò rántí títí tí ó fi mú ìrun náà dópin (Sálámọ̀), ó gbudọ̀ san ìrun náà padà ní àkókò tí ó rántí.

فَصْلٌ: فَرَائِضُ الْوُضُوءِ سَبْعٌ: اَلنِّيَّةُ، وَغَسْلُ الْوَجْهِ، وَغَسْلُ الْيَدَيْنِ إِلَى الْمِرْفَقَيْنِ، وَمَسْحُ الرَّأْسِ، وَغَسْلُ الرِّجْلَيْنِ إِلَى الْكَعْبَيْنِ، وَالدَّلْكُ، وَالْفَوْرُ.

Ẹ̀kọ́ Míràn: Àwọn ọ̀ranyàn àlùwàlá jẹ́ méje- Níní àníyàn, fífọ ojú, wíwẹ ọwọ́ méjéèjì dé ìgbùwọ́, pípá orí, fífọ ẹsẹ̀ méjéèjì dé kókó ẹsẹ̀, fífi ọwọ́ gbo àwọn ààyè náà, síse àwọn ààyè náà láì kò fi àlàfo pípẹ́ sí ààrin wọn.

(وَسُنَنُهُ): غَسْلُ الْيَدَيْنِ إِلَى الْكُوعَيْنِ عِنْدَ الشُّرُوعِ، وَالْمَضْمَضَةُ، وَالِاسْتِنْشَاقُ، وَالِاسْتِنْثَارُ، وَرَدُّ مَسْحِ الرَّأْسِ وَمَسْحُ اَلْأُذُنَيْنِ وَتَجْدِيدُ الْمَاءِ لَهُمَا، وَالتَّرْتِيبُ بَيْنَ الْفَرَائِضِ. وَمَنْ نَسِيَ فَرْضًا مِنْ أَعْضَائِهِ فَإِنْ تَذَكَّرَهُ بِالْقُرْبِ فَعَلَهُ وَمَا بَعْدَهُ، وَإِنْ طَالَ فَعَلَهُ وَحْدَهُ وَأَعَادَ مَا صَلَّى قَبْلَهُ. وَإِنْ تَرَكَ سُنَّةً فَعَلَهَا وَلَا يُعِيدُ الصَّلَاةَ. وَمَنْ نَسِيَ لُمْعَةً غَسَلَهَا وَحْدَهَا بِنِيَّةٍ وَإِنْ صَلَّى قَبْلَ ذَلِكَ أَعَادَ. وَمَنْ تَذَكَّرَ الْمَضْمَضَةَ وَالِاسْتِنْشَاقَ بَعْدَ أَنْ شَرَعَ فِي الْوَجْهِ فَلَا يَرْجِعُ إِلَيْهِمَا حَتَّى يُتِمَّ وُضُوءَهُ.

(Ìlànà Ànábì lórí síse àlùwàlá): fífọ ọwọ́ méjéèjì títí dé ọrùn ọwọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ síse àlùwàlá, yíyọ ẹnu, fífín omi sí imú, fífọn omi tí a fín sinu ihò imú sí ìta padà, dida pípá orí padà láti ẹ̀yìn sí iwájú, pípá etí méjéèjì pẹ̀lú omi ọ̀tun, títò àwọn iburè tí ó jẹ́ ọ̀ranyan tẹ̀lé ara wọn. Ẹni tí ó bá wáá gbàgbé ọ̀kan nínú àwọn iburè tí ó jẹ́ ọ̀ranyàn, tí ó bá yára tete rántí, yóò padà sí ibi iburè náà pẹ̀lú síse àwọn iburè ọ̀ranyàn tí ó tẹ̀le. Tí ó bá wáá pẹ́ kí ó tóó rántí, yóò kàn dá iburè náà se, yóò sì se adápadà ìrun tí ó ti kí. Tí ó bá wáá jẹ́ wípé ọ̀kan nínú àwọn ìlànà síse àlùwàlá tí kìí se ọ̀ranyàn ni ó gbàgbé, yóò kàn se ẹ̀tọ́ tí ó bá yẹ lórí iburè náà, kò sì níí dá ìrun náà padà. Ẹni tí ó bá gbàgbé èkíké iburè àlùwàlá kan, yóò dá iburè náà fọ̀ pẹ̀lú aniyan, koda bí ó bá ti kírun kí ó tóó rántí, yóò dá ìrun náà padà. Ẹni tí ó bá wáá rántí wípé òun kò yọ ẹnu, àti wípé òun kò fín imú, nígbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀ orí pípá, kò níí padà sori méjéèjì titi yóò fi parí àlùwàlá rẹ̀.

(وَفَضَائِلُهُ) التَّسْمِيَّةُ وَالسِّوَاكُ وَالزَّائِدُ عَلَى الْغَسْلَةِ الْأُولَى فِي الْوَجْهِ وَالْيَدَيْنِ، وَالْبُدَاءَةُ بِمُقَدِّمِ الرَّأْسِ، وَتَرْتِيبُ السُّنَنِ وَقِلَّةُ الْمَاءِ عَلَى الْعُضْوِ، وَتَقْدِيمُ الْيُمْنَى عَلَى الْيُسْرَى. وَيَجِبُ تَخْلِيلُ أَصَابِعِ الرِّجْلَيْنِ، وَيَجِبُ تَخْلِيلُ اللِّحْيَةِ الْخَفِيفَةِ فِي الْوُضُوءِ دُونَ الْكَثِيفَةِ، وَيَجِبُ تَخْلِيلُهَا فِي الْغُسْلِ وَلَوْ كَانَتْ كَثِيفَةً.

(Àwọn oun tí wọ́n fẹ́ síse wọn níbi àlùwàlá): Dídá orúkọ Ọlọ́hun ní ìbẹ̀rẹ̀ àlùwàlá (Síse Bismillah), rírun orín, fífọ ojú àti ọwọ́ méjéèjì kọjá ẹ̀ẹ̀kan, bíbẹ̀rẹ̀ pípá orí láti iwájú, títo àwọn ìlànà àlùwàlá (Sunan) tẹ̀lé ara wọn, gígán omi lò, síse ìmọ́tótó apá ọ̀tún síwájú apá òsì. Ọ̀ranyàn sì ni fífi ọwọ́ gbo àwọn àlàfo ọmọníka ẹsẹ̀ méjéèjì. Ọ̀ranyàn sì ni fífi ọwọ́ ya irungbọ̀n tí kò bá pọ̀ níbi àlùwàlá, ó sì di ọ̀ranyàn fífi ọwọ́ yà á, kódà kí ó pọ̀ níbi ìwẹ̀ òfin.

فَصْلٌ: نَوَاقِضُ الْوُضُوءِ أَحْدَاثٌ وَأَسْبَابٌ: فَالْأَحْدَاثُ: الْبَوْلُ وَالْغَائِطُ وَالرِّيحُ وَالْمَذْيُ وَالْوَدْيُ. وَالْأَسْبَابُ: النَّوْمُ الثَّقِيلُ وَالْإِغْمَاءُ وَالسُّكْرُ وَالْجُنُونُ وَالْقُبْلَةُ، وَلَمْسُ الْمَرْأَةِ إِنْ قَصَدَ اللَّذَّةَ أَوْ وَجَدَهَا، وَمَسُّ الذَّكَرِ بِبَاطِنِ الْكَفِّ أَوْ بِبَاطِنِ الْأَصَابِعِ. وَمَنْ شَكَّ فِي حَدَثٍ وَجَبَ عَلَيْهِ الْوُضُوءُ إِلَّا أَنْ يَكُونَ مُوَسْوَسًا فَلَا شَيْءَ عَلَيْهِ. وَيَجِبُ عَلَيْهِ غَسْلُ الذَّكَرِ كُلِّهِ مِنَ الْمَذْيِ، وَلَا يَغْسِلُ الْأُنْثَيَيْنِ. وَالْمَذْيُ هُوَ الْمَاءُ الْخَارِجُ عِنْدَ الشَّهْوَةِ الصُّغْرَى بِتَفَكُّرٍ أَوْ نَظَرٍ أَوْ غَيْرِهِ.

Ẹ̀kọ́ míràn: Àwọn oun tí ó má ń ba àlùwàlá ni ẹ̀gbin àti oun tí oun tí ó le se okùnfà ẹ̀gbin. Àwọn ẹ̀gbin tí ó má ń ba àlùwàlá jẹ́ ni: ìtọ̀, ìgbẹ́, isó, àtọ̀ tí ó jáde nígbà tí à ń ronu adùn, àti àtọ̀ tí ó jáde lẹ́yìn ìtọ̀. Àwọn oun tí ó le se okùnfà ẹ̀gbin ni: oorun tí ó wọra, dídákú, ìhúnrìrà, ìpàdánù ọpọlọ, fífi ẹnu ko ẹlẹ́tọ́ ẹni lẹ́nu, dídi obìnrin mú pẹ̀lú èrò adùn tàbí rírí adùn, fífi àtẹlẹwọ́ tàbí ìka di abẹ́ ọkùnrin (àsákàrí) mú. Ẹni tí ó bá se iyèméjì lórí jíjáde ẹ̀gbin lára rẹ̀, síse àlùwàlá di ọ̀ranyàn fún un, àyàfi tí ó bá jẹ́ wípé ó ní àìsàn ròyíròyí, kò níí tún àlùwàlá se. Ó di ọ̀ranyàn fún ẹni ti àtọ̀ jáde lára rẹ̀ nígbà tí ó ń ronu adùn kí ó fọ àsọ̀ọ̀rọ̀ tí ìtọ̀ ńgba jáde, kó sì bùkáátà kí ó fọ àpò kórópọ̀n méjéèjì. Oun tí ń jẹ́ “Mọdiyyu” ni àtọ̀ tí ó ń jáde pẹ̀lú ìrònú tàbí títẹjú mọ́ àti àwọn ǹkan míràn tí ó tún lè mu jáde ní àsìkò adùn kékeré.

فَصْلٌ: لَا يَحِلُّ لِغَيْرِ الْمُتَوَضِّئِ صَلَاةٌ وَلَا طَوَافٌ وَلَا مَسُّ نُسْخَةِ الْقُرْآنِ الْعَظِيمِ وَلَا جِلْدِهَا، لَا بِيَدِهِ وَلَا بِعُودٍ وَنَحَوِهِ إِلَّا الْجُزْءَ مِنْهَا الْمُتَعَلَّمَ فِيهِ، وَلَا مَسُّ لَوْحِ الْقُرْآنِ الْعَظِيمِ عَلَى غَيْرِ الْوُضُوءِ إِلَّا لِمُتَعَلِّمٍ فِيهِ أَوْ مُعَلِّمٍ يُصَحِّحُهُ وَالصَّبِيُّ فِي مَسِّ الْقُرْآنِ كَالْكَبِيرِ، وَالْإِثْمُ عَلَى مُنَاوِلِهِ لَهُ، وَمَنْ صَلَّى بِغَيْرِ وُضُوءٍ عَامِدًا فَهُوَ كَافِرٌ وَالْعِيَاذُ بِاللَّهِ.

Ẹ̀kọ́ míràn: Kò lẹ́tọ́ fún ẹni tí kò ní àlùwàlá kí ó kí ìrun, àti kí ó pòòrì yíká ilé Ọlọ́hun (Kàábà), kò sì ní ẹ̀tọ́ kí ó fi ọ̀kankan nínú oríké ara rẹ̀ gbá odidi àti awọ Àlùkùráánì mú; kò gbudọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bẹ́ẹ̀ ni kò gbudọ̀ fi òǹkà (bí igi) àti àwọn oun tí ó bá tún jọ́ kàn án àyàfi tí apá kan láti fi kọ́ ẹ̀kọ́. Kódà dídi pátákó tí wọ́n han Àlùkùráánì sí kò ní ẹ̀tọ́ láì kò ní àlùwàlá, àyàfi fún ẹni tí ó fi ń kọ́ ẹ̀kọ́ tàbí ó fi ń kọ́ ẹlòmíràn ní ẹ̀kọ́. Kò sí ìyàtọ̀ láàrin ọmọdé àti àgbàlagbà níbi ìdájọ́ dídi Àlùkùráánì mú. Ẹni tí yóó sì ni ẹ̀sẹ̀ ni ẹni tí ó bá gbé Àlùkùráánì fún ọmọdé. Ẹni tí ó bá mọ̀ńmọ̀ kí ìrun láì ní àlùwàlá ti di kèfèrí, kí Ọlọ́hun sọ́ wa níbi ìse àti ìwà kèfèrí.

No comments:

The timeless lessons from Abū Bakr’s companionship with the Prophet ﷺ during the migration to Madinah

  كِتَابُ فَضَائِلِ الصَّحَابَةِ مَنَاقِبُ أَبِي بَكْرٍ رَضِي عَنْهُ بَابُ قَوْلِهِ تَعَالَى: ﴿إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ ا...